Nehemiah 10 – YCB & CARS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 10:1-39

1Àwọn tí ó fi èdìdì dì í ni:

Nehemiah baálẹ̀, ọmọ Hakaliah.

Sedekiah 2Seraiah, Asariah, Jeremiah,

3Paṣuri, Amariah, Malkiah,

4Hattusi, Ṣebaniah, Malluki,

5Harimu, Meremoti, Ọbadiah,

6Daniẹli, Ginetoni, Baruku,

7Meṣullamu, Abijah, Mijamini,

8Maasiah, Bilgai àti Ṣemaiah.

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà.

9Àwọn ọmọ Lefi:

Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Henadadi, Kadmieli,

10àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣebaniah,

Hodiah, Kelita, Pelaiah, Hanani,

11Mika, Rehobu, Haṣabiah,

12Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah,

13Hodiah, Bani àti Beninu.

14Àwọn olórí àwọn ènìyàn:

Paroṣi, Pahati-Moabu, Elamu, Sattu, Bani,

15Bunni, Asgadi, Bebai.

16Adonijah, Bigfai, Adini,

17Ateri, Hesekiah, Assuri,

18Hodiah, Haṣumu, Besai,

19Harifu, Anatoti, Nebai,

20Magpiaṣi, Meṣullamu, Hesiri

21Meṣesabeli, Sadoku, Jaddua

22Pelatiah, Hanani, Anaiah,

23Hosea, Hananiah, Haṣubu,

24Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki,

25Rehumu, Haṣabna, Maaseiah,

26Ahijah, Hanani, Anani,

27Malluki, Harimu, àti Baanah.

28“Àwọn ènìyàn tókù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwó wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé 29gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.

30“A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.

31“Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.

32“Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa: 33Nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

34“Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.

35“Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.

36“Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

37“Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́. 38Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí inú ilé ìṣúra. 39Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí.

“Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

Священное Писание

Неемия 10:1-39

1Печати приложили:

Наместник Неемия, сын Ахалии.

Цедекия, 2Серая, Азария, Иеремия,

3Пашхур, Амария, Малхия,

4Хаттуш, Шевания, Маллух,

5Харим, Меремот, Авдий,

6Даниял, Гиннетон, Барух,

7Мешуллам, Авия, Миямин,

8Маазия, Билгай и Шемая –

это священнослужители.

9Левиты:

Иешуа, сын Азании, Биннуи, из сыновей Хенадада, Кадмиил

10и их собратья: Шевания,

Ходия, Келита, Пелая, Ханан,

11Миха, Рехов, Хашавия,

12Заккур, Шеревия, Шевания,

13Ходия, Бани и Бенину.

14Вожди народа:

Парош, Пахат-Моав, Елам, Затту, Бани,

15Бунни, Азгад, Бевай,

16Адония, Бигвай, Адин,

17Атер, Езекия, Аззур,

18Ходия, Хашум, Бецая,

19Хариф, Анатот, Невай,

20Магпиаш, Мешуллам, Хезир,

21Мешезавил, Цадок, Иаддуа,

22Пелатия, Ханан, Аная,

23Осия, Ханания, Хашув,

24Аллохеш, Пилха, Шовек,

25Рехум, Хашавна, Маасея,

26Ахия, Ханан, Анан,

27Маллух, Харим и Баана.

28– И остальной народ – священнослужители, левиты, привратники, певцы, храмовые слуги и все, кто ради Закона Всевышнего отделился от чужеземных народов, вместе со своими жёнами, и всеми своими сыновьями, и дочерьми, которые способны понимать, – 29все они ныне присоединяются к своим братьям из знати и связывают себя проклятием и клятвой следовать Закону Вечного, данному через Мусу, раба Всевышнего, и бережно исполнять все повеления, законы и установления Вечного, нашего Владыки.

30Мы обещаем не отдавать своих дочерей в жёны народам, которые вокруг нас, и не брать их дочерей за своих сыновей.

31Если народы, которые вокруг нас, принесут на продажу товары или зерно в субботу10:31 См. сноску на 9:14., то мы не станем покупать у них в субботу или в какой-либо другой святой день. Каждый седьмой год мы не будем обрабатывать землю и будем прощать все долги.

32Мы берём на себя обязательство исполнять повеления о том, чтобы каждый год давать по четыре грамма10:32 Букв.: «треть шекеля». серебра на нужды дома нашего Бога: 33на священный хлеб, на постоянные хлебные приношения и всесожжения, на приношения в субботу, Новолуние и в установленные праздники, на священные пожертвования, на жертвы за грех10:33 См. таблицы: «Праздники в Исраиле» и «Жертвоприношения в Исраиле»., чтобы очищать Исраил, и на все работы в доме нашего Бога.

34Мы, священнослужители, левиты и народ, бросили жребий, чтобы узнать, когда каждая из наших семей должна доставлять дрова в дом нашего Бога в установленные сроки каждый год, чтобы жечь их на жертвеннике Вечного, нашего Бога, как написано в Законе.

35Ещё мы берём на себя обязанность каждый год доставлять в дом Вечного первые плоды от наших урожаев и от каждого плодового дерева.

36И как ещё написано в Законе, мы будем приводить к священнослужителям в доме нашего Бога первенцев из наших сыновей и первородное от скота – из наших стад и отар.

37Ещё мы будем приносить в хранилища дома нашего Бога, к священнослужителям, муку первого помола, наши хлебные приношения от первых плодов, первые плоды всех наших деревьев и нашего молодого вина и масла. Мы будем приносить десятую часть наших урожаев левитам, ведь это левитам надлежит собирать десятую часть во всех городах, где мы обрабатываем землю. 38Когда левиты собирают десятую часть, их должен сопровождать священнослужитель, ведущий свой род от Харуна, а левиты должны доставлять десятую часть от десятой части в дом нашего Бога, в комнаты хранилища. 39Народ Исраила, включая левитов, должен приносить свои пожертвования зерна, молодого вина и масла в хранилища, где хранятся предметы для святилища и где живут священнослужители, которые находятся на службе, и привратники, а также певцы.

Мы не оставим дом нашего Бога.