基督徒的自由
1基督释放了我们,好让我们得自由。所以,要站稳了,不要再被奴仆的轭辖制。
2听着!我保罗郑重地告诉你们,如果你们接受割礼,基督对你们就毫无益处。 3我再次警告所有接受割礼的人,他们必须遵守全部的律法。 4你们若想靠遵行律法被称为义人,就与基督隔绝了,并且离开了上帝的恩典。 5但我们要靠着圣灵,凭信心热切等候所盼望的义。 6因为在基督耶稣里,受不受割礼根本无关紧要,借着爱表现出来的信心才至关重要。
7你们本来在信心的路上一直跑得很好。现在是谁拦阻了你们,叫你们不再信从真理呢? 8这种劝导当然不是出于呼召你们的上帝! 9“一点面酵能使整团面发起来。” 10我在主里深信你们不会有二心,但无论谁搅扰你们,都必受惩罚。
11弟兄姊妹,我如果仍旧主张行割礼,怎么还会受迫害呢?如果是那样,十字架冒犯人的地方就被消除了。 12我恨不得那些搅扰你们的人把自己阉了5:12 “把自己阉了”或作“与你们隔离”。!
13弟兄姊妹,你们蒙召得了自由,但不要以自由为借口来放纵本性,要本着爱心互相服侍, 14因为全部的律法可以总结成一句话:“要爱邻如己。”5:14 利未记19:18。 15你们要谨慎,如果你们相咬相吞,恐怕会同归于尽。
顺从圣灵
16因此,我劝你们行事为人要顺从圣灵的引导,这样就不会放纵本性的私欲。 17因为人本性的私欲与圣灵作对,圣灵也与人本性的私欲作对,两者势不两立,使你们不能做自己想做的事。 18但你们如果顺从圣灵的引导,就不在律法之下。 19顺从本性去做的事显而易见,如淫乱、污秽、邪荡、 20拜偶像、行邪术、仇恨、争斗、忌恨、恼怒、纷争、冲突、分裂5:20 “分裂”或译“异端”。、 21嫉妒、凶杀、醉酒和荒宴无度等。我从前警告过你们,现在再一次警告你们:行这些事的人必不能承受上帝的国。
22但圣灵所结的果子是仁爱、喜乐、和平、忍耐、恩慈、良善、信实、 23温柔、自制。没有律法会禁止这些事。 24那些属基督耶稣的人,已经把本性及其邪情私欲都钉在十字架上了。 25我们如果是靠圣灵生活,就当凡事顺从圣灵的引导。 26我们不要自高自大,彼此惹气,互相嫉妒。
Òmìnira nínú Jesu
1Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.
2Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun. 3Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́. 4A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́. 5Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. 65.6: 1Kọ 7.19; Ga 6.15.Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
7Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? 8Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. 95.9: 1Kọ 5.6.Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. 10Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. 11Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò. 12Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò.
13Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín. 145.14: Le 19.18; Ro 13.8-10.Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” 15Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.
Ìyè nípa ti ẹ̀mí
16Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. 175.17: Ro 7.15-23.Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. 18Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.
195.19: Ro 1.28.Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
22Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, 24Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 25Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí. 26Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣe ògo asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.