創世記 8 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 8:1-22

洪水消退

1上帝眷顧挪亞及方舟裡的野獸和牲畜,使風吹在大地上,水便開始消退。 2深淵的泉源和天上的水閘都關閉了,大雨也停了。 3地上的洪水慢慢消退,過了一百五十天,水退下去了。 4七月十七日,方舟停在亞拉臘山上。 5水繼續消退,到十月一日,山頂都露出來了。

6又過了四十天,挪亞打開方舟的窗戶, 7放出一隻烏鴉。牠一直在空中飛來飛去,直到地上的水都乾了。 8後來,挪亞放出一隻鴿子,以便瞭解地面的水是否已經消退。 9但遍地都是水,鴿子找不到歇腳的地方,就飛回了方舟,挪亞伸手把鴿子接進方舟裡。 10過了七天,挪亞再把鴿子放出去。 11到了黃昏,鴿子飛回來,嘴裡啣著一片新擰下來的橄欖葉,挪亞便知道地上的水已經退了。 12等了七天,他又放出鴿子,這一次,鴿子沒有回來。

13挪亞六百零一歲那年的一月一日,地上的水乾了。挪亞打開方舟的蓋觀望,看見地面都乾了。 14到了二月二十七日,大地完全乾了。 15上帝對挪亞說: 16「你與妻子、兒子和兒媳可以出方舟了。 17你要把方舟裡的飛禽走獸及爬蟲等所有動物都帶出來,讓牠們在地上多多繁殖。」 18於是,挪亞與妻子、兒子和兒媳都出了方舟。 19方舟裡的飛禽走獸和爬蟲等所有地上的動物,都按種類出了方舟。

挪亞獻祭

20挪亞為耶和華築了一座壇,在上面焚燒各種潔淨的牲畜和飛鳥作為燔祭。 21耶和華聞到這燔祭的馨香,心想:「雖然人從小就心存惡念,但我再不會因為人的緣故而咒詛大地,再不會毀滅一切生靈。 22只要大地尚存,播種收割、夏熱冬寒、白晝黑夜必永不停息。」

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 8:1-22

Ìkún omi gbẹ

1Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. 2Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. 3Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. 4Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. 5Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn.

6Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀. 7Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀. 8Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 9Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. 10Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. 11Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 12Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

13Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. 14Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá.

15Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé. 16“Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. 17Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.”

18Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde. 19Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn.

20Noa sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 21Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe.

22“Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà,

ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè

ìgbà òtútù àti ìgbà ooru,

ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò,

ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru,

yóò wà títí láé.”