1我是奉上帝旨意做基督耶稣使徒的保罗,同提摩太弟兄, 2写信给歌罗西的圣徒,就是忠于基督的弟兄姊妹。
愿我们的父上帝赐给你们恩典和平安!
感恩与祷告
3-4我们听说了你们对基督耶稣的信心和对众圣徒的爱心,为你们祷告的时候,常常感谢我们主耶稣基督的父上帝。 5你们能有这样的信心和爱心是因为那为你们存在天上的盼望,就是你们之前从福音真道中听到的盼望。 6这福音不但传到了你们那里,也传到了世界各地,不断结出果实并发展壮大,正如你们当初听了福音并真正明白上帝恩典后的情形。 7这福音是你们从我们亲爱的同工以巴弗那里学到的。他代表我们1:7 “我们”有古卷作“你们”。做基督的忠仆, 8并把圣灵赐给你们的爱心告诉了我们。
9因此,从听到你们的消息那天起,我们便不断地为你们祷告,求上帝使你们在一切属灵的智慧和悟性上完全明白祂的旨意, 10以便你们行事为人对得起主,凡事蒙祂喜悦,在一切善事上结出果实,对上帝的认识不断增加。 11愿上帝用祂荣耀的权能使你们刚强,无论遇到什么事都能长久忍耐, 12欢喜地感谢天父,因祂使你们有资格跟众圣徒在光明中同享基业。 13祂把我们从黑暗的权势下拯救出来,迁入祂爱子的国度里。 14我们借着祂的爱子蒙救赎,罪得到赦免。
基督超越一切
15爱子是那不能看见之上帝的真像,超越1:15 “超越”或译“先存于”,希腊文是“长子”,常用来指地位上的优越或时间上的优先。一切受造之物。 16因为万物都是借着祂创造的,天上的、地上的、有形的、无形的、做王的、统治的、执政的、掌权的,一切都是借着祂也是为了祂而创造的。 17祂存在于万物之先,万物都靠祂维系。 18祂是教会的头,教会是祂的身体;祂是开始,是首先从死里复活的,好在一切事上居首位。 19因为上帝乐意让一切的丰盛住在祂里面, 20又借着祂在十字架上所流的血成就了和平,使天地万物借着祂与上帝和好。
21你们从前与上帝隔绝,行事邪恶,心思意念与祂为敌; 22但现在上帝借着基督肉身的死使你们与祂和好了,让你们在祂面前成为圣洁无瑕、无可指责的人。 23只是你们必须恒心持守所信的道,根基稳固,坚定不移,不要失去你们听到福音后所得到的盼望。这福音传给了天下万民。我保罗也做了这福音的使者。
保罗为教会受苦
24我现在因着能为你们受苦而欢喜,并且我是为基督的身体——教会的缘故,在自己身上补满基督未受尽的苦难。 25我受上帝的委派成为教会的仆人,要把上帝的道完整地传给你们。 26这道是历世历代一直隐藏的奥秘,现在已经向祂的众圣徒显明了。 27上帝要他们知道这奥秘在外族人中有何等丰盛的荣耀,这奥秘就是:基督在你们里面,使你们有荣耀的盼望。 28我们传扬基督,用一切智慧劝诫、教导众人,使他们在基督里长大成熟,好把他们交给上帝。 29为此,我按着祂在我身上运行的大能尽心竭力,不辞劳苦。
1Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa.
21.2: Ro 1.7.Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose.
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.
Àwọn ọpẹ́ àti àdúrà
31.3: Ef 1.16.Nígbàkúgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 4Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 5Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìhìnrere náà, 6èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀. 71.7: Kl 4.12; Fm 23.Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa. 8Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
91.9: Ef 1.15-17.Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 131.13: Ef 1.21; 2.2.Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
Títóbi Kristi
151.15: 2Kọ 4.4.Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. 16Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. 171.17: Òw 8.22-31.Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. 181.18: Ef 4.15.Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. 20Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.
21Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín. 22Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi, 23bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìhìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.
Iṣẹ́ Paulu ṣíṣe fún àwọn ìjọ
24Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ. 251.25: Ef 3.2.Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. 261.26: Ef 3.9.Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́. 27Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín.
28Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kristi. 29Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń ṣiṣẹ́ nínú mi.