Saamu 23 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 23:1-6

Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

1Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

223.2: If 7.17.Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù

Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;

3Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò

Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo

nítorí orúkọ rẹ̀.

4Bí mo tilẹ̀ ń rìn

Láàrín àfonífojì òjìji ikú,

èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;

nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ

wọ́n ń tù mí nínú.

5Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi

ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;

ìwọ ta òróró sí mi ní orí;

ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.

6Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn

ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,

èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa

títí láéláé.