腓立比书 4 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible 2022 (Simplified)

腓立比书 4:1-23

保罗的劝勉

1我所亲爱、所想念的弟兄姊妹,你们就是我的喜乐和冠冕。我亲爱的弟兄姊妹,你们要靠主坚定不移。 2我恳求友阿蝶循都姬要在主里同心。 3信实的同工啊,请你帮助她们二人,因为她们曾与我、革利免和其他同工一起为福音辛劳,这些人的名字都在生命册上。

4你们要靠主常常喜乐!我再说,你们要喜乐! 5要让众人都知道你们是谦和宽容的人。主快来了。 6你们应该一无挂虑,凡事要借着祷告和祈求,怀着感恩把你们的需要告诉上帝。 7这样,上帝那超越人所能理解的平安必在基督耶稣里保守你们的心思意念。

8最后,弟兄姊妹,你们要思想一切真实、可敬、公义、纯洁、可爱、有好名声、有美德和值得赞许的事情。 9你们从我身上学习、领受、看到和听到的,都要付诸实践。这样,赐平安的上帝就必与你们同在。

致谢

10我靠主非常喜乐,因为你们现在又一次关心我。其实你们向来都很关心我,只是没有机会。 11我并非因为缺乏才这样说,因为我已经学会在任何处境中都能知足。 12我知道如何过贫穷的日子,也知道如何过富足的日子。我学到了秘诀,不论饱足或饥饿,丰裕或缺乏,在任何情况下都可以处之泰然。 13靠着赐我力量的那位,我凡事都能做。

14然而,你们与我共患难,真是美好。 15腓立比人啊!你们也知道,在我离开马其顿传福音的初期,除了你们以外,没有别的教会供应我的需要。 16即使我在帖撒罗尼迦的时候,你们也不止一次供应过我的需要。 17我不求得到馈赠,只求有更多成果归在你们账上。 18我现在样样都有,丰富有余。我从以巴弗提手上收到了你们送给我的礼物,已经充足了。这些馈赠是蒙上帝悦纳的馨香祭物。 19我的上帝必按照祂在基督耶稣里的荣耀,丰丰富富地赐给你们所需用的一切。

20愿荣耀归给我们的父上帝,直到永永远远。阿们!

问候

21请代我问候在基督耶稣里的众圣徒。我这里的弟兄姊妹也问候你们。 22所有的圣徒,特别是在凯撒宫里的人,都问候你们。

23愿主耶稣基督的恩典与你们的灵同在!

Yoruba Contemporary Bible

Filipi 4:1-23

1Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú

2Èmi ń bẹ̀ Euodia, mo sì ń bẹ Sintike, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa. 34.3: Lk 10.20.Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.

4Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 64.6: Mt 6.25-34.Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

8Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. 94.9: Ro 15.33.Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.

Àwọn ọpẹ́ fún àwọn ẹ̀bùn wọn

104.10: 2Kọ 11.9.Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó. 11Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 134.13: 2Kọ 12.9.Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

14Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. 15Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. 164.16: Ap 17.1-9; 1Tẹ 2.9.Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. 17Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín 18Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì tún ni lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. 19Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.

20Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.

Ọ̀rọ̀ ìkíni ìkẹyìn

21Ẹ kí olúkúlùkù ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu.

Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín.

22Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari.

234.23: Ga 6.18; Fm 25.Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.