Saamu 46 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 46:1-11

Saamu 46

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa

ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

2Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,

tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

3Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì

tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

4Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,

ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.

5Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:

Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.

6Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,

ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

7Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,

Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

8Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa

irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.

9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé

ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì

ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná

10Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.

A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè

A ó gbé mi ga ní ayé.

11Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa

Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.