Nehemiah 8 – YCB & CST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 8:1-18

1gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè Omi. Wọ́n sọ fún Esra akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mose jáde, èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún Israẹli.

2Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Esra gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé. 3Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.

4Akọ̀wé Esra dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ni Mattitiah, Ṣema, Anaiah, Uriah, Hilkiah àti Maaseiah gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ ní Pedaiah, Misaeli, Malkiah, Haṣumu, Haṣabadana, Sekariah àti Meṣullamu dúró sí.

5Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró. 6Esra yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.

7Àwọn Lefi—Jeṣua, Bani, Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodiah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani àti Pelaiah—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀. 8Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké.

9Nígbà náà ni Nehemiah tí ó jẹ́ baálẹ̀, Esra àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Lefi tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún” Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sọkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà.

10Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ Olúwa ni agbára yín.”

11Àwọn ọmọ Lefi mú kí gbogbo ènìyàn dákẹ́ jẹ́, wọ́n wí pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí mímọ́ ni ọjọ́ yìí. Ẹ má ṣe banújẹ́.”

12Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn lọ láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì fi ìpín oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá, nítorí báyìí àwọn òfin tí a sọ di mímọ́ fun wọn ti yé wọn.

13Ní ọjọ́ kejì oṣù náà, àwọn olórí, gbogbo ìdílé, àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Esra akọ̀wé, wọ́n fi ara balẹ̀ láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ òfin. 14Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí Olúwa ti pa ní àṣẹ nípasẹ̀ Mose, kí àwọn ọmọ Israẹli gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje 15àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn án kálẹ̀ ní gbogbo ìlú wọn àti ní Jerusalẹmu: “Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olifi àti ẹ̀ka igi olifi igbó, àti láti inú maritili, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́”—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

16Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Efraimu. 17Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú wọn. Láti ọjọ́ Jeṣua ọmọ Nuni títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí. Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀.

18Esra kà nínú ìwé òfin Ọlọ́run, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láti ọjọ́ kìn-ín-ní dé ọjọ́ ìkẹyìn. Wọ́n ṣe àjọyọ̀ àjọ náà fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ní àpéjọ, ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

Nueva Versión Internacional (Castilian)

Nehemías 8:1-18

1Entonces todo el pueblo, como un solo hombre, se reunió en la plaza que está frente a la puerta del Agua y le pidió al maestro Esdras traer el libro de la ley que el Señor le había dado a Israel por medio de Moisés. 2Así que el día primero del mes séptimo, el sacerdote Esdras llevó la ley ante la asamblea, que estaba compuesta de hombres y mujeres y de todos los que podían comprender la lectura, 3y la leyó en presencia de ellos desde el alba hasta el mediodía en la plaza que está frente a la puerta del Agua. Todo el pueblo estaba muy atento a la lectura del libro de la ley.

4El maestro Esdras se puso de pie sobre una plataforma de madera construida para la ocasión. A su derecha estaban Matatías, Semá, Anías, Urías, Jilquías y Maseías; a su izquierda, Pedaías, Misael, Malquías, Jasún, Jasbadana, Zacarías y Mesulán. 5Esdras, a quien la gente podía ver porque él estaba en un lugar más alto, abrió el libro y todo el pueblo se puso de pie. 6Entonces Esdras bendijo al Señor, el gran Dios. Y todo el pueblo, levantando las manos, respondió: «¡Amén y amén!» Luego adoraron al Señor, inclinándose hasta tocar el suelo con la frente.

7Los levitas Jesúa, Baní, Serebías, Jamín, Acub, Sabetay, Hodías, Maseías, Quelitá, Azarías, Jozabed, Janán y Pelaías le explicaban la ley al pueblo, que no se movía de su sitio. 8Ellos leían con claridad el libro de la ley de Dios y lo interpretaban de modo que se comprendiera su lectura.

9Al oír las palabras de la ley, la gente comenzó a llorar. Por eso el gobernador Nehemías, el sacerdote y maestro Esdras y los levitas que enseñaban al pueblo les dijeron: «No lloréis ni os pongáis tristes, porque este día ha sido consagrado al Señor vuestro Dios».

10Luego Nehemías añadió: «Ya podéis iros. Comed bien, tomad bebidas dulces y compartid vuestra comida con quienes no tengan nada, porque este día ha sido consagrado a nuestro Señor. No estéis tristes, pues el gozo del Señor es nuestra fortaleza».

11También los levitas tranquilizaban a todo el pueblo. Les decían: «¡Tranquilos! ¡No estéis tristes, que este es un día santo

12Así que todo el pueblo se fue a comer y beber y compartir su comida, felices de haber comprendido lo que se les había enseñado.

La fiesta de las Enramadas

13Al día siguiente, los jefes de familia, junto con los sacerdotes y los levitas, se reunieron con el maestro Esdras para estudiar los términos de la ley. 14Y en esta encontraron escrito que el Señor le había mandado a Moisés que durante la fiesta del mes séptimo los israelitas debían habitar en enramadas 15y pregonar en todas sus ciudades y en Jerusalén esta orden: «Id a la montaña y traed ramas de olivo, de olivo silvestre, de arrayán, de palmera y de todo árbol frondoso, para hacer enramadas, conforme a lo que está escrito».

16De modo que la gente fue y trajo ramas, y con ellas hizo enramadas en las azoteas, en los patios, en el atrio del templo de Dios, en la plaza de la puerta del Agua y en la plaza de la puerta de Efraín. 17Toda la asamblea de los que habían regresado del cautiverio hicieron enramadas y habitaron en ellas. Como los israelitas no habían hecho esto desde los días de Josué hijo de Nun, hicieron una gran fiesta.

18Todos los días, desde el primero hasta el último, se leyó el libro de la ley de Dios. Celebraron la fiesta durante siete días, y en el día octavo hubo una asamblea solemne, según lo ordenado.