众使徒接纳保罗
1十四年后,我和巴拿巴又去耶路撒冷,并带了提多同去。 2我是遵照上帝的启示去的。我私下拜会了那些有名望的教会领袖,陈明我在外族人中间所传的福音,免得我过去或是现在的努力都白费了。 3跟我同去的提多虽然是希腊人,也没有人勉强他接受割礼。
4事情的缘由是因为有一些假信徒偷偷混了进来,要窥探我们在基督耶稣里享有的自由,想叫我们做律法的奴隶。 5但为了叫福音的真理常在你们当中,我们丝毫没有向他们妥协。
6至于那些德高望重的教会领袖,他们的地位对我来说无关紧要,因为上帝不以貌取人。他们对我所传的并没有增加什么。 7相反,他们都已看到,上帝委托我向外族人传福音,就像祂委托彼得向犹太人传福音一样。 8上帝感动了彼得,呼召他做犹太人的使徒,祂也同样感动了我,呼召我做外族人的使徒。 9当时被誉为教会柱石的雅各、矶法和约翰明白了上帝赐给我的恩典之后,就与我和巴拿巴用右手行相交之礼,让我们向外族人传福音,他们向受割礼的人传福音。 10他们只要求我们顾念那些贫困的人,这正是我一向热衷的事。
保罗面责矶法
11后来,矶法到了安提阿,因他做错了事,我就当面反对他。 12从雅各那里来的人抵达之前,他和外族的信徒一起吃饭。但那些人抵达以后,他因为怕那些坚持行割礼的犹太人批评,就与外族的信徒分开了。 13其他犹太基督徒也跟着他装假,甚至连巴拿巴也随从了他们的虚伪。 14我看见他们不照福音的真理行,就当众对矶法说:“你身为犹太人,如果行事为人像外族人,不像犹太人,又怎能强迫外族人按犹太人的规矩生活呢?”
15我们生来是犹太人,不是外族罪人, 16但我们知道人被称为义人不是靠遵行律法,而是靠信耶稣基督。所以我们信了基督耶稣,以便因信基督被称为义人,而不是靠遵行律法,因为无人能够靠遵行律法被称为义人。 17如果我们寻求在基督里被称为义人,结果却仍是罪人,难道基督助长罪恶吗?当然不是!
18倘若我重建我所拆毁的东西,就表明我是罪人。 19其实,我因无法满足律法的要求而向律法死了,使我可以为上帝而活。 20我已经与基督一同被钉在十字架上,现在活着的不再是我,而是基督活在我里面。我如今活在肉身中的生命是靠信上帝的儿子活着,祂爱我,为我舍命。 21我不废弃上帝的恩典,倘若靠遵行律法可以得到义,基督的死便毫无意义了。
Àwọn aposteli tẹ́wọ́ gba Paulu
12.1: Ap 15.2.Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. 2Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìhìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. 3Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. 4Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. 52.5: Ap 15.23-29.Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà.
62.6: De 10.17.Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. 7Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìhìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìhìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. 8Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. 9Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. 10Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.
Paulu tako Peteru
112.11: Ap 11.19-26.Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.
14Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?
15“Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’ 162.16: Sm 143.2; Ro 3.20.Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.
17“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin.
19“Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. 202.20: Ga 1.4.A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. 21Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”