1 Chroniques 9 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

1 Chroniques 9:1-44

Les habitants de Jérusalem après le retour de l’exil

1Tout Israël a été recensé et inscrit dans les Annales des rois d’Israël9.1 Recueil des décrets royaux contenant également les résultats des divers recensements (2 S 24.2-9). Ce chapitre donne un tableau des habitants de Jérusalem, des lévites et de leurs fonctions après le retour de l’exil (voir Né 11.3-19).. La population de Juda fut déportée à Babylone, à cause de ses infidélités. 2Les premiers à s’établir de nouveau dans leurs propriétés et dans leurs villes respectives, furent des Israélites, des prêtres, des lévites, et desservants9.2 Voir Esd 2.43, 70 ; Né 7.72. du Temple.

3De plus, des gens des tribus de Juda, de Benjamin, d’Ephraïm et de Manassé s’établirent à Jérusalem : 4Outaï, fils d’Ammihoud, ayant pour ascendants Omri, Imri, Bani, du lignage de Pérets, fils de Juda. 5Parmi les Shilonites, il y avait Asaya, le premier-né et ses fils. 6Des descendants de Zérah, il y avait Yeouel. Les membres de la tribu de Juda installés à Jérusalem étaient au nombre de 690. 7De la tribu de Benjamin, il y avait Sallou, fils de Meshoullam, qui avait pour ascendants : Hodavia et Hassenoua ; 8Yibneya, fils de Yeroham ; Ela, fils d’Ouzzi, et petit-fils de Mikri ; Meshoullam, fils de Shephatia et petit-fils de Reouel, le fils de Yibniya.

9Les membres de la tribu de Benjamin installés à Jérusalem étaient au nombre de 956 et tous ces hommes étaient des chefs de groupe familial dans leur groupe familial.

10Parmi les prêtres, il y avait : Yedaeya, Yehoyarib, Yakîn, 11Azaria, fils de Hilqiya, qui avait pour ascendants : Meshoullam, Tsadoq, Merayoth, Ahitoub, responsable en chef du temple de Dieu ; 12il y avait aussi Adaya, fils de Yeroham, qui avait pour ascendants Pashhour et Malkiya ; il y avait Maesaï, fils d’Adiel, dont les ascendants étaient Yahzéra, Meshoullam, Meshillémith et Immer. 13Avec les autres prêtres, chefs de leur groupe familial, ils étaient au nombre de 1 760 hommes forts et valeureux affectés au service du temple de Dieu.

14Parmi les lévites : Shemaya, fils de Hashoub, descendant d’Azriqam, Hashabia du lignage de Merari ; 15il y avait aussi Baqbaqar, Héresh, Galal, Mattania, fils de Michée, petit-fils de Zikri, et descendant d’Asaph. 16Il y avait Abdias, fils de Shemaya, descendant de Galal et Yedoutoun ; il y avait Bérékia, fils d’Asa et petit-fils d’Elqana, qui habitait dans les villages des Netophatites9.16 Voir 2.54 ; Né 12.28-29. Netopha: ville située près de Bethléhem.. 17Il y avait encore des portiers : Shalloum, Aqqoub, Talmôn, Ahimân et leurs frères. Shalloum en était le chef. 18Et, jusqu’à présent, ses descendants surveillent l’entrée orientale du Temple appelée la porte du Roi. Ce sont là les portiers du camp des lévites. 19Shalloum, fils de Qoré, descendant d’Ebyasaph, et de Qoré, ainsi que les autres membres du groupe familial des Qoréites, remplissaient les fonctions de gardiens de l’entrée de la tente de la Rencontre, comme leurs ancêtres avaient gardé l’entrée du camp de l’Eternel. 20Phinéas, fils d’Eléazar, avait été autrefois leur chef car l’Eternel était avec lui.

21Zacharie, fils de Meshélémia, était aussi portier à l’entrée de la tente de la Rencontre. 22Ils étaient en tout 212 qui avaient été choisis comme portiers des entrées et ils avaient été recensés d’après leurs villages d’origine. David et Samuel le prophète les avaient établis dans leur fonction de façon permanente. 23Eux et leurs descendants ont donc pour fonction de surveiller les portes du sanctuaire de l’Eternel, c’est-à-dire du sanctuaire de la tente. 24Il y avait des portiers des quatre côtés : à l’est, à l’ouest, au nord et au sud. 25D’autres portiers, qui demeuraient dans leurs villages respectifs, devaient de temps à autre venir auprès d’eux pendant sept jours. 26Cependant, ces quatre portiers principaux étaient en fonction de façon permanente ; c’étaient des lévites et ils avaient la responsabilité des salles et des trésors du sanctuaire de Dieu. 27Ils passaient la nuit dans les environs du sanctuaire de Dieu, puisqu’ils en avaient la garde et qu’ils devaient en ouvrir les portes chaque matin9.27 Le temple était fermé la nuit. La clé était gardée par les portiers qui veillaient autour du sanctuaire..

28Certains lévites avaient la responsabilité des ustensiles du service : ils les comptaient lorsqu’on les emportait et lorsqu’on les rapportait. 29D’autres étaient désignés pour veiller sur les ustensiles, y compris les ustensiles du sanctuaire, et sur la fleur de farine, le vin, l’huile, l’encens et les aromates. 30Mais c’étaient des membres des familles sacerdotales qui composaient les parfums aromatiques. 31Mattitia, l’un des lévites, fils aîné de Shalloum le Qoréite, était responsable de la fabrication des gâteaux cuits à la poêle. 32D’autres lévites, faisant partie des Qehatites, avaient la responsabilité de préparer chaque jour de repos les pains devant être exposés devant l’Eternel.

33Les chefs de groupe familial des lévites affectés au chant avaient leurs chambres ; ils étaient dispensés de toute autre tâche, parce qu’ils étaient de service jour et nuit. 34Ce sont là des chefs de groupe familial des lévites chacun dans sa génération. Ils habitaient à Jérusalem.

La famille de Saül

(1 Ch 8.28-38)

35Le père de Gabaon9.35 Voir 8.29 et note., Yeïel, habitait à Gabaon. Sa femme s’appelait Maaka. 36Abdôn fut son fils premier-né, puis vinrent Tsour, Qish, Baal, Ner, Nadab, 37Guedor, Ahyo, Zacharie et Miqloth.

38Miqloth eut pour fils Shimeam. Ces derniers habitaient eux aussi à Jérusalem avec ceux qui leur étaient apparentés. 39Ner eut pour fils Qish, qui eut pour fils Saül ; les fils de Saül furent Jonathan, Malkishoua, Abinadab et Eshbaal. 40Jonathan eut pour fils Merib-Baal, qui eut pour fils Michée. 41Fils de Michée : Pitôn, Mélek et Tahréa9.41 Certains manuscrits de l’ancienne version grecque, la version syriaque, la Vulgate (voir 1 Ch 8.36) ont : Tahréa et Achaz.. 42Ahaz eut pour fils Yaera9.42 Certains manuscrits hébreux et l’ancienne version grecque ont : Yaeda (voir 1 Ch 8.36). qui eut pour fils : Alémeth, Azmaveth et Zimri. Voici les descendants de Zimri en ligne directe : Motsa, 43Binea, Rephaya, Eleasa, Atsel. 44Atsel eut six fils, dont voici les noms : Azriqam, Bokrou, Ismaël, Shearia, Abdias et Hanân. Tels étaient les fils d’Atsel.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 9:1-44

19.1,2: Es 2.70; Ne 7.73; 11.3.Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn.

Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jerusalẹmu

2Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa.

39.3-17: Ne 11.4-19.Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:

4Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda.

5Àti nínú ará Ṣilo:

Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.

6Ní ti ará Sera:

Jeueli.

Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).

7Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni:

Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah;

8Ibinaiah ọmọ Jerohamu;

Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri;

àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah.

9Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.

10Ní ti àwọn àlùfáà:

Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini;

11Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

12Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah;

àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri.

13Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14Ní ti àwọn ará Lefi:

Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari;

15Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;

16Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni;

àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa.

17Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà:

Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn, 18ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.

19Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé Olúwa.

20Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

21Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.

22Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn.

Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. 23Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́. 24Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. 25Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. 26Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. 27Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ, wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

28Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. 29Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. 30Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. 31Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín. 32Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Lefi dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì ṣe lára iṣẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́sàn, lóru.

34Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

Ìdílé àti Ìrandíran Saulu

35Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.

Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka, 36pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu. 37Gedori, Ahio, Sekariah àti Mikiloti. 38Mikiloti jẹ́ baba Ṣimeamu, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

39Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba a Saulu, àti Saulu baba a Jonatani, àti Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

40Ọmọ Jonatani:

Meribu-Baali, tí ó jẹ́ baba Mika.

41Àwọn ọmọ Mika:

Pitoni. Meleki, Tarea àti Ahasi.

42Ahasi jẹ́ baba Jada, Jada jẹ́ baba Alemeti, Asmafeti, Simri, sì Simri jẹ́ baba Mosa. 43Mosa jẹ́ baba Binea; Refaiah jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.

44Aseli ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:

Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli Ṣeariah, Obadiah àti Hanani, gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.