אגרת פולוס השליח אל-הרומיים 2 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס השליח אל-הרומיים 2:1-29

1אולי תאמר: ”אילו הם אנשים רשעים!“ אך דע לך שאינך טוב מהם! באמירתך כי הם רשעים וכי יש להענישם, אתה שופט למעשה את עצמך, שכן אתה עושה בדיוק אותם מעשים. 2ואנחנו יודעים שאלוהים מעניש בצדק את העושים מעשי תועבה כאלה. 3הסבור אתה שבעשותך מעשי תועבה כמוהם, אלוהים ישפוט וירשיע את האחרים ויניח לך? 4האם אתה לא רואה עד כמה אלוהים טוב, אורך רוח וסבלני איתך? האם אתה לא רואה שהטוב הזה מיועד להסב אותך מהחטא?

5דע לך כי בעקשנותך ובסירובך להפסיק לחטוא ולחזור בתשובה, אתה צובר לך עונש נורא ליום־הדין – היום שבו ישפוט אלוהים בצדק את העולם כולו. 6ביום זה ישלם אלוהים לכל איש את המגיע לו לפי מעשיו: 7אלה המשתדלים לעשות מעשים טובים, המצייתים לאלוהים והשואפים לכבוד והדר שלא מן העולם הזה, יזכו בחיי נצח. 8ואילו הרשעים אשר מורדים בה׳ ואינם מצייתים לו, יקבלו עונש נורא. 9צער וסבל יבואו על כל העושים מעשי חטא ועוול: על היהודי בראשונה, וגם על ה”גוי“. 10לעומת זאת, כל אלה שיצייתו לאלוהים ויעשו מעשים טובים יזכו לכבוד, להדר ולשלום מאת האלוהים – היהודי בראשונה, וגם הגוי. 11כי אלוהים אינו מפלה בין בני־האדם.

12אלוהים יעניש את כל החוטאים! אלה שחטאו בלי שהכירו את התורה ייענשו גם בלי להתחשב בתורה; אלה שהכירו את התורה וחטאו, יישפטו וייענשו על־פי התורה. 13שהרי אלוהים אינו מצדיק את אלה שמכירים את התורה, כי אם את אלה שמקיימים אותה הלכה למעשה. 14כאשר הגויים, שאין להם את התורה, מקיימים את עיקר חוקיה מתוך חוש טבעי, הרי שחוש זה הוא תורתם ולפיו הם יישפטו. 15התנהגותם מוכיחה שדרישות התורה כתובות למעשה על לבם; מצפונם אומר להם מה מותר ומה אסור, ומחשבותיהם מצדיקות או מאשימות אותם. 16הם יישפטו ביום־הדין – היום שבו ישפוט אלוהים, באמצעות המשיח, את הצד הנסתר בחייו של כל אדם. זהו חלק מתוכניתו של ה׳ שאותה אני מבשר.

17אתם, היהודים, מתגאים שאתם ידידיו הנבחרים של אלוהים; אתם חושבים שהואיל ונתן לכם את תורתו, הכול כשורה ביניכם לבינו. 18אתם יודעים מהו רצונו של אלוהים; אתם יודעים להבחין בין טוב לרע, שכן למדתם את תורתו עוד לפני זמן רב. 19אתם משוכנעים שהנכם מוכשרים וראויים ללמד את אלה שאינם יודעים את הדרך לה׳, ולשמש כלפידי אור המדריכים אל ה׳ את אלה שתעו בחשכה. 20אתם משוכנעים שהנכם מוכשרים ללמד את הבורים, את התמימים ואת הילדים, שכן אתם מכירים את תורת ה׳.

21אבל אתם המוכנים תמיד ללמד את האחרים – מדוע אינכם מלמדים את עצמכם? אתם מצווים על אחרים לא לגנוב – האם אתם בעצמכם נקיי כפיים? 22אתם מצווים על אחרים לא לנאוף – האם אינכם נואפים בעצמכם? אתם מתנגדים לעבודת האלילים – האם אינכם גוזלים את כלי הקדושה שלהם?

23אתם גאים בעובדת ידיעתכם את תורת אלוהים, אך באי־קיימכם את מצוותיו אתם מבזים למעשה את אלוהים. 24אין פלא שכתבי־הקודש אומרים:2‏.24 ב 24 ישעיהו נב 5 ”בגללכם שם אלהים מחולל בגוים“!

25לברית־המילה יש ערך ומשמעות רק אם אתה שומר את מצוות ה׳. אם אינך שומר את מצוות ה׳, אינך טוב מהגויים. 26ואם גוי, שלא נימול, ישמור את מצוות ה׳, האם לא יעניק לו אלוהים את הזכויות שהתכוון להעניק ליהודים? 27למעשה, הגוי המקיים את התורה הוא שישפוט אותך, היהודי, למרות שנמולת ושניתנה לך תורת ה׳ שאותה הפרת. 28הרי אינך יהודי אמיתי רק משום שנולדת להורים יהודים, או משום שנמולת. 29יהודי אמיתי הוא זה שאוהב את ה׳. כי אלוהים אינו מעוניין באלה שכל יהדותם מסתכמת בקיום ברית־המילה בלבד, כי אם באלה שלבם וחייהם השתנו, ולאלה הוא יעניק כבוד ושבח לא בעיני בני אדם, כי אם בעיני אלוהים.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 2:1-29

Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run

12.1: Ro 14.22.Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́, nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́. 2Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. 3Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí? 42.4: Ef 1.7; 2.7; Fp 4.19; Kl 1.27.Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?

5Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 62.6: Mt 16.27; 1Kọ 3.8; 2Kọ 5.10; If 22.12.Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. 7Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. 8Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. 9Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; 10ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 11Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

122.12: Ro 3.19; 1Kọ 9.21.Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin, àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́. 132.13: Jk 1.22-23,25.Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 162.16: Su 12.14; Ro 16.25; 1Kọ 4.5.Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.

Àwọn Júù àti òfin

17Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 182.18: Fp 1.10.tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 202.20: Ro 6.17; 2Tm 1.13.Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́. 212.21: Mt 23.3-4.Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 242.24: Isa 52.5.Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.”

252.25: Jr 9.25.Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. 262.26: 1Kọ 7.19; Ap 10.35.Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? 272.27: Mt 12.41.Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà.

282.28: Mt 3.9; Jh 8.39; Ro 9.6-7; Ga 6.15.Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà. 292.29: 2Kọ 3.6; Fp 3.3; Kl 2.11; 1Pt 3.4.Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.