Saamu 108 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 108:1-13

Saamu 108

Orin. Saamu ti Dafidi.

1108.1-5: Sm 57.7-11.Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin

èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin

2Jí ohun èlò orin àti haapu

èmi ó jí ní kùtùkùtù

3Èmi ó yìn ọ́, Ọlọ́run, nínú àwọn orílẹ̀-èdè

èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn

4Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ

ju àwọn ọ̀run lọ

àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀

5Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,

àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

6108.6-13: Sm 60.5-12.Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;

fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,

kí o sì dá mi lóhùn

7Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé:

“Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,

èmi yóò sì wọn Àfonífojì Sukkoti kúrò.

8Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,

Efraimu ni ìbòrí mi,

Juda ni olófin mi,

9Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,

lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,

lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”

10Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?

Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?

11Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.

Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.

12Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,

nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.

13Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin

nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.