传道书 2 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

传道书 2:1-26

1我心里想:“来吧,不如尽情享乐,好好享受!”唉!结果这也是虚空。 2我说:“欢笑只不过是一阵狂妄,享乐又有什么用!” 3于是,我决意用酒使自己快乐,在体验愚昧的同时仍然保持理智,直到我明白在短暂的人生岁月中做何事才有益。 4我大动工程,为自己建造房屋,栽种葡萄园, 5开垦花圃园囿,种植各种果树, 6开凿池塘,浇灌茂林。 7我买了仆婢,又有生在家中的仆婢,拥有的牛羊远超过有史以来耶路撒冷的任何人。 8我为自己积聚金银,搜罗列王和各省的奇珍异宝,得到男女歌优及许多妃嫔——都是世人所想望的。 9这样,我便财势日增,享誉盛名,超过耶路撒冷历来所有的人。然而,我仍然保持智慧。 10凡我眼睛爱看的、心里渴慕的,我都随心所欲,尽情享受。我的心从劳碌中得到欢乐,这是我劳碌所得的回报。 11然而,当我回顾双手辛勤经营的一切成就时,唉,却发现都是虚空,都是捕风;日光之下的一切都毫无益处。 12于是,我转念思考什么是智慧、狂妄和愚昧。其实以后接替君王的人除了重演历史之外,还能做什么呢? 13我领悟到智慧胜过愚昧,如同光明胜过黑暗。 14智者高瞻远瞩,愚人却在黑暗中摸索。但我知道两者终必有同样的命运。 15于是,我想:“既然愚人的命运也将是我的命运,我有智慧又怎么样呢?我只能说,‘这也是虚空。’” 16因为智者和愚人一样,不过被人记得一时,日后都会被遗忘。两者都难逃死亡。 17所以,我憎恶生命,因为在日光之下所做的一切都令我愁烦。唉!这一切都是虚空,都是捕风。 18我憎恶自己在日光之下劳碌得来的一切,因为这些必留给后人。 19谁知道那人是智者还是愚人呢?然而,他却要接管我在日光之下用智慧辛勤经营的产业。这也是虚空。 20因此,我对自己在日光之下一切的劳碌感到绝望。 21一个人用智慧、知识和技能所得来的一切,却要留给不劳而获的人享用,这也是虚空,是极大的不幸! 22世人在日光之下劳心劳力,究竟得到什么呢? 23他们一生充满痛苦,劳碌中尽是愁烦,即使夜间心里也不安宁。这也是虚空。 24对人而言,没有什么比吃喝并享受劳碌之乐更好,我看这也是出自上帝的手。 25离了上帝,谁还能吃喝享受呢? 26上帝把智慧、知识和喜乐赐给祂喜悦的人,却让罪人忙于积攒财富,然后把他们的财富赐给祂喜悦的人。这也是虚空,也是捕风。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 2:1-26

Ìgbádùn

1Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. 2“Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” 3Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

42.4-8: 1Kọ 10.23-27; 2Ki 9.22-27.Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. 5Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. 6Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. 72.7: 1Ki 4.23.Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. 8Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. 9Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.

10Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.

N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.

Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,

èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.

11Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe

àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:

gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni

gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;

ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.

12Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,

àti ìsínwín àti àìgbọ́n

kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe

ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.

13Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀

gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.

14Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,

nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,

ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀

wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.

15Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,

“Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú

kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”

Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,

“Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”

16Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;

gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.

Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

Asán ni iṣẹ́ ṣíṣe

17Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. 18Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. 19Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. 20Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. 21Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. 22Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.

242.24: Su 3.13; 5.18; 9.7; Isa 56.12; Lk 12.19; 1Kọ 15.32.Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. 25Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? 26Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.