以色列的后裔
1以色列的儿子是吕便、西缅、利未、犹大、以萨迦、西布伦、 2但、约瑟、便雅悯、拿弗他利、迦得和亚设。
犹大的后裔
3犹大的儿子是珥、俄南和示拉。这三人是迦南人书亚的女儿生的。犹大的长子珥在耶和华眼中是个邪恶的人,因而被耶和华击杀了。 4犹大的儿媳她玛给犹大生了法勒斯和谢拉。犹大共有五个儿子。 5法勒斯的儿子是希斯仑和哈姆勒。 6谢拉的五个儿子是心利、以探、希幔、甲各、大拉。 7迦米的儿子是亚干,这亚干私藏本该毁灭之物,连累了以色列人。 8以探的儿子是亚撒利雅。
9希斯仑的儿子是耶拉篾、兰和迦勒2:9 “迦勒”希伯来文是“基路拜”,“迦勒”的另一种拼法。。 10兰生亚米拿达,亚米拿达生拿顺,拿顺是犹大人的首领。 11拿顺生撒门,撒门生波阿斯, 12波阿斯生俄备得,俄备得生耶西。 13耶西生长子以利押、次子亚比拿达、三子示米亚、 14四子拿坦业、五子拉代、 15六子阿鲜、七子大卫。 16他们的姊妹是洗鲁雅和亚比该。洗鲁雅的三个儿子是亚比筛、约押和亚撒黑。 17亚比该生亚玛撒,亚玛撒的父亲是以实玛利人益帖。
希斯仑的后裔
18希斯仑的儿子迦勒和妻子阿苏巴生了儿子,他也和耶略生了儿子。阿苏巴的儿子是耶设、朔罢和押墩。 19阿苏巴死后,迦勒又娶了以法她,生了户珥。 20户珥生乌利,乌利生比撒列。 21希斯仑六十岁娶玛吉的女儿,与她生了西割。玛吉是基列的父亲。 22西割生雅珥,雅珥在基列有二十三座城邑。 23后来基述人和亚兰人夺取了雅珥的城邑,包括基纳及其附近的六十个村落。这些人都是基列的父亲玛吉的后代。 24希斯仑死在迦勒·以法他后,他的妻子亚比雅给他生了亚施户。亚施户是提哥亚的父亲。
耶拉篾的后裔
25希斯仑的长子耶拉篾生了长子兰,又生了布拿、阿连、阿鲜、亚希雅。 26耶拉篾的另一个妻子名叫亚她拉,是阿南的母亲。 27耶拉篾的长子兰的儿子是玛斯、雅悯和以结。 28阿南的儿子是沙迈和雅大。沙迈的儿子是拿答和亚比述。 29亚比述的妻子名叫亚比孩,她给丈夫生了亚班和摩利。 30拿答的儿子是西列和亚遍。西列死后没有留下儿子。 31亚遍的儿子是以示,以示的儿子是示珊,示珊的儿子是亚来。 32沙迈的兄弟雅大的儿子是益帖和约拿单。益帖死后没有留下儿子。 33约拿单的儿子是比勒和撒萨。这些人都是耶拉篾的子孙。 34示珊没有儿子,只有女儿,还有一个名叫耶哈的埃及仆人。 35示珊把女儿嫁给仆人耶哈,她给丈夫生了亚太。 36亚太生拿单,拿单生撒拔, 37撒拔生以弗拉,以弗拉生俄备得, 38俄备得生耶户,耶户生亚撒利雅, 39亚撒利雅生希利斯,希利斯生以利亚萨, 40以利亚萨生西斯迈,西斯迈生沙龙, 41沙龙生耶加米雅,耶加米雅生以利沙玛。
迦勒的后裔
42耶拉篾的兄弟迦勒的长子是西弗的父亲米沙,希伯伦的父亲玛利沙也是迦勒的儿子。 43希伯伦的儿子是可拉、他普亚、利肯、示玛。 44示玛生拉含,拉含是约干的父亲。利肯生沙迈, 45沙迈的儿子是玛云,玛云是伯·夙的父亲。 46迦勒的妾以法生哈兰、摩撒和迦谢。哈兰生迦谐。 47雅代的儿子是利健、约坦、基珊、毗力、以法、沙亚弗。 48迦勒的妾玛迦生示别、特哈拿、 49麦玛拿的父亲沙亚弗、抹比拿和基比亚的父亲示法。迦勒的女儿是押撒。 50这些人都是迦勒的子孙。以法她的长子户珥生基列·耶琳的父亲朔巴、 51伯利恒的父亲萨玛、伯迦得的父亲哈勒。 52基列·耶琳的父亲朔巴的子孙是哈罗以和半数米努·哈人。 53基列·耶琳的各宗族是以帖人、布特人、舒玛人、密来人,从这些宗族中又衍生出琐拉人和以实陶人。 54萨玛的后代是伯利恒人、尼陀法人、亚他绿·伯·约押人、半数玛拿哈人、琐利人, 55以及住在雅比斯的文书世家特拉人、示米押人和苏甲人。这些都是基尼人,是利甲家族的祖先哈末的后代。
Àwọn ọmọ Israẹli
12.1-2: Gẹ 35.23-26.Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, 2Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.
Juda
Àwọn ọmọ Hesroni
32.3-4: Gẹ 38.3-7,29-30; Nu 26.19,20.Àwọn ọmọ Juda:
Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua.
Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.
52.5: Gẹ 46.12; Gẹ 26.21.Àwọn ọmọ Peresi:
Hesroni àti Hamulu.
6Àwọn ọmọ Sera:
Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7Àwọn ọmọ Karmi:
Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8Àwọn ọmọ Etani:
Asariah.
9Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni:
Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni
10Ramu sì ni baba Amminadabu,
àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
11Nahiṣoni sì ni baba Salmoni,
Salmoni ni baba Boasi,
12Boasi baba Obedi
àti Obedi baba Jese.
13Jese sì ni baba
Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu,
ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, 14Ẹlẹ́kẹrin Netaneli,
ẹlẹ́karùnún Raddai, 15ẹlẹ́kẹfà Osemu
àti ẹlẹ́keje Dafidi.
16Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili.
Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli.
17Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.
Kalebu ọmọ Hesroni
18Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀:
Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.
19Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.
20Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli.
21Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu.
22Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.
23(Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.)
Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri Baba Gileadi.
24Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un.
Jerahmeeli ọmọ Hesroni
25Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni:
Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah. 26Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu.
27Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli:
Maasi, Jamini àti Ekeri.
28Àwọn ọmọ Onamu:
Ṣammai àti Jada.
Àwọn ọmọ Ṣammai:
Nadabu àti Abiṣuri. 29Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi.
30Àwọn ọmọ Nadabu
Ṣeledi àti Appaimu. Ṣeledi sì kú láìsí ọmọ.
31Àwọn ọmọ Appaimu:
Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai.
32Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai:
Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ.
33Àwọn ọmọ Jonatani:
Peleti àti Sasa.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli.
34Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.
Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha. 35Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.
36Attai sì jẹ́ baba fún Natani,
Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,
37Sabadi ni baba Eflali,
Eflali jẹ́ baba Obedi,
38Obedi sì ni baba Jehu,
Jehu ni baba Asariah,
39Asariah sì ni baba Helesi,
Helesi ni baba Eleasa,
40Eleasa ni baba Sismai,
Sismai ni baba Ṣallumu,
41Ṣallumu sì ni baba Jekamiah,
Jekamiah sì ni baba Eliṣama.
Ìdílé Kalebu
42Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli:
Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi,
àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
43Àwọn ọmọ Hebroni:
Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.
44Ṣema ni baba Rahamu,
Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu.
Rekemu sì ni baba Ṣammai.
45Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni,
Maoni sì ni baba Beti-Suri.
46Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá
Harani, Mosa àti Gasesi,
Harani sì ni baba Gasesi.
47Àwọn ọmọ Jahdai:
Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafa.
48Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá
Seberi àti Tirhana.
49Ó sì bí Ṣaafa baba Madmana,
Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah.
ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.
50Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu.
Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata:
Ṣobali baba Kiriati-Jearimu. 51Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.
52Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni:
Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti. 53Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.
54Àwọn ọmọ Salma:
Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori, 55Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.