Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 18

Ẹni tí ó tóbi jù ní ìjọba Ọ̀run

1Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?”

Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.

“Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun. Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá! Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé. Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì.

Òwe àgùntàn tó sọnù

10 “Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèkéé wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 11 Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.

12 “Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí? 13 Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ? 14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.

Arákùnrin tí ó ṣẹ̀ sí ọ

15 “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò. 16 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà. 17 Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.

18 “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhun ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run.

19 “Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín. 20 Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrín wọn níbẹ̀.”

Òwe aláìláàánú ọmọ ọ̀dọ̀

21 Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”

22 Jesu dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í ṣe ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje.

23 “Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 24 Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. 25 Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.

26 “Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ 27 Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.

28 “Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’

29 “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’

30 “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. 31 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

32 “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. 33 Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ 34 Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́.

35 “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”

Korean Living Bible

마태복음 18

어린 아이같이 되라

1그때 제자들이 예수님께 와서 “하늘 나라에서는 누가 가장 위대합니 까?” 하고 물었다.

그래서 예수님은 한 어린 아이를 불러 그들 가운데 세우고

이렇게 말씀하셨다. “내가 분명히 말해 둔다. 너희가 변화되어 어린 아이와 같이 되지 않으면 결코 하늘 나라에 들어가지 못할 것이다.

그러므로 하늘 나라에서 가장 위대한 사람은 이 어린 아이처럼 자기를 낮추는 사람이다.

누구든지 내 이름으로 이런 어린 아이를 영접하면 곧 나를 영접하는 것이다.

그러나 누구든지 나를 믿는 이런 어린 아이 하나를 죄 짓게 하는 사람은 [a]차라리 목에 큰 맷돌짝을 달고 깊은 바다에 빠져 죽는 것이 더 낫다.

“죄 짓게 하는 일 때문에 이 세상에 불행이 닥칠 것이다. 세상에는 죄 짓게 하는 일이 항상 있기 마련이다. 그러나 죄 짓게 하는 그 사람에게는 불행이 닥칠 것이다.

네 손이나 발이 너를 죄 짓게 하면 잘라 버려라. 두 손이나 두 발을 가지고 [b]영원히 불타는 지옥에 들어가는 것보다는 절뚝발이나 불구자로 [c]영원한 생명을 누리는 하늘 나라에 들어가는 것이 더 낫다.

네 눈이 너를 죄 짓게 하면 빼어 버려라. 두 눈을 가지고 불타는 지옥에 들어가는 것보다는 외눈으로 [d]하나님 나라에 들어가는 것이 더 낫다.

10 “너희는 이런 어린 아이 하나라도 업신여기지 않도록 조심하라. 그들의 천사들이 하늘에 계신 내 아버지를 항상 뵙고 있다.

11 [e]([f]나는 잃어버린 사람을 구원하러 왔다.)

12 너희는 어떻게 생각하느냐? 어떤 사람에게 양 백 마리가 있는데 그 중에 한 마리가 길을 잃으면 아흔아홉 마리를 산에 두고 가서 길 잃은 양을 찾지 않겠느냐?

13 내가 너희에게 분명히 말하지만 그가 양을 찾으면 길을 잃지 않은 아흔아홉 마리 양보다 그 한 마리 양 때문에 더 기뻐할 것이다.

14 이와 같이 하늘에 계신 너희 아버지께서는 이런 어린 아이 하나라도 [g]잃는 것을 원치 않으신다.”

남을 용서하여라

15 “형제가 네게 죄를 짓거든 너는 그와 단둘이 만나 잘못을 타일러라. 그가 네 말을 들으면 너는 네 형제를 얻은 것이다.

16 그러나 듣지 않으면 너는 한두 사람을 더 데리고 가서 두세 증인의 입으로 모든 사실을 증명하라.

17 그래도 듣지 않으면 너는 교회에 말하고 교회의 말도 듣지 않으면 [h]믿지 않는 사람이나 죄인처럼 여겨라.

18 내가 너희에게 분명히 말하지만 너희가 땅에서 [i]처벌하면 하늘에서도 [j]처벌할 것이며 너희가 땅에서 [k]용서하면 하늘에서도 [l]용서할 것이다.

19 내가 다시 말한다. 너희 중에 두 사람이 땅에서 마음을 같이하여 무엇이든지 구하면 하늘에 계신 내 아버지께서 이루어 주실 것이다.

20 두세 사람이 내 이름으로 모이는 곳에는 나도 그들 가운데 있다.”

21 그때 베드로가 예수님께 와서 “주님, 형제가 내게 죄를 지었을 때 몇 번이나 용서해야 합니까? 일곱 번까지면 되겠습니까?” 하고 묻자

22 예수님은 이렇게 말씀하셨다. “일곱 번만 아니라 [m]일흔 번씩 일곱 번이라도 용서하여라.

23 그러므로 하늘 나라는 종들과 계산을 하려는 왕과 같다.

24 계산을 시작하자 [n]10,000달란트 빚진 한 종이 왕 앞에 끌려왔다.

25 그 종에게는 빚을 갚을 돈이 없었으므로 왕은 종에게 그와 아내와 자식들과 그가 가진 것 전부를 팔아서 빚을 갚으라고 명령하였다.

26 그러자 종은 왕에게 엎드려 ‘조금만 참아 주십시오. 그러면 다 갚아 드리겠습니다’ 하고 간청하였다.

27 그래서 왕은 그를 불쌍히 여겨 빚을 모두 면제해 주고 놓아 주었다.

28 “그러나 그 종은 나가 자기에게 [o]100데나리온 빚진 동료를 만나 멱살을 잡고 ‘당장 내 돈을 내놔!’ 하면서 재촉하였다.

29 그 동료는 엎드려 ‘조금만 참아 주게. 반드시 갚겠네’ 하고 간청하였다.

30 그러나 그 종은 그 사람의 간청을 들어주지 않고 빚을 다 갚을 때까지 그를 감옥에 가둬 버렸다.

31 다른 종들이 그가 하는 짓을 보고 몹시 마음이 아파 왕에게 가서 모두 일러바쳤다.

32 그래서 왕이 그 종을 불러 말하였다. ‘네 이놈, 네가 간청하기에 모든 빚을 면제해 주지 않았느냐?

33 그렇다면 내가 너를 불쌍히 여긴 것처럼 너도 네 동료를 불쌍히 여기는 것이 마땅하지 않으냐?’

34 그러고서 왕은 화를 내며 빚을 다 갚을 때까지 그 종을 가두어 두었다.

35 너희가 진심으로 형제를 용서하지 않으면 하늘에 계신 내 아버지께서도 너희에게 그와 같이 하실 것이다.”

Footnotes

 1. 18:6 원문에는 이 구절에 쓰인 동사가 수동태로 되어 있다.
 2. 18:8 원문에는 ‘영원한 불’
 3. 18:8 원문에는 ‘생명에’
 4. 18:9 또는 ‘영생에’
 5. 18:11 대부분의 사본에는 괄호 안의 구절이 없음.
 6. 18:11 원문에는 ‘인자’ (사람의 아들)
 7. 18:14 또는 ‘멸망하는 것을’
 8. 18:17 원문에는 ‘이방인과 세리’
 9. 18:18 원문에는 ‘매면’
 10. 18:18 원문에는 ‘매일 것이요’
 11. 18:18 원문에는 ‘풀면’
 12. 18:18 원문에는 ‘풀리리라’
 13. 18:22 또는 ‘일흔 일곱 번씩이라도’
 14. 18:24 1달란트는 6,000데나리온. 1데나리온은 하루 품삯. 하루 품삯을 10,000원으로 계산할 경우 10,000달란트는 6천억 원이 된다.
 15. 18:28 하루 품삯을 10,000원으로 계산할 경우 100데나리온은 백만 원, 곧 일만 달란트의 60만분의 1이 된다.