Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 3:1-10

Aṣọ mímọ́ fún olórí àlùfáà

1Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i. 23.2: Jd 9.Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”

3A sì wọ Joṣua ni aṣọ èérí, ó sì dúró níwájú angẹli náà. 4Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.”

Ó sì wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo mú kí àìṣedéédéé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”

5Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.

6Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé: 7“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.

83.8: Isa 4.2; Jr 23.5; 33.15; Sk 6.12.‘Gbọ́, ìwọ Joṣua olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsi i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi, Ẹ̀ka náà wá. 9Nítorí kíyèsi i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Joṣua; lórí òkúta kan ni ojú méje wà: kíyèsi i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.

103.10: Mt 4.4.“ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”

New International Version

Zechariah 3:1-10

Clean Garments for the High Priest

1Then he showed me Joshua the high priest standing before the angel of the Lord, and Satan3:1 Hebrew satan means adversary. standing at his right side to accuse him. 2The Lord said to Satan, “The Lord rebuke you, Satan! The Lord, who has chosen Jerusalem, rebuke you! Is not this man a burning stick snatched from the fire?”

3Now Joshua was dressed in filthy clothes as he stood before the angel. 4The angel said to those who were standing before him, “Take off his filthy clothes.”

Then he said to Joshua, “See, I have taken away your sin, and I will put fine garments on you.”

5Then I said, “Put a clean turban on his head.” So they put a clean turban on his head and clothed him, while the angel of the Lord stood by.

6The angel of the Lord gave this charge to Joshua: 7“This is what the Lord Almighty says: ‘If you will walk in obedience to me and keep my requirements, then you will govern my house and have charge of my courts, and I will give you a place among these standing here.

8“ ‘Listen, High Priest Joshua, you and your associates seated before you, who are men symbolic of things to come: I am going to bring my servant, the Branch. 9See, the stone I have set in front of Joshua! There are seven eyes3:9 Or facets on that one stone, and I will engrave an inscription on it,’ says the Lord Almighty, ‘and I will remove the sin of this land in a single day.

10“ ‘In that day each of you will invite your neighbor to sit under your vine and fig tree,’ declares the Lord Almighty.”