Nehemiah 5 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 5:1-19

Nehemiah ran àwọn aláìní lọ́wọ́

1Nísinsin yìí àwọn ènìyàn àti àwọn ìyàwó wọn kígbe ńlá sókè sí àwọn Júù arákùnrin wọn. 2Àwọn kan ń wí pé, “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀; kí àwa kí ó le è jẹ, kí a sì wà láààyè, a gbọdọ̀ rí oúnjẹ.”

3Àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ti fi oko wa ọgbà àjàrà wa àti ilé wa dógò kí àwa kí ó lè rí oúnjẹ ní àkókò ìyàn.”

4Síbẹ̀ àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ní láti yá owó láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba lórí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹran-ara kan àti ẹ̀jẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú wa tí àwọn ọmọkùnrin wa sì dára bí í tiwọn, síbẹ̀ àwa ní láti fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa sí oko ẹrú. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin wa ti wà lóko ẹrú náà, ṣùgbọ́n àwa kò ní agbára, nítorí àwọn oko àti ọgbà àjàrà wa ti di ti ẹlòmíràn.”

6Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí. 7Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí. 8Mo sì wí fún wọn pé: “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsin yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohunkóhun sọ.

9Nítorí náà, mo tẹ̀síwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀tá wa? 10Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró! 11Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà olifi wọn àti ilé e wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn padà kíákíá.”

12Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà. Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.”

Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí. 13Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!”

Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí.

14Síwájú sí í, láti ogún ọdún ọba Artasasta, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Juda, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀. 15Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn. Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lórí wọn. Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 16Dípò bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi jì fún iṣẹ́ lórí odi yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn mi péjọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà; a kò sì gba ilẹ̀ kankan.

17Síwájú sí í, àádọ́jọ (150) àwọn Júù àti àwọn ìjòyè jẹun lórí tábìlì mi, àti pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wá bá wa láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká. 18Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni a máa ń pèsè màlúù kan, ààyò àgùntàn mẹ́fà àti adìyẹ fún mi àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pèsè onírúurú wáìnì tí ó pọ̀ fún mi. Fún gbogbo èyí, èmi kò béèrè oúnjẹ baálẹ̀, nítorí ohun ti a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pọ̀ jọjọ.

19Rántí mi, Ọlọ́run mi, fún rere, nítorí fún gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún àwọn ènìyàn yìí.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

尼希米記 5:1-19

尼希米幫助窮苦人

1那時,民眾和他們的妻子都抱怨他們的猶太同胞。 2有的說:「我們和我們的兒女人口眾多,需要糧食來活命。」 3有的說:「因為饑荒的緣故,我們要將田地、葡萄園和房屋作抵押來獲取糧食。」 4有的說:「我們要借錢才能繳納王對我們的田地和葡萄園徵收的稅。 5我們和他們是同胞,我們的孩子就像他們的孩子。但現在我們的兒女要被迫成為僕婢,甚至我們的女兒有些已經淪為奴婢。我們卻無能為力,因為我們的田地和葡萄園已經歸別人了。」

6聽到他們的抱怨後,我非常憤怒。 7經過深思熟慮後,我便斥責這些貴族和官員,說:「你們竟然向同胞放高利貸!」於是我召開大會處理他們的問題。 8我對他們說:「我們在盡力贖回那些被賣到外邦的猶太同胞,你們卻要賣他們為奴,好讓我們再贖回他們嗎?」他們都沉默不語,無言以對。 9我繼續說:「你們的所作所為實在不對。難道你們不應該敬畏上帝,以免我們的仇敵凌辱我們嗎? 10我和我的兄弟及僕人都借錢、借糧給民眾,現在我們要停止放高利貸。 11你們今天就要歸還他們的田地、葡萄園、橄欖園和房屋,以及你們向他們所收的五穀、新酒和油的利息。」

12他們說:「我們會照你的話去做,把東西還給他們,不再向他們索債。」於是,我召來祭司,讓這些人起誓遵守自己的諾言。 13我抖著衣服說:「如果你們不守誓言,願上帝也這樣抖掉你們的家園和你們勞碌得來的,使你們一無所有。」全體會眾都說:「阿們!」他們讚美耶和華,民眾都遵照誓言去行。

尼希米大公無私

14亞達薛西王二十年至三十二年,也就是我奉派為猶大省長的十二年間,我和我的弟兄都沒有吃省長的俸祿。 15在我之前的省長使民眾負擔沉重,天天索取食物、酒及五百克銀子。他們的僕人也欺壓民眾,但我因敬畏上帝而沒有這樣做。 16我全心修築城牆,沒有購置田產,我的僕人也都參與修建城牆的工作。 17除了從周圍外邦來到我們這裡的人之外,還有一百五十名猶太人和官員與我一同吃飯。 18我每天需要預備一頭公牛、六隻肥羊和飛禽;每十天還要大量供應各樣酒品。即使這樣,我仍然沒有吃省長的俸祿,因為民眾已經負擔沉重。 19我的上帝啊,求你記念我為這些民眾所做的一切,施恩於我。