效法基督
1所以,你们如果在基督里受到鼓励,得到爱的安慰,与圣灵相通,有慈悲和怜悯之心, 2就要同心合意,彼此相爱,灵里合一,思想一致,好让我的喜乐满溢。 3凡事不可自私自利、爱慕虚荣,要心存谦卑,看别人比自己强。 4各人不要只顾自己的事,也要顾别人的事。 5你们应当有基督耶稣那样的心意。
6祂虽然本质上是上帝,
却不紧抓与上帝同等之位,
7反而甘愿放下一切,
取了奴仆的形象,
降生为人的样子。
8祂以人的样子出现后,
就自愿卑微,顺服至死,
而且死在十字架上。
9因此,上帝将祂升为至尊,
赐给祂超乎万名之上的名,
10使一切天上的、
地上的和地底下的,
无不屈膝跪拜在耶稣的名下,
11无不口称耶稣基督是主,
将荣耀归于父上帝。
暗世明灯
12所以,我亲爱的弟兄姊妹,你们一向都很顺服,不只是当着我的面时才顺服,我不在时你们更加顺服,要战战兢兢地活出你们的救恩。 13因为你们立志和行事都是上帝在你们心中工作,为要成就祂美好的旨意。
14无论做什么事,都不要抱怨,也不要与人争论, 15好使你们在这个扭曲乖谬的时代中清白无过,做上帝纯洁无瑕的儿女,2:15 申命记32:5。如同明光照耀在世上, 16坚守生命之道。这样,到了基督再来的时候,我可以夸口自己没有空跑一场,也没有白费功夫。 17你们的信心就是献给上帝的祭物,即使在上面浇奠我的生命,我也很喜乐,并且和大家一同喜乐。 18同样,你们也要喜乐,要和我一同喜乐。
保罗的得力同工
19靠着主耶稣,我希望尽快派提摩太去你们那里,好知道你们的近况,使我也感到欣慰。 20因为没有人像他那样跟我一同真正关心你们的事。 21别人都只顾自己的事,不顾耶稣基督的事。 22但你们知道提摩太的为人,他与我在福音事工上一起服侍,情同父子。 23所以,我的案子一旦明朗了,我会立刻派他去见你们。 24我靠主深信自己很快也会去你们那里。
25另外,我觉得有必要让以巴弗提回到你们那里。他是我的弟兄、同工和战友,也是你们差遣来服侍我、供应我需用的。 26他很想念你们各位,并且感到不安,因为你们听说了他患病的事。 27他确实病了,几乎丧命,但上帝怜悯了他,不但怜悯他,也怜悯了我,没让我忧上加忧。 28所以,我想尽快派他回去与你们相聚,好让你们喜乐,也可以减少我的挂虑。 29你们要在主里欢欢喜喜地接待他,而且要敬重像他这样的人, 30因为他冒着生命危险弥补你们服侍我的不足之处,为了基督的工作几乎丧命。
Kọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Kristi
12.1: 2Kọ 13.14.Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, 2síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà. 32.3-4: Ro 12.10; 15.1-2.Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ. 4Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.
52.5-8: Mt 11.29; 20.28; Jh 1.1; 2Kọ 8.9; Hb 5.8.Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.
6Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,
kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
7Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,
ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,
a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
8Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,
ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,
o sì tẹríba títí de ojú ikú,
àní ikú lórí àgbélébùú.
92.9-11: Ro 10.9; 14.9; Ef 1.20-21.Nítorí náà, Ọlọ́run
ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,
ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un
10Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,
ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
11Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,
fún ògo Ọlọ́run Baba.
Títàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ìràwọ̀
12Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 132.13: 1Kọ 15.10.Nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.
14Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn. 152.15: Mt 5.45,48.Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé. 16Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. 17Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. 18Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.
Timotiu àti Epafiroditu
19Mo ni ìrètí nínú Jesu Olúwa, láti rán Timotiu sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúròó yín. 20Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín. 21Nítorí gbogbo wọn ni ó tọ́jú nǹkan ti ara wọn, kì í ṣe àwọn nǹkan ti Jesu Kristi. 22Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé Timotiu pegedé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀, nínú iṣẹ́ ìhìnrere. 23Nítorí náà, mo ní ìrètí láti rán sí yín ní àìpẹ́ tí mo bá wòye bí yóò ti rí fún mi. 24Ṣùgbọ́n mo ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, pé èmi tìkára mi pẹ̀lú yóò wá ní àìpẹ́.
25Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epafiroditu arákùnrin mi sí yín, àti olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi. 26Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn. 27Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́. 28Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù. 29Nítorí náà, ẹ fi ayọ̀ púpọ̀ gbà á nínú Olúwa; kí ẹ sì máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. 30Nítorí iṣẹ́ Kristi ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.