Matiu 1 – YCB & JCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 1:1-25

Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jesu Kristi

1Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

2Abrahamu ni baba Isaaki;

Isaaki ni baba Jakọbu;

Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

3Juda ni baba Peresi àti Sera,

Tamari sì ni ìyá rẹ̀,

Peresi ni baba Hesroni:

Hesroni ni baba Ramu;

4Ramu ni baba Amminadabu;

Amminadabu ni baba Nahiṣoni;

Nahiṣoni ni baba Salmoni;

5Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀;

Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀;

Obedi sì ni baba Jese;

6Jese ni baba Dafidi ọba.

Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

7Solomoni ni baba Rehoboamu,

Rehoboamu ni baba Abijah,

Abijah ni baba Asa,

8Asa ni baba Jehoṣafati;

Jehoṣafati ni baba Jehoramu;

Jehoramu ni baba Ussiah;

9Ussiah ni baba Jotamu;

Jotamu ni baba Ahaṣi;

Ahaṣi ni baba Hesekiah;

10Hesekiah ni baba Manase;

Manase ni baba Amoni;

Amoni ni baba Josiah;

111.11: 2Ọb 24.14; Jr 27.20.Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

12Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli:

Jekoniah ni baba Ṣealitieli;

Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

13Serubbabeli ni baba Abihudi;

Abihudi ni baba Eliakimu;

Eliakimu ni baba Asori;

14Asori ni baba Sadoku;

Sadoku ni baba Akimu;

Akimu ni baba Elihudi;

15Elihudi ni baba Eleasari;

Eleasari ni baba Mattani;

Mattani ni baba Jakọbu;

16Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

17Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

Ìtàn ibí Jesu Kristi

181.18: Lk 1.26-38.Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. 19Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

20Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. 211.21: Lk 2.21; Jh 1.29; Ap 13.23.Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: 231.23: Isa 7.14.“Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”

24Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. 25Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.

Japanese Contemporary Bible

マタイの福音書 1:1-25

1

イエスの系図

1これは、イエス・キリストの系図です。イエス・キリストはダビデ王の子孫、さらにさかのぼってアブラハムの子孫です。

2アブラハムはイサクの父、イサクはヤコブの父、ヤコブはユダとその兄弟たちの父です。

3ユダはパレスとザラの父〔彼らの母はタマル〕、パレスはエスロンの父、エスロンはアラムの父です。

4アラムはアミナダブの父、アミナダブはナアソンの父、ナアソンはサルモンの父です。

5サルモンはボアズの父〔母はラハブ〕、ボアズはオベデの父〔母はルツ〕、オベデはエッサイの父です。

6エッサイはダビデ王の父、ダビデはソロモンの父〔母はウリヤの妻でした〕です。

7ソロモンはレハブアムの父、レハブアムはアビヤの父、アビヤはアサの父です。

8アサはヨサパテの父、ヨサパテはヨラムの父、ヨラムはウジヤの父です。

9ウジヤはヨタムの父、ヨタムはアハズの父、アハズはヒゼキヤの父です。

10ヒゼキヤはマナセの父、マナセはアモンの父、アモンはヨシヤの父です。

11ヨシヤはエコニヤとその兄弟たちの父です〔彼らは、イスラエルの人たちがバビロンに移住していた時に生まれました〕。

12バビロンに移住してからは、エコニヤはサラテルの父、サラテルはゾロバベルの父です。

13ゾロバベルはアビウデの父、アビウデはエリヤキムの父、エリヤキムはアゾルの父です。

14アゾルはサドクの父、サドクはアキムの父、アキムはエリウデの父です。

15エリウデはエレアザルの父、エレアザルはマタンの父、マタンはヤコブの父です。

16そして、ヤコブはヨセフの父です〔このヨセフが、キリストと呼ばれるイエスの母マリヤの夫となった人です〕。

17こういう次第で、アブラハムからダビデ王までが十四代、ダビデ王からバビロン移住までが十四代、バビロン移住からキリストまでが十四代となります。

約束されていた救い主

18イエス・キリストの誕生は次のとおりです。母マリヤはヨセフと婚約していました。ところが結婚する前に、聖霊によってみごもったのです。 19婚約者のヨセフは、神の教えを堅く守る人でしたから、婚約を破棄しようと決心しました。しかし、人前にマリヤの恥をさらしたくなかったので、ひそかに縁を切ることにしました。

20ヨセフがこのことで悩んでいた時、天使が夢に現れて言いました。「ダビデの子孫ヨセフよ。ためらわないで、マリヤと結婚しなさい。マリヤは聖霊によってみごもったのです。 21彼女は男の子を産みます。その子をイエス(「主は救い」の意)と名づけなさい。この方こそ、ご自分を信じる人々を罪から救ってくださるからです。 22このことはみな、神が預言者(神に託されたことばを語る人)を通して語られた、次のことばが実現するためです。

23『見よ。処女がみごもって、男の子を産む。その子はインマヌエル〔神が私たちと共におられる〕と呼ばれる。』イザヤ7・14

24目が覚めるとヨセフは、天使の命じたとおり、マリヤと結婚しました。 25しかし、その子が生まれるまでは、マリヤに触れませんでした。そして、生まれた子をイエスと名づけました。