以色列人受欺压
1以色列的众子带着家眷跟雅各1:1 “雅各”就是“以色列”,上帝为雅各改名以色列,故事参考创世记32:28。一起去了埃及,以下是他们的名字: 2吕便、西缅、利未、犹大、 3以萨迦、西布伦、便雅悯、 4但、拿弗他利、迦得、亚设。 5雅各的子孙总共有七十人。那时,约瑟已经住在埃及。 6后来,约瑟和他的弟兄以及同辈的人都相继去世。 7以色列人生养众多,人口大增,很快就遍布埃及,成为一个强大的民族。 8那时,埃及有一位不认识约瑟的新王登基, 9对他的百姓说:“你们看,以色列人比我们多,又比我们强。 10来吧!我们要设法阻止他们人口增长,否则一遇到战争,他们便会加入我们敌人的阵营来攻打我们,然后一走了之。”
11于是,埃及人派监工强迫以色列人服劳役,在比东和兰塞两地为法老兴建储货城。 12以色列人越受奴役,人口增长得越快,散居的范围也越广,令埃及人感到恐惧。 13于是,埃及人更残酷地奴役他们, 14强迫他们和泥造砖,并做田间一切的苦工,使他们痛苦不堪。 15埃及王又命令两个希伯来的接生婆施弗拉和普阿: 16“你们在替希伯来妇女接生的时候,如果看到生下的是男婴,就把他杀掉;如果是女婴,就让她活下来。” 17但这两个接生婆敬畏上帝,没有执行王的命令,而是保留了男婴的性命。 18埃及王召见那两个接生婆,质问她们:“你们为什么这样做?为什么让男婴活着?” 19她们回答说:“因为希伯来妇女跟埃及妇女不同。她们身体强健,我们还没有赶到,婴儿就生下来了。” 20-21因此,以色列人口继续增加,更加繁盛。因为这两个接生婆敬畏上帝,上帝便赐福给她们,使她们生儿育女。 22后来,法老命令全埃及的人把以色列人生的所有男婴都抛进尼罗河里,只让女婴活着。
A ni àwọn ọmọ Israẹli lára
11.1-4: Gẹ 46.8-27; Nu 26.4-50.Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ejibiti, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀:
2Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda;
3Isakari, Sebuluni àti Benjamini;
4Dani àti Naftali;
Gadi àti Aṣeri.
51.5-8: Ap 7.14-18.Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti.
6Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, 71.7: Ap 7.17.ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.
81.8: Ap 7.18.Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 9Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. 101.10,11,22: Ap 7.19.Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”
11Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao. 12Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tànkálẹ̀. Nítorí náà, àwọn ará Ejibiti bẹ̀rù nítorí àwọn ará Israẹli. 13Àwọn ará Ejibiti sì mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àsìnpa. 14Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò.
15Ọba Ejibiti sọ fún àwọn agbẹ̀bí Heberu ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifura àti Pua pé, 16“Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.” 17Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè. 18Ọba Ejibiti pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?”
19Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Heberu kò rí bí àwọn obìnrin Ejibiti, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
20Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Israẹli sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ. 21Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé tiwọn.
221.22: Ap 7.19.Nígbà náà ni Farao pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Naili, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láààyè.”