1天使又让我看一道流淌着生命水的河,清澈如水晶,从上帝和羔羊的宝座那里流出, 2从城内的大街中间穿过,河两岸有结十二种果子的生命树,每个月都结果子,叶子能医治万民。 3再也没有咒诅,城里有上帝和羔羊的宝座,祂的奴仆都要事奉祂。 4他们必见上帝的面,上帝的名字必印在他们的额上。 5再没有黑夜,也不需要灯光和阳光,因为主上帝必做他们的光。他们要执掌王权直到永永远远。
基督的再来
6天使对我说:“这些话真实可靠。赐圣灵感动众先知的主上帝已差遣祂的天使,将很快必发生的事指示给祂的奴仆们。”
7“看啊,我快要来了。遵行这书中预言的人有福了!”
8以上都是我约翰的所见所闻。我耳闻目睹这些事后,就俯伏敬拜让我看这些事的天使。 9天使对我说:“千万不可!我与你、你的众先知弟兄和那些遵行这书上话语的人同是上帝的奴仆,你要敬拜上帝。”
10他又对我说:“不可封住这卷书上的预言,因为时候快到了。 11不义的,让他继续不义;污秽的,让他继续污秽;公义的,让他保持公义;圣洁的,让他保持圣洁。”
12“看啊,我快要来了,赏罚在我,我要按各人的行为施行赏罚。 13我是阿拉法,我是俄梅加;我是首先的,我是末后的;我是开始,我是终结。 14那些洗净自己衣裳的人有福了!他们有权得生命树的果子,也可以从城门进入城中。 15那些如同恶犬的败类、行邪术的、淫乱的、杀人的、拜偶像的和一切喜欢弄虚作假的,都要被拒之城外。 16我耶稣差遣我的天使到众教会,向你们证明这些事。我是大卫的根,也是大卫的后裔,又是明亮的晨星。”
17圣灵和新娘都说:“来吧!”听见的也要说:“来吧!”口渴的,让他来吧!愿意的,让他白白地享用生命水吧!
警告
18我警告所有听见这书上预言的人:如果谁在这书上增添什么,上帝必将这书上所记载的灾祸加在他身上; 19如果有人从这预言书上删减什么,上帝必使他无份于这书上所记载的生命树和圣城。
20那位证明这些事的说:“是的,我快要来了。”阿们!主耶稣啊,我愿你来!
21愿主耶稣的恩典与众圣徒同在。阿们!
Omi iyè
1Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí Kirisitali, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá, 222.2: Gẹ 2.9.Ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà. 322.3: Sk 14.11.Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín: 422.4: Sm 17.15.Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn. 5Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé.
6Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”
7“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”
8Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi, 9Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”
10Ó sì wí fún mi pé, “má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀. 1122.11: Da 12.10.Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só: àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só: àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”
1222.12: Isa 40.10; Jr 17.10.“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí. 1322.13: Isa 44.6; 48.12.Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.
14“Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà. 15Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.
16“Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”
1722.17: Isa 55.1.Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.
18Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. 19Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.
20Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.”
Àmín, Máa bọ̀, Jesu Olúwa!
2122.21: 2Tẹ 3.18.Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àmín.