Второзаконие 32 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Второзаконие 32:1-52

1«Внимайте, небеса, я буду говорить;

слушай, земля, слова моих уст.

2Пусть польётся моё учение, словно дождь,

пусть сойдут мои слова, как роса,

словно ливень на зелень,

как дождь на побеги.

3Имя Вечного провозглашу,

славьте величие нашего Бога!

4Он – скала, Его дела совершенны,

все Его пути праведны.

Верен Всевышний, не творящий неправды,

Он праведен и честен.

5Перед Ним они развратились,

и не дети они Ему,

но род упрямый и извращённый,

к своему стыду.

6Так ли воздаёте вы Вечному,

народ безрассудный и глупый?

Разве Он не Отец, не Творец твой,

Тот, Кто создал, основал тебя?

7Вспомни древние дни;

подумай об ушедших поколениях.

Спроси своего отца, и он скажет тебе,

своих старейшин, и они объяснят тебе:

8когда Высочайший давал народам их наследие,

когда Он разделил весь человеческий род,

Он поставил пределы народов

по числу сынов Исроила32:8 Или: «сынов Всевышнего»..

9Ведь доля Вечного – народ Исроила,

потомки Якуба – наследственный удел Его.

10В пустынной земле Он его нашёл,

в степи печальной и дикой.

Ограждал его, пёкся о нём;

хранил его, как зеницу Своего ока.

11Как орёл защищает своё гнездо32:11 Или: «учит своих птенцов летать».

и парит над своими птенцами,

простирает свои крылья, берёт птенцов

и несёт на своих перьях,

12так Вечный один его вёл;

чужого бога не было с Ним.

13Он вознёс его на высоты земли

и питал плодами полей.

Он кормил его мёдом из сот,

что в скалистых расщелинах,

и маслом из оливкового дерева,

что растёт на каменистой почве,

14творогом и молоком от стада и отары

и упитанными ягнятами и козлами,

лучшими баранами Бошона

и отборной пшеницей.

Ты пил вино, кровь винограда.

15Исроил32:15 Букв.: «Иешурун» – это слово переводится как «праведный» и является другим, поэтическим именем Исроила. То же в 33:5, 26. растолстел и стал упрям;

растолстел, обрюзг и разжирел.

Он оставил Всевышнего, Который создал его,

и отверг Скалу своего спасения.

16Они возбудили в Нём ревность чужими богами

и разгневали Его мерзкими идолами.

17Они приносили жертвы демонам, а не Всевышнему –

богам, которых не знали,

богам, появившимся недавно,

богам, которых ваши предки не боялись.

18Вы покинули Скалу, родившую вас;

вы забыли Всевышнего, создавшего вас.

19Вечный увидел это и отверг их,

так как разгневался на Своих сыновей и дочерей.

20„Я скрою от них Своё лицо, – сказал Он, –

и увижу, каков будет их конец;

потому что они – извращённый род,

неверные дети.

21Они пробудили во Мне ревность тем, что не Бог,

и разгневали Меня ничтожными идолами.

Я пробужу в них ревность теми, кто не Мой народ;

Я разгневаю их невежественными язычниками;

22потому что от Моего гнева запылал огонь,

что жжёт до дна мира мёртвых.

Он пожрёт землю и её урожаи

и подожжёт основания гор.

23Я соберу на них беды,

выпущу в них свои стрелы.

24Я пошлю на них опустошительный голод,

истребляющий мор и смертельную заразу;

Я пошлю на них хищных зверей,

ядовитых змей, что ползают в прахе.

25На улицах меч лишит их детей,

в их домах будет царить ужас.

Будут гибнуть юноши и девушки,

младенцы и седовласые старики.

26Я сказал бы: рассею их

и изглажу их память из человеческого рода,

27если бы не опасался насмешек врагов,

чтобы противники не возомнили

и не сказали: «Нашей руки торжество;

не Вечный совершил всё это»“.

28Это народ, потерявший рассудок,

нет у них разума.

29О, если бы они были мудры,

то понимали бы это

и уразумели, какой их ждёт конец!

30Как мог бы один человек преследовать тысячу

или двое обратить в бегство десять тысяч,

если бы их Скала не отступилась от них,

если бы Вечный их не выдал?

31Ведь скала врагов не такова, как наша Скала:

даже наши враги сами признают это.

32Их виноград с лозы Содома

и с полей Гоморры.

Их плоды полны яда,

а их гроздья – горечи.

33Их вино – яд змей,

смертельный яд кобр.

34„Я сокрыл злые дела их врагов, – говорит Вечный, –

и запечатал их в своих кладовых.

35Предоставьте месть Мне, Я воздам.

Придёт время, поскользнутся ноги врага;

день их бедствия близок,

и участь их поспешает“.

36Вечный будет судить Свой народ

и пожалеет Своих рабов,

когда увидит, что исчезла их сила

и не осталось никого: ни раба, ни свободного.

37И скажет Он: „Где же их боги,

та скала, за которой они укрывались?

38Боги, которые ели жир их жертв,

пили вино их жертвенных возлияний?

Пусть восстанут, чтобы помочь вам!

Пусть дадут вам покров!

39Смотрите же ныне, что только Я Бог32:39 Букв.: «Я, Я есть Он».,

и нет Бога, кроме Меня.

Я умерщвляю и оживляю,

Я ранил, и Я исцелю,

и никто не может избавить от Моей руки.

40Я поднимаю руку к небу и объявляю:

Верно, как и то, что Я живу вовеки, –

41когда отточу Свой сияющий меч

и рука Моя примет его для суда,

Я отомщу Моим противникам

и воздам тем, кто Меня ненавидит.

42Я напою Мои стрелы кровью,

а Мой меч будет пожирать плоть,

кровь павших и пленных,

головы вражеских вождей“.

43Радуйтесь, народы, вместе с Его народом32:43 Или: «Обрадуйте Его народ, о народы». В некоторых рукописях: «Радуйтесь, небеса, вместе с Ним; пусть все ангелы Всевышнего поклонятся Ему! Радуйтесь, народы, вместе с Его народом; пусть посланники Всевышнего возвещают о Его могуществе!»,

потому что Он отомстит за кровь Своих рабов;

отомстит Он Своим врагам,

очистит Свою землю и Свой народ».

44Мусо пришёл с Иешуа, сыном Нуна, и произнёс народу все слова этой песни. 45Сказав эти слова всему Исроилу, Мусо 46добавил:

– Примите к сердцу все слова, которые я торжественно возвестил вам сегодня, чтобы вы велели своим детям прилежно слушаться всех слов этого Закона. 47Для вас это не пустые слова, в них – ваша жизнь. Они дадут вам долго жить на земле, в которую вы переходите за Иордан, чтобы овладеть ею.

48В тот же день Вечный сказал Мусо:

49– Поднимись на горную цепь Аварим, на гору Нево в Моаве, напротив Иерихона, и осмотри Ханон, землю, которую Я отдаю во владение исроильтянам. 50На этой горе, на которую ты поднимешься, ты умрёшь и присоединишься к своему народу так же, как твой брат Хорун умер на горе Ор и присоединился к своему народу. 51Это случится из-за того, что вы оба изменили Мне у вод Меривы-Кадеша, в пустыне Цин, на глазах у исроильтян, и из-за того, что вы не отстаивали Мою святость среди них32:51 См. Чис. 20:1-13.. 52Поэтому ты увидишь землю, которую Я даю народу Исроила, только на расстоянии – ты не войдёшь в неё.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 32:1-52

1Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;

ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

2Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,

kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,

bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,

bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.

3Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa.

Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa!

4Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,

gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.

Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,

Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.

532.5: Fp 2.15.Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;

fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,

ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.

6Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,

ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?

Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,

tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?

7Rántí ìgbà láéláé;

wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.

Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,

àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.

8Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,

nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,

ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn

gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.

9Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,

Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.

10Ní aginjù ni ó ti rí i,

ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.

Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,

ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.

11Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń

rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,

tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì

gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.

12Olúwa ṣamọ̀nà;

kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.

13Ó mú gun ibi gíga ayé

ó sì fi èso oko bọ́ ọ.

Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,

àti òróró láti inú akọ òkúta wá.

14Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn

àti ti àgbò ẹran

àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,

pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani

tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.

15Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;

ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.

O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ

o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.

16Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,

ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.

17Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,

ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,

ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,

ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.

18Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;

o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

19Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,

nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.

20Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,

èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;

nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,

àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.

2132.21: Ro 10.19; 11.11; 1Kọ 10.22.Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,

wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.

Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;

èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.

22Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,

yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.

Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀

yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

23“Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí

èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

24Èmi yóò mú wọn gbẹ,

ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.

Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

25Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,

ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.

Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.

26Mo ní èmi yóò tú wọn ká

èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn,

27nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,

kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má

ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;

kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”

28Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.

29Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn

kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!

30Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000),

tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá,

bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,

bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

31Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,

àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.

32Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu

àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.

Èso àjàrà wọn kún fún oró,

ìdì wọn korò.

33Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,

àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.

34“Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́

èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?

35Ti èmi ni láti gbẹ̀san. Èmi yóò san án fún wọn

ní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;

ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etílé

ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”

36Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀

yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀

nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán

tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.

37Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,

àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,

38ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn

tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?

Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!

Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!

39“Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!

Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.

Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.

Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,

kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

40Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,

Èmi ti wà láààyè títí láé,

41nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi

àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,

Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi

Èmi ó sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.

42Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,

nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:

ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,

láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”

4332.43: Ro 15.10; Hb 1.6 (Septuagint); If 6.10; 19.2.Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀

nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;

yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀

yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.

44Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni. 45Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli. 46Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí. 47Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”

Ikú Mose lórí òkè Nebo

48Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Mose pé, 49“Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. 50Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. 51Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 52Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”