Sekariah 8 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 8:1-23

Ọlọ́run ṣe ìpinnu láti bùkún Jerusalẹmu

1Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá.

2Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.”

3Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”

4Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. 5Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”

6Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

7Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. 8Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”

9Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili. 10Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

12“Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 13Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”

14Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15“Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 168.16: Ef 4.25.Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.

18Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

19Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”

20Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’ 22Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”

23Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

撒迦利亞書 8:1-23

對耶路撒冷的應許

1萬軍之耶和華的話傳給了我,說: 2「萬軍之耶和華說,『我對錫安充滿了火熱的愛,我為錫安而大發烈怒。 3我要回到錫安,住在耶路撒冷耶路撒冷必被稱為忠信之城,我的山必被稱為聖山。這是萬軍之耶和華說的。 4必再次有年紀老邁、手拿拐杖的男女坐在耶路撒冷的街上。這是萬軍之耶和華說的。 5街上必到處都是玩耍的男女孩童。』 6萬軍之耶和華說,『那時,這事在這些餘民看來是不可能的,但在我看來毫不稀奇。這是萬軍之耶和華說的。』 7萬軍之耶和華說,『看啊,我要從東方和西方救出我的子民, 8帶他們回到耶路撒冷居住。他們要做我的子民,我要做他們信實和公義的上帝。』

9「萬軍之耶和華說,『在奠立萬軍之耶和華殿的根基那天,眾先知都在場。現今聽見這些先知之言的人啊,你們要剛強,以便可以建造聖殿! 10那日之前,人和牲畜都得不到工錢。在敵人的威脅下,人們出入沒有平安。因為我使眾人彼此為敵。 11如今我不會像從前那樣對待這些餘民了。這是萬軍之耶和華說的。 12因為他們必平安地撒種,葡萄樹必結果子,土地必出產五穀,天必降下甘霖,我要把這些福氣賜給這些餘民。 13猶大家和以色列家啊,從前你們在列國中是受咒詛的,現在我要拯救你們,使你們成為蒙福的人。你們不要懼怕,要剛強。』

14「萬軍之耶和華說,『從前你們的祖先惹我發怒,我決定毫不留情地降禍給他們。這是萬軍之耶和華說的。 15現在我決定賜福給耶路撒冷猶大家。你們不要懼怕。 16你們所當做的是彼此說真話,在城門口秉公斷案,使人和睦。 17不可設陰謀彼此相害,不可以起假誓為樂,因為這些都是我所憎惡的。這是耶和華說的。』」

18萬軍之耶和華的話傳給了我,說: 19「萬軍之耶和華說,『四月、五月、七月、十月的禁食必成為猶大家歡喜快樂的日子和幸福的節期。因此,你們要喜愛真理與和平。 20各族的人和各城的居民都必來這裡。這是萬軍之耶和華說的。 21這一城的居民必到那一城,說,我們快去向耶和華求恩,去尋求萬軍之耶和華吧!我自己也去。 22各民族和各強國必來耶路撒冷尋求萬軍之耶和華,向耶和華求恩。 23那時,十個來自列國、講不同語言的人必拉住一個猶大人的衣角,說,讓我們跟你們同去吧,因為我們聽說上帝與你們同在。這是萬軍之耶和華說的。』」