Exodus 14 – APSD-CEB & YCB

Ang Pulong Sa Dios

Exodus 14:1-31

1Unya miingon ang Ginoo kang Moises, 2“Ingna ang mga Israelinhon nga mobalik sila ug magkampo duol sa Pi-Hahirot, sa tunga-tunga sa Migdol ug sa Pulang Dagat, ug magkampo sila sa daplin sa dagat, atbang sa Baal Zefon. 3Maghunahuna ang hari nga nahisalaag kamo ug dili na makagawas sa kamingawan. 4Ug pagahion ko ang iyang kasingkasing ug gukdon niya kamo. Apan laglagon ko siya ug ang iyang mga sundalo. Niining paagiha mapasidunggan ako, ug mahibaloan sa mga Ehiptohanon nga ako mao ang Ginoo.” Busa gihimo kini sa mga Israelinhon.

5Sa dihang nabalitaan sa hari sa Ehipto nga miikyas ang mga Israelinhon, nausab ang iyang hunahuna ug sa iyang mga opisyal bahin sa mga Israelinhon. Miingon sila, “Unsa kining atong gibuhat? Nganong gipalakaw man nato ang mga Israelinhon? Karon wala na kitay mga ulipon!” 6Busa gipaandam sa hari ang iyang karwahe ug ang iyang mga sundalo. 7Gidala niya ang 600 sa pinakamaayong karwahe sa Ehipto ug ang uban pang karwahe. Gidumalahan kining tanan sa iyang mga opisyal. 8Gipagahi sa Ginoo ang kasingkasing sa Faraon nga hari sa Ehipto, busa gigukod niya ang mga Israelinhon nga maisogong mibiya. 9Ang mga Ehiptohanon nga miuban sa paggukod mao ang mga sundalo sa hari uban sa iyang mga tigkabayo nga nagasakay sa mga kabayo ug mga karwahe. Naapsan nila ang mga Israelinhon sa ilang ginakampohan daplin sa Pulang Dagat duol sa Pi-Hahirot, atbang sa Baal Zefon.

10Sa nagapadulong ang hari ug ang iyang mga sundalo, nakita sila sa mga Israelinhon. Busa nangahadlok sila pag-ayo ug nagpakitabang sila sa Ginoo. 11Miingon sila kang Moises, “Nganong gidala mo pa kami dinhi sa kamingawan aron mamatay? Wala bay lubnganan didto sa Ehipto? Nganong gipagawas mo pa man kami gikan sa Ehipto? 12Di ba nagaingon man kami kanimo didto sa Ehipto nga pasagdan mo na lang kami nga magpaulipon sa mga Ehiptohanon? Mas maayo pa nga nagpaulipon na lang kami sa mga Ehiptohanon kaysa mamatay kami dinhi sa kamingawan!”

13Mitubag si Moises sa mga tawo, “Ayaw kamo kahadlok. Pagmalig-on kamo ug tan-awa ninyo ang pagluwas kaninyo sa Ginoo karong adlawa. Kanang mga Ehiptohanon nga nakita ninyo karon dili na gayod ninyo makita pag-usab. 14Pagmalinawon lang kamo. Ang Ginoo ang makiggira alang kaninyo.” 15Unya miingon ang Ginoo kang Moises, “Nganong nagpakitabang ka man kanako? Ingna ang mga Israelinhon nga magpadayon sila sa paglakaw. 16Unya ipunting ang imong baston sa dagat aron matunga ang tubig ug makatabok ang mga Israelinhon sa malang yuta taliwala sa dagat. 17Pagahion ko ang kasingkasing sa mga Ehiptohanon aron gukdon nila kamo. Apan laglagon ko ang hari ug ang tanan niyang mga sundalo, mga tigkabayo, ug mga karwahe. Niining paagiha mapasidunggan ako. 18Ug kon malaglag ko na sila, mahibaloan sa mga Ehiptohanon nga ako mao ang Ginoo.”

19Unya ang anghel sa Dios nga nagauna sa katawhan sa Israel mibalhin sa luyo, ug ang panganod nga daw haligi mibalhin usab sa luyo. 20Mipundo ang panganod sa tunga-tunga sa mga Israelinhon ug sa mga Ehiptohanon. Tibuok gabii naghatag ang panganod ug kahayag sa mga Israelinhon ug naghatag ug kangitngit sa mga Ehiptohanon. Busa milabay ang gabii nga wala makaduol ang mga Ehiptohanon sa mga Israelinhon.

21Unya gipunting ni Moises ang iyang kamot ibabaw sa dagat, ug natunga ang dagat pinaagi sa makusog nga hangin nga gipadala sa Ginoo gikan sa sidlakan. Tibuok gabii nga kusog ang hangin hangtod nga mimala ang yuta taliwala sa dagat. 22Unya nangagi niining malang yuta ang mga Israelinhon, ug ang tubig nahimong morag paril sa ilang isigka-kilid. 23Gigukod sila sa mga Ehiptohanon. Ang tanang mga kabayo sa hari, mga karwahe ug ang tanang tigkabayo misunod kanila sa taliwala sa dagat. 24Apan nianang pagkakaadlawon, mitan-aw ang Ginoo gikan sa panganod nga daw kalayo ug daw haligi ngadto sa mga sundalo sa Ehipto, ug gipataranta niya sila. 25Gipaungot niya ang mga ligid14:25 Gipaungot… ligid: Sa uban nga daang mga teksto, Gipangkuha niya ang mga ligid. sa ilang mga karwahe aron maglisod sila sa pagpadagan niini. Miingon ang mga Ehiptohanon, “Moatras na lang kita gikan sa mga Israelinhon, kay ang Ginoo mao ang nakiggira kanato alang kanila.”

26Sa dihang nakatabok na ang mga Israelinhon, miingon ang Ginoo kang Moises, “Ipunting pag-usab ang imong kamot sa dagat aron mobalik ang tubig ug matabonan ang mga Ehiptohanon ug ang ilang mga karwahe ug mga tigkabayo.” 27Busa gipunting ni Moises ang iyang kamot sa dagat, ug sa pagsubang sa adlaw, mibalik ang tubig sa daang nahimutangan niini. Misulay ang mga Ehiptohanon sa pag-ikyas apan gilumsan sila sa Ginoo. 28Natabonan sa tubig ang tanang kasundalohan sa hari sa Ehipto nga migukod sa mga Israelinhon lakip ang ilang mga tigkabayo ug mga karwahe. Wala gayoy usa kanila nga nakalingkawas. 29Apan ang mga Israelinhon naglakaw sa malang yuta taliwala sa dagat, diin ang mga tubig nahimong morag paril sa ilang isigka-kilid. 30Nianang adlawa, giluwas sa Ginoo ang mga Israelinhon gikan sa kamot sa mga Ehiptohanon. Ug nakita sa mga Israelinhon ang mga patayng lawas sa mga Ehiptohanon nga nagbuy-od sa baybayon. 31Nakita sa mga Israelinhon ang katingalahang gahom sa Ginoo nga iyang gigamit batok sa mga Ehiptohanon. Tungod niini, mitahod ug misalig sila sa Ginoo ug sa iyang alagad nga si Moises.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 14:1-31

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni. 3Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. 4Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.

5Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Ejibiti pé àwọn ènìyàn náà ti sálọ, ọkàn Farao àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.” 6Ó sì di kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, 7ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Ejibiti, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn. 814.8: Ap 13.17.Olúwa sé ọkàn Farao ọba Ejibiti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù. 9Àwọn ará Ejibiti ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹṣin kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bàá òkun ní ìhà Pi-Hahirotu, ni òdìkejì Baali-Ṣefoni.

10Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa. 11Wọ́n sọ fún Mose pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Ejibiti ní ìwọ ṣe mú wa wá láti kú sínú aginjù? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti wá? 1214.12: Ek 16.3; 17.3.Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Ejibiti, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Ejibiti’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Ejibiti ju kí a kú sínú aginjù yìí lọ!”

13Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí, àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́. 14Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”

15Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Israẹli kí wọn máa tẹ̀síwájú. 16Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi Òkun, kí ó lè pín ní yà kí àwọn ọmọ Israẹli lè la òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀. 17Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 18Àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Farao: lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”

19Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn. 20Ó sì wà láàrín àwọn ọmọ-ogun Ejibiti àti Israẹli. Ìkùùkuu sì ṣú òkùnkùn sí àwọn ará Ejibiti ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Israẹli ni òru náà, ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.

21Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà, 2214.22: 1Kọ 10.1,2; Hb 11.29.àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.

23Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun. 24Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti. 25Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.”

26Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.” 27Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun. 28Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.

29Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn. 30Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Israẹli là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti; Israẹli sì rí òkú àwọn ará Ejibiti ni etí òkun. 31Nígbà ti àwọn ọmọ Israẹli rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa ṣe fún wọn lára àwọn ará Ejibiti, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa, wọ́n sì gba Olúwa àti Mose ìránṣẹ́ rẹ gbọ́.