Saamu 84 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 84:1-12

Saamu 84

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,

Olúwa àwọn ọmọ-ogun!

2Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́

ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa

àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀

sí Ọlọ́run alààyè.

3Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,

ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,

níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:

ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,

Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

4Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;

wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

5Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ

àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

6Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ

wọn sọ ọ́ di kànga

àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;

7Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá

títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

8Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;

tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.

9Wo asà wa, Ọlọ́run;

fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.

10Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ

ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;

èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi

jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;

Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;

kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn

fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.

12Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.