Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 26

1Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.”

Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé: “Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi, pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrín àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fi sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.

“Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?

“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. 10 Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. 11 Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.

12 “Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Damasku pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 13 Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò. 14 Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

15 “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’

“Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. 16 Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ: 17 Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí 18 láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

19 “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà. 20 Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà. 21 Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí. 22 Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ: 23 Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

24 Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”

25 Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde. 26 Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀. 27 Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

28 Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

29 Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

30 Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Bernike, àti àwọn tí o bá wọn jókòó; 31 Nígbà tí wọn wọ ìyẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.”

32 Agrippa sì wí fún Festu pé, “A bà dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ bí ó bá ṣe pe kò ì tí ì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Kesari.”

The Message

Acts 26

“I Couldn’t Just Walk Away”

11-3 Agrippa spoke directly to Paul: “Go ahead—tell us about yourself.”

Paul took the stand and told his story. “I can’t think of anyone, King Agrippa, before whom I’d rather be answering all these Jewish accusations than you, knowing how well you are acquainted with Jewish ways and all our family quarrels.

4-8 “From the time of my youth, my life has been lived among my own people in Jerusalem. Practically every Jew in town who watched me grow up—and if they were willing to stick their necks out they’d tell you in person—knows that I lived as a strict Pharisee, the most demanding branch of our religion. It’s because I believed it and took it seriously, committed myself heart and soul to what God promised my ancestors—the identical hope, mind you, that the twelve tribes have lived for night and day all these centuries—it’s because I have held on to this tested and tried hope that I’m being called on the carpet by the Jews. They should be the ones standing trial here, not me! For the life of me, I can’t see why it’s a criminal offense to believe that God raises the dead.

9-11 “I admit that I didn’t always hold to this position. For a time I thought it was my duty to oppose this Jesus of Nazareth with all my might. Backed with the full authority of the high priests, I threw these believers—I had no idea they were God’s people!—into the Jerusalem jail right and left, and whenever it came to a vote, I voted for their execution. I stormed through their meeting places, bullying them into cursing Jesus, a one-man terror obsessed with obliterating these people. And then I started on the towns outside Jerusalem.

12-14 “One day on my way to Damascus, armed as always with papers from the high priests authorizing my action, right in the middle of the day a blaze of light, light outshining the sun, poured out of the sky on me and my companions. Oh, King, it was so bright! We fell flat on our faces. Then I heard a voice in Hebrew: ‘Saul, Saul, why are you out to get me? Why do you insist on going against the grain?’

15-16 “I said, ‘Who are you, Master?’

“The voice answered, ‘I am Jesus, the One you’re hunting down like an animal. But now, up on your feet—I have a job for you. I’ve handpicked you to be a servant and witness to what’s happened today, and to what I am going to show you.

17-18 “‘I’m sending you off to open the eyes of the outsiders so they can see the difference between dark and light, and choose light, see the difference between Satan and God, and choose God. I’m sending you off to present my offer of sins forgiven, and a place in the family, inviting them into the company of those who begin real living by believing in me.’

19-20 “What could I do, King Agrippa? I couldn’t just walk away from a vision like that! I became an obedient believer on the spot. I started preaching this life-change—this radical turn to God and everything it meant in everyday life—right there in Damascus, went on to Jerusalem and the surrounding countryside, and from there to the whole world.

21-23 “It’s because of this ‘whole world’ dimension that the Jews grabbed me in the Temple that day and tried to kill me. They want to keep God for themselves. But God has stood by me, just as he promised, and I’m standing here saying what I’ve been saying to anyone, whether king or child, who will listen. And everything I’m saying is completely in line with what the prophets and Moses said would happen: One, the Messiah must die; two, raised from the dead, he would be the first rays of God’s daylight shining on people far and near, people both godless and God-fearing.”

24 That was too much for Festus. He interrupted with a shout: “Paul, you’re crazy! You’ve read too many books, spent too much time staring off into space! Get a grip on yourself, get back in the real world!”

25-27 But Paul stood his ground. “With all respect, Festus, Your Honor, I’m not crazy. I’m both accurate and sane in what I’m saying. The king knows what I’m talking about. I’m sure that nothing of what I’ve said sounds crazy to him. He’s known all about it for a long time. You must realize that this wasn’t done behind the scenes. You believe the prophets, don’t you, King Agrippa? Don’t answer that—I know you believe.”

28 But Agrippa did answer: “Keep this up much longer and you’ll make a Christian out of me!”

29 Paul, still in chains, said, “That’s what I’m praying for, whether now or later, and not only you but everyone listening today, to become like me—except, of course, for this prison jewelry!”

30-31 The king and the governor, along with Bernice and their advisors, got up and went into the next room to talk over what they had heard. They quickly agreed on Paul’s innocence, saying, “There’s nothing in this man deserving prison, let alone death.”

32 Agrippa told Festus, “He could be set free right now if he hadn’t requested the hearing before Caesar.”