施洗者约翰预备道路
1有关上帝的儿子耶稣基督的福音是这样开始的。
2以赛亚先知书上说:
“看啊,
我要差遣我的使者在你前面为你预备道路。
3他在旷野大声呼喊,
‘预备主的道,
修直祂的路。’”
4果然,约翰出现了,他在旷野劝人悔改,接受洗礼,使罪得到赦免。 5犹太全境和耶路撒冷的居民都到约翰面前承认他们的罪,在约旦河里接受他的洗礼。
6约翰身穿骆驼毛的衣服,腰束皮带,吃的是蝗虫和野蜜。 7他传道说:“在我之后,有一位能力比我更大的要来,我连弯腰替祂解鞋带也不配。 8我是用水给你们施洗,但祂要用圣灵给你们施洗。”
耶稣受洗
9那时,耶稣从加利利的拿撒勒来约旦河接受约翰的洗礼。 10耶稣从水中一上来,就看见天开了,圣灵好像鸽子一样降在祂身上, 11从天上有声音说:“你是我的爱子,我甚喜悦你。”
耶稣受试探
12圣灵随即催促祂到旷野。 13祂在旷野受撒旦的试探四十天。祂与野兽在一起,有天使服侍祂。
呼召四渔夫
14约翰被捕后,耶稣来到加利利宣讲上帝的福音,说: 15“时候到了,上帝的国临近了,你们要悔改,相信福音。”
16耶稣沿着加利利湖边走,看见两个渔夫——西门和他的弟弟安得烈正在湖上撒网捕鱼。 17耶稣对他们说:“来跟从我!我要使你们成为得人的渔夫。” 18他们立刻抛下渔网,跟从了耶稣。
19耶稣往前走了不远,又看见西庇太的两个儿子雅各和约翰正在船上补网, 20便立刻呼召他们。他们就辞别父亲和船上的工人,跟从了耶稣。
传道赶鬼
21他们到了迦百农,耶稣在安息日去会堂里讲道。 22那里的人都很吃惊,因为祂教导他们时像个有权柄的人,不像律法教师。 23当时会堂里有一个被污鬼附身的人喊道: 24“拿撒勒的耶稣啊,我们和你有什么关系?你是来毁灭我们吗?我知道你是谁,你是上帝的圣者!”
25耶稣责备它说:“住口,从他身上出来!”
26污鬼使那人抽搐了一阵,大叫一声,就出来了。 27在场的人十分惊讶,彼此议论说:“这是怎么回事?真是充满权柄的新教导啊!竟然连污鬼都服从祂的命令。” 28于是,耶稣的名声立刻传遍了整个加利利。
医病赶鬼
29耶稣同雅各和约翰离开会堂,来到西门和安得烈家。 30当时西门的岳母正发烧,躺在床上,他们立刻把这事告诉耶稣。 31耶稣走到她的床边,拉着她的手扶她起来,她的烧立刻退了,便起来服侍他们。
32日落之后,有人把病人和被鬼附身的人都带来见耶稣。 33全城的人都聚在门前。 34耶稣医好了许多患各种疾病的人,又赶出很多鬼。祂不准鬼说话,因为鬼认识祂。
在加利利传道
35第二天清早,天还没亮,耶稣就起来独自走到旷野去祷告。 36西门和同伴们四处寻找耶稣, 37找到了,便对祂说:“大家都在找你呢!”
38耶稣却回答说:“我们到附近的乡镇去吧,我也好在那里传道,因为我就是为这事来的。”
39于是,耶稣走遍加利利,在各会堂传道,赶鬼。
治好麻风病人
40有一次,一个患麻风病的人来到耶稣面前,跪下央求:“只要你肯,一定能使我洁净。”
41耶稣动了慈心,就伸手摸他,说:“我肯,你洁净了吧!” 42那人的麻风病立即消失了,他就洁净了。 43耶稣让他回去并郑重地叮嘱: 44“不要把这事告诉别人,要去让祭司察看你的身体,并照摩西的规定献祭,向众人证明你已经洁净了。”
45但那人离开之后,却到处传扬这件事,以致耶稣无法再公开进城。祂只能待在城外的旷野,可是人们仍从各处来找祂。
Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀
1Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
21.2-8: Mt 3.1-12; Lk 3.2-16; Jh 1.6,15,19-28.1.2: Ml 3.1; Mt 11.10; Lk 7.27.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé:
“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
31.3: Isa 40.3.“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
41.4: Ap 13.24.Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. 5Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 6Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. 7Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. 8Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”
Ìtẹ̀bọmi àti ìdánwò Jesu
91.9-11: Mt 3.13-17; Lk 3.21-22; Jh 1.29-34.Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 111.11: Sm 2.7. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
121.12-13: Mt 4.1-11; Lk 4.1-13.Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
141.14-15: Mt 4.12-17; Lk 4.14-15.Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. 15Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.”
161.16-20: Mt 4.18-22; Lk 5.1-11; Jh 1.40-42.Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
19Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. 20Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Jesu lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde
211.21-22: Mt 7.28-29; Lk 4.31-32.Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. 22Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn. 231.23-28: Lk 4.33-37.Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, 241.24: Jh 6.69.“Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”
25Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” 26Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
27Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.” 28Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili.
Jesu mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá
291.29-31: Mt 8.14-15; Lk 4.38-39.Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. 30Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. 31Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
321.32-34: Mt 8.16-17; Lk 4.40-41.Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. 33Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. 34Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
Jesu ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti gbàdúrà
351.35-38: Lk 4.42-43.Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. 36Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. 37Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
38Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” 391.39: Mt 4.23-25; Lk 4.44.Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
Ọkùnrin tí o ní ààrùn ẹ̀tẹ̀
401.40-45: Mt 8.2-4; Lk 5.12-16.Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”
41Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” 42Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
43Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi 441.44: Le 13.49; 14.2-32.Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.” 45Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.