1. Krønikebog 29 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

1. Krønikebog 29:1-30

David og forsamlingen bringer gaver til Herren

1Henvendt til hele forsamlingen sagde David: „Min søn Salomon, som Gud har udvalgt til at efterfølge mig på Israels trone, er endnu ung og uerfaren. Den opgave, der er ham betroet, er stor, for det er ikke et palads til et menneske, han skal bygge, men Herrens eget hus! 2Jeg har derfor gjort, hvad der stod i min magt for at forberede arbejdet. Jeg har samlet alt det guld, sølv, bronze, jern og træ, der skal bruges, foruden alle slags farvede smykkesten og mængder af marmor. 3For at bevise mit stærke ønske om at se Herrens hus blive bygget giver jeg derudover, hvad jeg personligt ejer af guld og sølv: 4-5100 tons rent guld og 240 tons rent sølv til at overtrække bygningens vægge med og til anden udsmykning i templet. Hvem iblandt jer vil følge mit eksempel og bringe gaver til Herren?”

6-7Straks kom stamme- og slægtsoverhovederne, officererne og de ledende embedsmænd frivilligt og gav følgende til opførelsen af Herrens hus: 170 tons guld og 10.000 guldmønter, 340 tons sølv, 610 tons bronze og 3400 tons jern. 8De, som ejede smykkesten, gav dem til Herrens hus, og de blev opbevaret i templets skatkammer under Jehiels varetægt. 9Alle glædede sig over at få lov at give, for de gav af hele deres hjerte til Herren, og David var rørt af glæde.

Davids takkesang til Herren

10David brød ud i lovsang til Herren i hele folkets påhør:

„Priset være du, Israels Gud,

vores fædres Gud fra evighed til evighed.

11Storhed og magt, ære og herlighed tilhører dig, Herre,

for alt i himlen og på jorden er dit.

Du er den almægtige hersker,

højt ophøjet over alt og alle.

12Rigdom og ære kommer fra dig,

du regerer over alle mennesker.

Du giver storhed og styrke til hvem, du vil.

13Du er vores Gud, og vi priser dig.

Vi lovsynger dit herlige navn.”

14David fortsatte: „I virkeligheden kan hverken jeg eller mit folk give dig noget som helst, for alt, hvad vi ejer, har vi fået af dig, så vi giver dig kun, hvad der allerede er dit. 15Vi er kun gæster på besøg i denne verden, ligesom vores forfædre var det. Vores liv på jorden er som en skygge, der passerer forbi. 16Al den rigdom, som vi nu har skaffet til veje for at bygge dit hus, kom fra dig. Det hele tilhører dig. 17Min Gud, jeg ved, at du kender menneskers motiver og glæder dig over et oprigtigt hjerte. Jeg gav med glæde og uden bagtanke, og nu har jeg set, at hele dit folk har givet frivilligt og med glæde.

18Herre, Abrahams, Isaks og Jakobs Gud, jeg beder om, at dit folk altid må bevare den samme indstilling, og at du vil drage deres hjerter til dig. 19Giv også min søn Salomon et helhjertet ønske om at adlyde alle dine befalinger, love og forordninger, så han kan bygge det tempel, som jeg har gjort forberedelser til.”

20Derefter sagde David til hele forsamlingen: „Lovsyng Herren, jeres Gud!” Alle lovpriste nu deres fædres Gud og bøjede sig til jorden for Gud og for kongen.

Salomon anerkendes som konge

21Dagen efter bragte forsamlingen 1000 unge tyre, 1000 væddere og 1000 lam som slagtofre og brændofre til Herren. Der var også drikofre og takofre i massevis, så der var nok at spise til hele forsamlingen. 22Hele dagen spiste og drak de med stor glæde for Herrens ansigt. Derpå indsatte de endnu en gang kong Davids søn Salomon til konge. Ind for Herrens ansigt salvede de ham som regent, og de salvede samtidig Zadok som ypperstepræst. 23Efter sin fars død overtog Salomon tronen. Han fik stor fremgang, og hele Israels folk adlød ham. 24Alle landets ledere, hærens officerer og kong Davids andre sønner aflagde troskabsløfte over for ham. 25Herren gjorde ham til en populær konge i Israel, som fik større ære og fremgang end nogen anden konge i Israel før ham.

Davids død

26-27David var konge over Israel i 40 år. I syv år regerede han fra Hebron og i 33 år fra Jerusalem. 28Han døde i en høj alder som en velhavende og respekteret mand, og hans søn Salomon blev konge i hans sted. 29Beskrivelser af kong Davids liv og bedrifter findes i profeterne Samuel, Natan og Gads bøger. 30De fortæller i detaljer om hans regeringstid, og hvad der ellers skete med ham og Israels folk og nabolandene.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 29:1-30

Ẹ̀bùn fún kíkọ́ ilé Olúwa

1Nígbà náà, ọba Dafidi sọ fún gbogbo àpéjọ pé, “Ọmọ mi Solomoni, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, sì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa Ọlọ́run. 2Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀. 3Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí, 4ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ǹtì wúrà, ti wúrà Ofiri àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà. 5Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún oríṣìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Nísinsin yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?”

6Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i. 7Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (10,000) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin (100,000) tálẹ́ǹtì irin. 8Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Olúwa ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. 9Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.

Àdúrà Dafidi

10Dafidi yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé,

“Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa,

Ọlọ́run baba a wa Israẹli,

láé àti láéláé.

11Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn

àti ọláńlá àti dídán,

nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.

Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;

a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.

12Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;

ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.

Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti

láti fi agbára fún ohun gbogbo.

13Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ,

a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.

14“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. 15Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí. 16Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. 17Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsin yìí èmi ti rí i pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́. 18Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Abrahamu, Isaaki àti Israẹli pa ìfẹ́ yìí mọ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtítọ́ sí ọ. 19Àti fún ọmọ mi Solomoni ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

20Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, “Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín.” Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.

A yan Solomoni gẹ́gẹ́ bí ọba

21Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún (1,000) kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin (1,000) kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli. 22Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà.

Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà. 2329.23: 1Ọb 2.12.Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba a rẹ̀ Dafidi. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Israẹli sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 24Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dafidi tẹrí ara wọn ba fún ọba Solomoni.

25Olúwa gbé Solomoni ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Israẹli, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọláńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú rẹ̀ tí ó jẹ lórí Israẹli.

Ikú Dafidi

26Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. 27Ó jẹ ọba lórí Israẹli fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jẹ ọba ní Hebroni, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. 28Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

29Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dafidi, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Samuẹli aríran, ìwé ìrántí ti Natani wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gadi aríran, 30lápapọ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti agbára rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbà tí ó kọjá lórí rẹ̀, àti lórí Israẹli, àti lórí gbogbo àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ náà.