Saamu 129 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 129:1-8

Saamu 129

Orin fún ìgòkè.

1“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú

láti ìgbà èwe mi wá”

ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;

2“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú

láti ìgbà èwe mi wá;

síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.

3Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:

wọ́n sì la aporo wọn gígùn.

4Olódodo ni Olúwa:

ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”

5Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,

kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.

6Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀

tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:

7Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:

bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.

8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,

ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:

àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.