Ezras Bog 8 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Ezras Bog 8:1-36

Familierne, der følger med Ezra til Jerusalem

1Her er listen over de familieoverhoveder, som sammen med deres familier fulgte med mig fra Babylonien på Artaxerxes’ tid:

2-14Fra Pinehas’ slægt: Gershom. Fra Itamars slægt: Daniel. Fra Davids slægt: Hattush, en efterkommer af Shekanja. Fra Parosh’ slægt: Zekarja samt 150 andre mænd. Fra Pahat-Moabs slægt: Eljoenaj, søn af Zerahja, samt 200 andre mænd. Fra Zattus slægt: Shekanja, søn af Jahaziel, samt 300 andre mænd. Fra Adins slægt: Ebed, søn af Jonatan, samt 50 andre mænd. Fra Elams slægt: Jeshaja, søn af Atalja, samt 70 andre mænd. Fra Shefatjas slægt: Zebadja, søn af Mikael, samt 80 andre mænd. Fra Joabs slægt: Obadja, søn af Jehiel, samt 218 andre mænd. Fra Banis slægt: Shelomit, søn af Josifja, samt 160 andre mænd. Fra Bebajs slægt: Zekarja, søn af Bebaj, samt 28 andre mænd. Fra Azgads slægt: Johanan, søn af Hakkatan, samt 110 andre mænd. Fra Adonikams slægt: Elifelet, Jeiel, Shemaja og 60 andre mænd, som kom senere. Fra Bigvajs slægt: Utaj og Zabud samt 70 andre mænd.

Forberedelserne til rejsen

15Før vi tog af sted, havde jeg samlet alle disse mennesker ved Ahavaflodens udløb. I tre dage lå vi i lejr, mens jeg gennemgik navnelisterne over de folk, som var ankommet. Jeg fandt adskillige præster imellem dem, men ikke en eneste levit. 16Derfor sammenkaldte jeg nogle af lederne, Eliezer, Ariel, Shemaja, Elnatan, Jarib, Elnatan, Natan, Zekarja og Meshullam, samt lærerne Jojarib og Elnatan. 17Jeg sendte dem til levitternes leder Iddo i byen Kasifja for at anmode ham og hans klansfæller om at sende os medarbejdere til Guds tempel i Jerusalem. 18Og Gud var med os, så levitterne sendte os en fremragende mand ved navn Sherebja og sammen med ham 18 af hans sønner og brødre. Han var efterkommer af Mahli, der var søn af Levi, som var søn af Jakob. 19Desuden sendte de Hashabja og Jeshaja af Meraris slægt sammen med 20 af deres sønner og brødre. 20Derudover kom der 220 tempeltjenere, som af kong David havde fået til opgave at hjælpe levitterne. Alle 220 mand blev opført på listen med navns nævnelse.

21Mens vi opholdt os ved Ahavafloden, udråbte jeg en faste, så vi på den måde kunne ydmyge os for Gud og bede om en vellykket rejse og om beskyttelse over os selv, vores børn og vores ejendele. 22Jeg brød mig nemlig ikke om at bede kongen om soldater og ryttere til at hjælpe os mod fjenderne undervejs. Vi havde jo netop sagt til kongen: „Vores Gud beskytter alle dem, som tilbeder ham. Men ulykke rammer dem, som vender sig fra ham.” 23Altså fastede vi og bønfaldt Gud om at være med os. Og det var han.

24Jeg indsatte derefter 12 af præsterne som ledere, og desuden indsatte jeg Sherebja, Hashabja og ti andre som ledere af levitterne. 25Dem overlod jeg så ansvaret for sølvet, guldet, fadene, skålene og de øvrige ting, som kongen og hans embedsmænd samt Israels folk havde skænket til Guds hus. 26Da jeg overdrog dem disse værdier, vejede jeg guldet og sølvet og fandt, at der var 22 tons sølv og 3,4 tons guld, samt sølvgenstande med en totalvægt på 3,4 tons, 2720 guldbægre til en værdi af 1000 guldmønter og to smukke bronzeskåle så fine og værdifulde, som var de af guld. 28De førnævnte mænd indviede jeg til Herren tillige med skattene, de havde ansvar for, pengene og alt tempeludstyret, der var blevet givet som frivillige ofre til Herren, vores fædres Gud.

29„Pas godt på alle disse ting,” sagde jeg til dem, „for I har ansvaret for dem, indtil de bliver vejet igen i Herrens hus i Jerusalem og kvitteret for af præsterne, levitterne og folkets ledere.” 30Præsterne og levitterne overtog så ansvaret for at bringe pengene og udstyret til Guds hus i Jerusalem.

31Den 12. dag i den første måned var vi klar til at bryde op fra vores lejr ved Ahava for at rejse til Jerusalem. Og Gud beskyttede os imod fjender og banditter undervejs. 32Da vi var ankommet til Jerusalem i god behold, hvilede vi ud de første tre dage. 33På fjerdedagen efter ankomsten blev guldet, sølvet og tempeludstyret vejet i templet og overdraget til Meremot, søn af præsten Urija. Han blev assisteret af Eleazar, søn af Pinehas, samt levitterne Jozabad, søn af Jeshua, og Noadja, søn af Binnuj. 34Alting blev optalt, vejet og checket af efter listen, og den samlede vægt blev udregnet og nedskrevet.

35Efter at det var gjort, ofrede alle de hjemvendte judæere brændofre til Israels Gud: 12 tyre for hele Israel, 96 væddere og 77 lam. Som et særligt syndoffer ofrede man 12 gedebukke. 36Den kongelige befaling blev overdraget til guvernørerne og de højtstående embedsmænd i området vest for Eufratfloden, og fra da af gav de deres støtte til folket og til Guds hus.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 8:1-36

Olórí àwọn ìdílé tí ó padà pẹ̀lú Esra

1Wọ̀nyí ni àwọn olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi láti Babeli ní àkókò ìjọba Artasasta ọba:

2nínú àwọn ọmọ Finehasi:

Gerṣomu;

nínú àwọn ọmọ Itamari:

Daniẹli;

nínú àwọn ọmọ Dafidi:

Hattusi, 3nínú àwọn ọmọ Ṣekaniah;

nínú àwọn ọmọ Paroṣi:

Sekariah, àti pé àádọ́jọ ọkùnrin fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;

4nínú àwọn ọmọ Pahati-Moabu:

Elihoenai ọmọ Serahiah àti àwọn igba ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

5nínú àwọn ọmọ Sattu:

Ṣekaniah ọmọ Jahasieli àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

6nínú àwọn ọmọ Adini:

Ebedi ọmọ Jonatani, àti àádọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

7nínú àwọn ọmọ Elamu:

Jeṣaiah ọmọ Ataliah àwọn àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

8nínú àwọn ọmọ Ṣefatia:

Sebadiah ọmọ Mikaeli, àti ọgọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

9nínú àwọn ọmọ Joabu:

Obadiah ọmọ Jehieli àti ogún ó lé nígba ó dín méjì (218) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

10nínú àwọn ọmọ Bani:

Ṣelomiti ọmọ Josafiah, àti ọgọ́jọ ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

11nínú àwọn ọmọ Bebai:

Sekariah ọmọ Bebai àti ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀;

12nínú àwọn ọmọ Asgadi:

Johanani ọmọ Hakatani, àti àádọ́fà ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

13nínú àwọn ọmọ Adonikami:

àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orúkọ wọn ń jẹ́ Elifaleti, Jeieli àti Ṣemaiah, àti ọgọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú wọn;

14nínú àwọn ọmọ Bigfai:

Uttai àti Sakkuri, àti àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú wọn.

Ìpadà sí Jerusalẹmu

15Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀. 16Nígbà náà ni mo pe Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, Elnatani, Jaribi, Elnatani, Natani, Sekariah, àti Meṣullamu, tí wọ́n jẹ́ olórí, àti Joiaribu àti Elnatani tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀, 17mo sì rán wọn tí àwọn ti àṣẹ sí ọ̀dọ̀ Iddo, tí ó jẹ́ olórí ní ibi ti a ń pè ni Kasifia, mo sì sọ fún wọn ohun tí wọn yóò wí fun Iddo àti àwọn Lefi arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹmpili ní Kasifia pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ wa fún ilé Ọlọ́run wa. 18Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún. 19Àti Haṣabiah, pẹ̀lú Jeṣaiah láti ìran Merari, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún ọkùnrin. 20Wọ́n sì tún mú ogún lé nígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili wá—àwọn ènìyàn tí Dafidi àti àwọn ìjòyè rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

21Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Ahafa, mo kéde àwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa. 22Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹṣin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbínú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” 23Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.

24Nígbà náà ni mo ya àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣerebiah, Haṣabiah àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn, 25mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa. 26Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta (650) tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, 27ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà.

28Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Fàdákà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín. 29Ẹ máa tọ́jú wọn dáradára títí ẹ̀yin yóò fi fi òsùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jerusalẹmu ní iwájú àwọn aṣáájú, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Israẹli.” 30Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ tí a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerusalẹmu.

31Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Ahafa láti lọ sí Jerusalẹmu. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa. 32Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jerusalẹmu, níbi tí a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta.

33Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Meremoti ọmọ Uriah lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Eleasari ọmọ Finehasi wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi; Josabadi ọmọ Jeṣua àti Noadiah ọmọ Binnui wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 34Gbogbo nǹkan ni a kà, tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ní ìgbà náà.

35Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí ó ti padà láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ sísun sí Ọlọ́run Israẹli: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Israẹli, àgbò mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún, ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, àti òbúkọ méjìlá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa. 36Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run.