列王纪下 5 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

列王纪下 5:1-27

以利沙医治乃缦

1乃缦亚兰王的元帅,甚得亚兰王器重,因为耶和华借他使亚兰人打了许多胜仗。他是英勇的战士,只是患了麻风病。 2亚兰人袭击以色列时,曾掳回一个以色列少女,这少女做了乃缦妻子的婢女。 3有一天,她对主母说:“要是我主人去见撒玛利亚的那位先知就好了!他一定能治好我主人的麻风病。” 4乃缦把这以色列少女的话告诉亚兰王。 5亚兰王说:“你去吧。我会写信给以色列王的。”于是,乃缦带了三百四十公斤银子、七十公斤金子和十套衣服,启程前往以色列6他带给以色列王的信上写着:“谨以此信介绍我的臣仆乃缦到你那里,你要医好他的麻风病。” 7以色列王读完信后,就撕裂衣服说:“难道我是上帝吗?我能操纵人的生死吗?这人竟叫我医好一个人的麻风病!他只是想找借口攻打我。”

8上帝的仆人以利沙听说以色列王撕裂了衣服,便派人去对王说:“你为什么撕裂衣服呢?让那人到我这里来,我要让他知道以色列有先知。” 9乃缦带领车辆和马匹到了以利沙的家,站在门口。 10以利沙派使者出去对乃缦说:“你到约旦河里洗七次,你的皮肤就会复原,并得到洁净。” 11乃缦却怒冲冲地走了。他说:“我以为他一定会出来见我,为我站着求告他的上帝耶和华,用手在我的患处晃一晃,医好我的麻风病。 12大马士革亚波纳河和法尔法河不比以色列所有的河都好吗?难道我在那里洗就不能得到洁净吗?”于是,他怒冲冲地转身走了。 13他的仆人上前对他说:“我父啊,先知若吩咐你做一件大事,难道你会不去做吗?何况他只是说你去洗洗就可以洁净!” 14乃缦就去约旦河,照上帝仆人的话在河里洗了七次,便洁净了,皮肤变得像小孩子的一样。

15乃缦率领全体随从回到上帝的仆人那里,站在他面前说:“如今我才知道,除了以色列,普天下没有上帝。请你收下仆人的礼物。” 16以利沙说:“我凭我事奉的永活上帝起誓,我决不接受。”乃缦再三请求,他仍不肯接受。 17乃缦说:“如果你不肯接受礼物,请你容许仆人用两头骡子驮些泥土回去。从此以后,我不再献燔祭或平安祭给其他神明,只献给耶和华。 18但有一件事,愿耶和华饶恕仆人。我主人进入临门庙祭拜时,他会扶着我的手,这样我也得随着他弯腰。若我在临门庙里弯腰,愿耶和华饶恕我。” 19以利沙对他说:“你安心地走吧。”

20乃缦刚走不远,上帝仆人以利沙的仆人基哈西心想:“我主人没有收亚兰乃缦带来的礼物就让他走了。我凭永活的耶和华起誓,我一定要追上去,向他要点东西。” 21他便去追赶乃缦乃缦见后面有人赶来,就下车迎接他,问他:“一切都好吗?” 22基哈西答道:“一切都好。我主人派我来告诉你,刚才有两位年轻的先知从以法莲山区来见他,请你赐给他们三十四公斤银子和两套衣服。” 23乃缦说:“请你拿走六十八公斤银子吧!”并再三请他接受,然后把六十八公斤银子装进两个袋子,连同两套衣服,交给他的两个仆人抬走,基哈西跟在他们后面。 24到了山冈,基哈西接过银子和衣服,放进屋里,便让他们回去了。 25基哈西进去侍立在以利沙面前,以利沙问他:“基哈西,你刚才去哪里了?”基哈西答道:“仆人哪里也没有去。” 26以利沙对他说:“那人下车回头迎接你的时候,我的心不也在那里吗?现在岂是接受人家银子、衣服、橄榄园、葡萄园、牛羊和仆婢的时候? 27因此,你和你的后代会永远沾染乃缦的麻风病。”基哈西离开以利沙时,患了麻风病,皮肤像雪一样白。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 5:1-27

Ìwòsàn Naamani adẹ́tẹ̀

1Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni Olúwa ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.

2Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. 3Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

4Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ. 5“Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìwọ̀n wúrà àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá. 6Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé, “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

7Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

8Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé, “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” 9Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa. 10Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”

11Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. 12Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.

13Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!” 14Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.

15Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

16Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò nígbà ohun kan,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Naamani rọ̀ ọ́ láti gbà á, ó kọ̀.

17Naamani wí pé, “Tí o kò bá nígbà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fi fún èmi ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ẹrù erùpẹ̀ tí ìbáaka méjì le rù, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rú ẹbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe sí Olúwa. 18Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí. Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rimoni láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rimoni, kí Olúwa dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

19Eliṣa wí pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.”

Lẹ́yìn ìgbà tí Naamani tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà, 20Gehasi, ìránṣẹ́ Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ́nú lórí Naamani, ará Aramu, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ní ọwọ́ rẹ̀.”

21Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáradára?” ó béèrè.

22“Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

23Naamani wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Gehasi láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Gehasi. 24Nígbà tí Gehasi sì dé ibi ilé ìṣọ́, ó gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, ó sì tó wọ́n sínú ilé, ó sì jọ̀wọ́ àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ lọ, wọ́n sì jáde lọ. 25Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa.

“Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè.

“Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn.

26Ṣùgbọ́n Eliṣa wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà olifi, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin? 27Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.