民数记 13 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

民数记 13:1-33

打探迦南

1耶和华对摩西说: 2“你要派十二位首领,每个支派一位,去打探我要赐给以色列人的迦南。” 3摩西就按耶和华的吩咐,从巴兰旷野派出了十二位首领。 4他们的名字如下:吕便支派撒刻的儿子沙姆亚5西缅支派何利的儿子沙法6犹大支派耶孚尼的儿子迦勒7以萨迦支派约色的儿子以迦8以法莲支派的儿子何西阿9便雅悯支派拉孚的儿子帕提10西布伦支派梭底的儿子迦叠11约瑟的子孙、玛拿西支派稣西的儿子迦底12支派基玛利的儿子亚米利13亚设支派米迦勒的儿子西帖14拿弗他利支派缚西的儿子拿比15迦得支派玛基的儿子臼利16以上是摩西派去打探迦南的人,他称的儿子何西阿约书亚

17摩西派他们去打探迦南,并嘱咐说:“你们先去南地,然后再进山区, 18打探那地方,看看那里的居民是强是弱,是多是少; 19那地方是好是坏,人们住的是坚固的城池还是不设防的营地; 20土地是肥沃还是贫瘠,有没有树木。尽量带些当地的果子回来。”当时是葡萄初熟的季节。

21于是,他们从旷野一直打探到哈马口附近的利合22他们经南地到达希伯仑希伯仑城比埃及锁安城还要早建七年,那里住着亚衲人的子孙亚希幔示筛挞买23他们来到以实各谷,在那里砍下一根葡萄枝,上面有一串葡萄,由两个人用杠子抬着,又采了一些石榴和无花果。 24因为他们在那里砍了一串葡萄,所以就称那地方为以实各13:24 以实各”意思是“一串”。谷。

25过了四十天,他们打探完毕,返回营地。 26他们来到巴兰旷野的加低斯摩西亚伦以色列全体会众汇报,把当地的果子给大家看。 27他们对摩西说:“我们照你的指示打探了那地方,果然是奶蜜之乡,这些都是那里的果子。 28但那里的居民很强悍,城邑又大又坚固。我们在那里还见到亚衲人的子孙。 29亚玛力人住在南地,人、耶布斯人和亚摩利人住在山区,迦南人住在海边和约旦河沿岸。” 30迦勒让站在摩西面前的民众安静,然后说:“我们立刻去占领那地方吧!我们必能取胜。” 31跟他一起去打探的人却说:“我们不能去攻打那些人,他们比我们强大。” 32他们还危言耸听,说:“我们去打探的地方是吞吃居民之地,我们看见的人个个身材高大。 33我们在那里看见了亚衲人的子孙,他们是巨人的后裔,我们跟他们相比就像蚱蜢,他们看我们也像蚱蜢。”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 13:1-33

Ṣíṣe Ayọ́lẹ̀wò sí ilẹ̀ Kenaani

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”

3Mose sì rán wọn jáde láti aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.

4Orúkọ wọn nìwọ̀nyí:

láti inú ẹ̀yà Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakkuri;

5láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;

6láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne;

7láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu;

8láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni;

9láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu;

10láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi;

11láti inú ẹ̀yà Manase (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;

12láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;

13láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

14láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;

15láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.

16Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)

17Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè. 18Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi? 20Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)

21Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati. 22Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.) 23Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀. 25Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.

Ìròyìn nípa ilẹ̀ tí wọ́n yẹ̀ wò

26Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí, “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí. 28Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀. 29Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jordani.”

30Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.”

31Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.” 32Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀. 3313.33: Gẹ 6.4.A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”