Esaïe 59 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

Esaïe 59:1-21

De l’injustice à la justice

Ce qui sépare de Dieu

1Mais non : la main de l’Eternel ╵n’est pas trop courte pour sauver,

et son oreille n’est pas sourde ╵au point de ne plus vous entendre !

2Ce sont vos fautes ╵qui vous séparent

de votre Dieu.

C’est à cause de vos péchés ╵qu’il s’est détourné loin de vous

pour ne plus vous entendre.

3Car vos mains sont souillées de sang

et vos doigts de péchés,

vos lèvres disent des mensonges,

votre langue susurre ╵des paroles perfides.

4Personne n’invoque le droit,

et nul ne plaide ╵selon la vérité.

On s’appuie sur de vains raisonnements

et l’on allègue des mensonges.

Ils conçoivent le mal

et enfantent l’iniquité.

5Ils couvent des œufs de vipère,

tissent des toiles d’araignée.

Qui mange de ces œufs mourra ;

de chaque œuf couvé qui éclôt

sortira un serpent.

6Leurs toiles d’araignée ╵ne servent pas de vêtement,

et l’on ne peut pas se couvrir ╵de ce qu’ils ont confectionné.

Les œuvres qu’ils produisent ╵sont des œuvres mauvaises ;

de leurs mains, ils commettent ╵des actes de violence.

7Leurs pieds courent au mal,

et ils ont hâte ╵de verser le sang innocent.

Leurs pensées sont sans cesse ╵orientées vers le mal,

dévastation et destruction ╵jalonnent leur parcours59.7 Pour les v. 7-8, voir Rm 3.15-17..

8Ils ne connaissent pas ╵le chemin de la paix,

et le droit est absent ╵des routes qu’ils empruntent.

Les sentiers qu’ils se tracent ╵sont des voies tortueuses :

quiconque s’y engage ╵ne connaît pas la paix.

Les péchés du peuple

9Voilà pourquoi le droit ╵demeure loin de nous,

et l’on ne nous rend pas justice.

Nous espérions de la lumière,

et c’est l’obscurité.

Oui, nous espérions la clarté

et nous marchons dans les ténèbres.

10Nous allons à tâtons ╵comme des aveugles ╵le long d’un mur ;

comme ceux qui n’ont plus leurs yeux,

nous allons à tâtons,

nous trébuchons en plein midi ╵comme à la nuit tombante ;

tout en étant pleins de vigueur,

nous sommes comme morts.

11Nous grondons tous comme des ours

et nous ne cessons de gémir ╵tout comme des colombes.

Nous espérons le droit, ╵mais il n’y en a pas ;

et le salut, ╵mais il est loin de nous !

12Car nos révoltes ╵contre toi sont nombreuses

nos transgressions ╵témoignent contre nous.

Nos péchés restent attachés à nous,

et nos fautes, nous les connaissons bien.

13Nous sommes des rebelles

et nous avons trompé ╵l’Eternel, notre Dieu, ╵en lui tournant le dos.

Nous ne parlons que d’oppression ╵et de révolte,

et nous avons conçu, ╵nous avons projeté ╵des propos mensongers ╵dans notre cœur.

14Aussi, le droit recule

et la justice est loin de nous.

La vérité trébuche ╵sur la place publique,

et la droiture ╵ne peut y accéder.

15La vérité a disparu

et celui qui se détourne du mal ╵se fait piller.

Dieu intervient

Mais l’Eternel a vu ╵avec indignation

qu’il n’y a plus de droit.

16Il n’a trouvé personne ╵qui intercède,

il s’en est étonné.

Alors son propre bras ╵lui est venu en aide,

et sa justice ╵a été son soutien59.16 Voir 63.5..

17Il se revêt de la justice ╵comme d’une cuirasse,

il s’est mis sur la tête ╵le casque du salut.

En guise de tunique, ╵il s’est drapé ╵de la rétribution,

il s’est enveloppé ╵comme dans un manteau59.17 Allusion en Ep 6.14-17 ; 1 Th 5.8. ╵d’une ardeur passionnée ╵pour la relation exclusive ╵qui le lie à son peuple.

18Il rendra à chacun ╵ce que lui vaut ses actes :

la fureur à ses adversaires,

et leur dû à ses ennemis ;

il paiera leur salaire ╵aux habitants des îles, ╵et des régions côtières.

19Ainsi, l’on craindra l’Eternel ╵et l’on révérera sa gloire

de l’occident jusqu’au levant.

Car il viendra ╵comme un fleuve en furie

agité par un vent ╵venu de l’Eternel59.19 Verset difficile, interprété de diverses manières..

20Car le libérateur ╵va venir pour Sion,

pour ceux qui, en Jacob, ╵renonceront à leurs révoltes.

L’Eternel le déclare.

21Quant à moi, déclare l’Eternel, voici quelle est l’alliance que je fais avec eux59.21 Les v. 20-21 sont cités en Rm 11.26. : Mon Esprit qui repose sur toi et mes paroles que je mets dans ta bouche59.21 Voir 51.16., ne s’écarteront ni de ta bouche, ni de la bouche de tes enfants, ni de la bouche de leurs enfants. Voilà ce que dit l’Eternel, dès maintenant et pour l’éternité.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 59:1-21

Ẹ̀ṣẹ̀, ìjẹ́wọ́ àti ìràpadà

1Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,

tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.

2Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;

ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín

tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

3Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,

àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi.

Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀,

ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

4Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo;

kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́;

wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà.

5Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀

wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,

àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.

6Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;

wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.

Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.

759.7-8: Ro 3.15-17.Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;

wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;

ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.

8Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;

kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn

wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ,

kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.

9Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,

àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.

A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn;

ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.

10Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri

tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.

Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;

láàrín alágbára àwa dàbí òkú.

11Gbogbo wa là ń ké bí i beari;

àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà.

A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀,

ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.

12Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,

àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.

Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,

àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,

13ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,

kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,

dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,

pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.

14Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,

àti ti òdodo dúró lókèèrè;

òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,

òdodo kò sì le è wọlé.

15A kò rí òtítọ́ mọ́,

àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.

Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́

pé kò sí ìdájọ́ òdodo.

16Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,

àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;

nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,

àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.

1759.17: Ef 6.14,17; 1Tẹ 5.8.Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,

àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;

ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀

ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.

18Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,

bẹ́ẹ̀ ni yóò san án

ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀

àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;

òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.

1959.19: Mt 8.11; Lk 13.29.Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,

àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.

Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi

èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.

2059.20-21: Ro 11.26-27.“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,

sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó

ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

21“Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé,” ni Olúwa wí.