Matiu 14 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 14:1-36

A bẹ́ Johanu Onítẹ̀bọmi lórí

114.1-2: Mk 6.14-16; Lk 9.7-9; Mk 8.28.Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, 2ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”

314.3-4: Mk 6.17-18; Lk 3.19-20; Le 18.16; 20.21.Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, 4nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” 514.5-12: Mk 6.19-29.Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.

6Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. 7Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. 8Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. 9Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. 10Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. 11A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 12Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn

1314.13-21: Mk 6.32-44; Lk 9.10-17; Jh 6.1-13; Mt 15.32-38.Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. 14Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.

15Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”

16Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

17Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”

18Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 1914.19: Mk 14.22; Lk 24.30.Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. 21Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Jesu rìn lójú omi

2214.22-23: Mk 6.45-46; Jh 6.15-17.Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn 23Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, 2414.24-33: Mk 6.47-52; Jh 6.16-21.ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.

25Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. 2614.26: Lk 24.37.Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.

27Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

28Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”

2914.29: Jh 21.7.Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”

Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. 30Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”

3114.31: Mt 6.30; 8.26; 16.8.Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”

32Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. 3314.33: Mt 28.9,17.Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”

3414.34-36: Mk 6.53-56; Gẹ 6.22.Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. 35Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. 3614.36: Mk 3.10; Nu 15.38; Mt 9.20.Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

New International Version

Matthew 14:1-36

John the Baptist Beheaded

1At that time Herod the tetrarch heard the reports about Jesus, 2and he said to his attendants, “This is John the Baptist; he has risen from the dead! That is why miraculous powers are at work in him.”

3Now Herod had arrested John and bound him and put him in prison because of Herodias, his brother Philip’s wife, 4for John had been saying to him: “It is not lawful for you to have her.” 5Herod wanted to kill John, but he was afraid of the people, because they considered John a prophet.

6On Herod’s birthday the daughter of Herodias danced for the guests and pleased Herod so much 7that he promised with an oath to give her whatever she asked. 8Prompted by her mother, she said, “Give me here on a platter the head of John the Baptist.” 9The king was distressed, but because of his oaths and his dinner guests, he ordered that her request be granted 10and had John beheaded in the prison. 11His head was brought in on a platter and given to the girl, who carried it to her mother. 12John’s disciples came and took his body and buried it. Then they went and told Jesus.

Jesus Feeds the Five Thousand

13When Jesus heard what had happened, he withdrew by boat privately to a solitary place. Hearing of this, the crowds followed him on foot from the towns. 14When Jesus landed and saw a large crowd, he had compassion on them and healed their sick.

15As evening approached, the disciples came to him and said, “This is a remote place, and it’s already getting late. Send the crowds away, so they can go to the villages and buy themselves some food.”

16Jesus replied, “They do not need to go away. You give them something to eat.”

17“We have here only five loaves of bread and two fish,” they answered.

18“Bring them here to me,” he said. 19And he directed the people to sit down on the grass. Taking the five loaves and the two fish and looking up to heaven, he gave thanks and broke the loaves. Then he gave them to the disciples, and the disciples gave them to the people. 20They all ate and were satisfied, and the disciples picked up twelve basketfuls of broken pieces that were left over. 21The number of those who ate was about five thousand men, besides women and children.

Jesus Walks on the Water

22Immediately Jesus made the disciples get into the boat and go on ahead of him to the other side, while he dismissed the crowd. 23After he had dismissed them, he went up on a mountainside by himself to pray. Later that night, he was there alone, 24and the boat was already a considerable distance from land, buffeted by the waves because the wind was against it.

25Shortly before dawn Jesus went out to them, walking on the lake. 26When the disciples saw him walking on the lake, they were terrified. “It’s a ghost,” they said, and cried out in fear.

27But Jesus immediately said to them: “Take courage! It is I. Don’t be afraid.”

28“Lord, if it’s you,” Peter replied, “tell me to come to you on the water.”

29“Come,” he said.

Then Peter got down out of the boat, walked on the water and came toward Jesus. 30But when he saw the wind, he was afraid and, beginning to sink, cried out, “Lord, save me!”

31Immediately Jesus reached out his hand and caught him. “You of little faith,” he said, “why did you doubt?”

32And when they climbed into the boat, the wind died down. 33Then those who were in the boat worshiped him, saying, “Truly you are the Son of God.”

34When they had crossed over, they landed at Gennesaret. 35And when the men of that place recognized Jesus, they sent word to all the surrounding country. People brought all their sick to him 36and begged him to let the sick just touch the edge of his cloak, and all who touched it were healed.