Chinese Contemporary Bible (Simplified)

箴言 18:1-24

1孤傲者独善其身,

他恼恨一切真知。

2愚人不喜欢悟性,

只喜欢发表意见。

3邪恶与藐视同行,

无耻与羞辱为伴。

4人口中的话如同深水,

智慧之泉像涓涓溪流。

5袒护恶人、冤枉义人都为不善。

6愚人说话引起纷争,

他的口招来鞭打。

7愚人的口自招灭亡,

他的嘴坑害他自己。

8闲言碎语如同美食,

深入人的五脏六腑。

9懒惰人与毁坏者臭味相投。

10耶和华的名是坚固保障,

义人投奔其中就得安稳。

11财富是富人的坚城,

在他幻想中是高墙。

12骄傲是败亡的前奏,

谦虚是尊荣的先锋。

13未听先答的人,

自显愚昧和羞辱。

14人的心灵能忍受疾病,

谁能忍受破碎的心灵?

15哲士的心得知识,

智者的耳求知识。

16礼物为人开路,

领人晋见权贵。

17先告状的看似有理,

一经对质真相大白。

18抽签可以平息争端,

调解强者间的纠纷。

19与结怨的兄弟和解比攻城还难,

争端难破,如坚城的门闩。

20人因口中所说的话而饱足,

因嘴中所出的言语而满足。

21口舌能够定生死,

多嘴多言食恶果。

22得到妻子就是得到珍宝,

也是蒙了耶和华的恩惠。

23穷人哀声恳求,

富人恶言相向。

24滥交友,自招损;

得知己,胜手足。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Òwe 18:1-24

1Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;

ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.

2Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye

ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.

3Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,

nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.

4Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,

ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.

5Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú

tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.

6Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀

ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.

7Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́

ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.

8Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn

wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

9Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀

arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.

10Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;

olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.

11Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn

wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

12Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga

ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

13Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,

èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.

14Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn

ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.

15Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;

etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.

16Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn

a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.

17Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre

títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.

18Ìbò dídì máa ń parí ìjà

a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.

19Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,

ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.

20Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;

láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.

21Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,

àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.

22Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,

o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.

23Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,

ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.

24Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun

ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.