Узайр 1 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Узайр 1:1-11

Указ Куруша о возвращении пленников

(2 Лет. 36:22-23)

1В первый год правления Куруша1:1 Куруш II Великий, основатель Персидского государства Ахменидов, правил с 558 по 530 гг. до н. э. В 539 г. покорил Вавилон и Месопотамию. Куруш погиб во время похода в Центральную Азию от руки сакской царицы Томирис., царя Персии (в 538 г. до н. э.), чтобы исполнилось слово Вечного1:1 Вечный – на языке оригинала: «Яхве». Под этим именем Всевышний открылся Мусо и народу Исроила (см. Исх. 3:13-15). См. пояснительный словарь., которое возвестил Иеремия1:1 См. Иер. 29:10-14., Вечный побудил Куруша, царя Персии, объявить по всему своему царству и записать такой указ:

2«Так говорит Куруш, царь Персии: Вечный, Бог небес, отдал мне все царства земли и поручил мне построить Ему храм в Иерусалиме, в Иудее. 3Всякий из вас, кто принадлежит к Его народу, – да будет с ним его Бог! – может отправляться в Иерусалим, в Иудею, и строить храм Вечного, Бога Исроила, Бога, Который в Иерусалиме. 4И пусть жители тех мест, где сейчас живут уцелевшие иудеи, снабдят их серебром и золотом, имуществом и скотом и добровольными пожертвованиями для храма Всевышнего в Иерусалиме».

5И главы семейств из родов Иуды и Вениамина со священнослужителями и левитами – всякий, кого побудил Всевышний, – стали собираться, чтобы пойти и отстроить дом Вечного в Иерусалиме. 6Все их соседи помогли им серебряными и золотыми вещами, имуществом и скотом и дорогими дарами, не считая всех добровольных пожертвований. 7Сам царь Куруш вынес утварь храма Вечного, которую Навуходоносор1:7 Царь Навуходоносор II, самый великий царь Нововавилонской империи, правил с 605 по 562 гг. до н. э. забрал из Иерусалима и положил в храме своего бога1:7 Или: «своих богов».. 8Куруш, царь Персии, вверил их хранителю сокровищницы Митредату, который по счёту выдал их Шешбацару, вождю Иудеи.

9Вот их опись:

золотых блюд 30серебряных блюд 1 000ножей 2910золотых чаш 30одинаковых серебряных чаш 410других предметов 1 000

11Всего золотых и серебряных предметов было пять тысяч четыреста. Когда переселенцы отправлялись из Вавилона в Иерусалим, Шешбацар взял всё это с собой.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 1:1-11

Kirusi ran àwọn tí a kó nígbèkùn lọ́wọ́ láti padà

11.1-3: Es 5.13; 6.3; 2Ki 36.22,23.Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé,

2“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:

“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. 3Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. 4Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

5Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. 6Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.

7Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. 8Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.

9Èyí ni iye wọn.

Ọgbọ̀n àwo wúrà 30Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n 2910Ọgbọ̀n àdému wúrà 30Irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000

11Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé irinwó (5,400).

Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu.