Судьи 20 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Судьи 20:1-48

Исроильтяне поражают вениамитян

1Все исроильтяне от Дона на севере до Беэр-Шевы на юге и из земли Галаад, что на востоке от Иордана, вышли, как один, и собрались перед Вечным в Мицпе. 2Вожди всего народа, всех родов Исроила, заняли свои места в собрании народа Всевышнего – четыреста тысяч пеших воинов, вооружённых мечами. 3(А вениамитяне услышали о том, что исроильтяне пошли в Мицпу.) И тогда исроильтяне сказали:

– Расскажите нам, как случилось это страшное дело.

4Левит, муж убитой женщины, сказал:

– Я и моя наложница пришли в Гиву, что в земле Вениамина, чтобы заночевать там. 5Ночью жители Гивы пришли за мной и окружили дом, намереваясь меня убить. Они изнасиловали мою наложницу, и она умерла. 6Я взял её, разрезал на части и послал в каждую область наследия Исроила, потому что они сделали это постыдное и подлое дело в Исроиле. 7Итак, все вы, исроильтяне, выскажитесь и дайте свой совет.

8Весь народ поднялся, как один человек, говоря:

– Никто из нас не пойдёт домой. Нет, никто из нас не возвратится в свой дом. 9Но вот что мы сделаем с Гивой: мы бросим жребий и определим, кто должен пойти на неё. 10Мы возьмём по десять человек из каждой сотни всех родов Исроила, сотню из тысячи и тысячу из десяти тысяч, чтобы достать для войска съестных припасов. И когда войско придёт в Гиву, что в земле Вениамина, оно воздаст им по заслугам за эту подлость, совершённую ими в Исроиле.

11И все воины Исроила собрались вместе и объединились, как один человек, против этого города. 12Роды Исроила послали людей по всему роду Вениамина, говоря:

– Что за страшное дело вы совершили в Исроиле? 13Выдайте этих порочных людей из Гивы, чтобы мы могли предать их смерти и искоренить в Исроиле зло.

Но вениамитяне не хотели слушать своих соплеменников-исроильтян. 14Из своих городов они собрались в Гиве, чтобы воевать с исроильтянами. 15Вениамитяне тотчас же выставили двадцать шесть тысяч воинов, вооружённых мечами, от своих городов, не считая семисот отборных воинов из числа жителей Гивы. 16Среди этого войска было семьсот отборных воинов, которые были левшами, каждый из них мог метнуть из пращи камень в волос и не промахнуться.

17Исроил, не включая сюда Вениамина, выставил четыреста тысяч человек, вооружённых мечами, все они были воинами.

18Исроильтяне пришли в Вефиль20:18 Или: «в дом Всевышнего»; также в 21:2. и спросили Всевышнего. Они сказали:

– Кто из нас должен идти воевать с вениамитянами первым?

Вечный ответил:

– Первым пойдёт Иуда.

19На следующее утро исроильтяне встали и разбили стан неподалёку от Гивы. 20Исроильтяне вышли, чтобы сразиться с вениамитянами, и выстроились в боевой порядок напротив Гивы. 21Вениамитяне вышли из Гивы и сразили в тот день на поле боя двадцать две тысячи исроильтян. 22Но исроильтяне, ободряя друг друга, вновь выстроились в боевой порядок там же, где и в первый день.

23(Исроильтяне пошли, плакали перед Вечным до самого вечера и спрашивали Его:

– Идти ли нам опять сражаться с нашими братьями вениамитянами?

Вечный ответил:

– Идите против них.

24Тогда исроильтяне приблизились к Вениамину во второй день.)

25На этот раз вениамитяне, выйдя из Гивы им навстречу, сразили ещё восемнадцать тысяч исроильтян, вооружённых мечами.

26Исроильтяне, весь народ, пришли в Вефиль и плакали там, сидя перед Вечным. Они постились в тот день до вечера и принесли Вечному жертвы всесожжения и жертвы примирения. 27Затем они спросили Вечного. (В те дни сундук соглашения20:27 Сундук соглашения – см. пояснительный словарь, а также Исх. 25:10-22. со Всевышним был там, 28а Пинхас, сын Элеазара, внук Хоруна, служил перед ним.) Они спросили:

– Идти ли нам опять сражаться с нашими братьями вениамитянами или нет?

Вечный ответил:

– Идите. Завтра Я отдам их в ваши руки.

29Исроильтяне поставили вокруг Гивы засаду. 30Они пошли на вениамитян в третий день и встали в боевой порядок напротив Гивы, как и прежде. 31Вениамитяне вышли им навстречу, и их увели от города. Они начали, как и прежде, наносить исроильтянам потери, так что около тридцати человек пало убитыми в поле и на дорогах, одна из которых ведёт к Вефилю, а другая к Гиве.

32И пока вениамитяне говорили: «Мы бьём их, как и прежде», исроильтяне говорили: «Будем отступать и уведём их от города на дороги».

33Основные силы исроильтян переместились к Баал-Тамару, а те, кто был в засаде, ринулись со своего места к западу от20:33 Букв.: «на равнине». Гивы. 34На Гиву устремилось десять тысяч лучших исроильских воинов, и началась такая жестокая битва, что вениамитяне даже не понимали, как близка беда. 35Вечный разбил Вениамина перед Исроилом, и в тот день исроильтяне сразили двадцать пять тысяч сто вениамитян, вооружённых мечами. 36И вениамитяне увидели, что они разбиты.

Исроильтяне отступили перед вениамитянами, потому что надеялись на засаду, которую поставили неподалёку от Гивы. 37Воины, которые были в засаде, стремительно бросились на Гиву, вступили в город и предали его мечу. 38А исроильтяне договорились с воинами из засады об условном знаке: когда над городом начнёт подниматься дым, 39основные силы исроильтян должны будут перейти в наступление.

А вениамитяне уже начали наносить исроильтянам потери, убив около тридцати из них. Они думали: «Конечно, мы бьём их, как и в первой битве». 40Но когда из города начал подниматься столб дыма, вениамитяне повернулись и увидели, как от города к небу поднимается дым! 41Исроильтяне перешли в наступление, и вениамитяне испугались, потому что поняли, что пришла беда. 42И они побежали перед исроильтянами к пустыне, но битва настигла их, и те, кто уже выходили из города, разили их, зажав посередине. 43Окружив вениамитян, они преследовали и разили их от Нохи до восточной стороны Гивы. 44Из вениамитян пало восемнадцать тысяч человек, все они были храбрыми воинами. 45Когда они повернулись и побежали к пустыне, к скале Риммон, исроильтяне перебили пять тысяч человек на дорогах. Они гнались за ними до самого Гидома и сразили ещё две тысячи.

46В тот день пало двадцать пять тысяч вениамитян, носивших меч, все они были храбрыми воинами. 47Но шестьсот человек повернулись и бежали в пустыню к скале Риммон и там оставались четыре месяца. 48А исроильтяне вернулись к вениамитянам и предали их мечу – людей, животных и всё, что нашли. И все города на их пути они подожгли.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Onidajọ 20:1-48

Àwọn ọmọ Israẹli bá ará Benjamini jà

1Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti Dani dé Beerṣeba, àti láti ilẹ̀ Gileadi jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú Olúwa ni Mispa. 2Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. 3(Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.”

4Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. 5Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. 6Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli. 7Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”

8Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀. 9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí. Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa. 10A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.” 11Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

12Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín? 13Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.”

Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli. 14Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 15Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah. 16Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé).

17Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

18Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?”

Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.”

19Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah). 20Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah. 21Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà. 22Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. 23Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?”

Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

24Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì. 25Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

26Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa. 27Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀, 28Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?”

Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”

29Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sá pamọ́ yí Gibeah ká. 30Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí. 31Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah. 32Nígbà tí àwọn Benjamini ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”

33Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Baali-Tamari, àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí wọ́n sá pamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn Gibeah. 34Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Israẹli gbógun ti Gibeah láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Benjamini kò funra pé ìparun wà nítòsí. 35Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,100) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun. 36Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn.

Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah. 37Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà. 38Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà, 39nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun.

Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.” 40Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run. 41Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Benjamini nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu. 42Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ Israẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀. 43Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Benjamini ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn Gibeah. 44Ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun. 45Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin ṣubú.

46Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. 47Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin. 48Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.