Lefitiku 17 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 17:1-16

Ẹ̀jẹ̀ jíjẹ jẹ́ èèwọ̀

1Olúwa sọ fún Mose pé: 2“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ nìyí: 3Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó 4tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 5Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé: kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa. 6Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa. 7Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.

8“Kí ó sọ fún wọn pé: ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ 9tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

1017.10-16: Le 3.17; 7.26,27; 19.26; De 12.16,23-25.“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13“ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.

15“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀: tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò: ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́. 16Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”

Thai New Contemporary Bible

เลวีนิติ 17:1-16

ห้ามกินเลือด

1องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 2“จงกล่าวแก่อาโรนกับบรรดาบุตรชายและปวงชนอิสราเอลว่า ‘องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงบัญชาไว้ดังนี้ว่า 3ชาวอิสราเอลคนใดถวายวัว17:3 ในภาษาฮีบรูคำนี้เป็นได้ทั้งตัวผู้และตัวเมีย ลูกแกะหรือแพะในค่ายหรือนอกค่าย 4แทนที่จะนำมาที่ทางเข้าเต็นท์นัดพบ เพื่อถวายเป็นเครื่องบูชาแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าหน้าพลับพลาขององค์พระผู้เป็นเจ้าให้ถือว่าชายคนนั้นได้ทำผิดในเรื่องทำให้โลหิตตก และจะถูกตัดออกจากหมู่ประชากรของเขา 5กฎข้อนี้มีไว้เพื่อให้ชนอิสราเอลเลิกถวายเครื่องบูชากลางแจ้ง พวกเขาต้องนำมาให้ปุโรหิต นั่นคือนำมาถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าตรงทางเข้าเต็นท์นัดพบ แล้วเผาถวายเป็นเครื่องสันติบูชา 6ปุโรหิตจะพรมเลือดบนแท่นบูชาตรงทางเข้าเต็นท์นัดพบ และเผาไขมันเป็นกลิ่นหอมซึ่งองค์พระผู้เป็นเจ้าพอพระทัย 7ประชากรจะได้เลิกถวายเครื่องบูชาแก่เทวรูปแพะ17:7 หรือผีมารซาตาน อันเป็นการทำตัวแพศยา นี่เป็นข้อปฏิบัติถาวรสำหรับเจ้าทั้งหลายสืบไปทุกชั่วอายุ’

8“จงกล่าวแก่พวกเขาว่า ‘เราขอย้ำว่าผู้ใดก็ตามไม่ว่าชาวอิสราเอลหรือคนต่างด้าวซึ่งอาศัยอยู่ในหมู่พวกเขาที่ถวายเครื่องเผาบูชาหรือเครื่องบูชาในที่อื่น 9และไม่ได้นำมาตรงทางเข้าเต็นท์นัดพบเพื่อถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้า จะต้องถูกตัดออกจากหมู่ประชากรของเขา

10“ ‘เราจะเป็นปฏิปักษ์กับทุกคนที่กินเลือดทุกชนิด ไม่ว่าคนนั้นจะเป็นคนอิสราเอลหรือคนต่างด้าวซึ่งอาศัยอยู่ในหมู่พวกเขา เราจะตัดคนนั้นออกจากหมู่ประชากรของเขา 11เพราะชีวิตของสิ่งมีชีวิตอยู่ในเลือด และเราได้ให้เลือดแก่เจ้าเพื่อลบบาปสำหรับตัวเจ้าบนแท่นบูชา เลือดนั้นเองที่ได้ลบบาปสำหรับชีวิตของคนๆ หนึ่ง 12ฉะนั้นเราจึงสั่งชาวอิสราเอลว่า “พวกเจ้าและคนต่างด้าวซึ่งอาศัยอยู่ในหมู่พวกเจ้าจะต้องไม่กินเลือด”

13“ ‘ใครก็ตาม ไม่ว่าชาวอิสราเอลหรือคนต่างด้าวซึ่งอาศัยอยู่ในหมู่พวกเจ้าที่ล่าสัตว์ แล้วฆ่าสัตว์หรือนกที่อนุญาตให้เป็นอาหารได้ จะต้องรินเลือดออกมาแล้วเอาดินกลบ 14เพราะชีวิตของสิ่งมีชีวิตทุกอย่างคือเลือด นั่นเป็นเหตุที่เราพูดกับชาวอิสราเอลว่า “เจ้าจะต้องไม่กินเลือดของสิ่งมีชีวิตใดๆ เพราะชีวิตของสิ่งมีชีวิตทุกชนิดคือเลือดของมัน ผู้ใดกินเลือดจะต้องถูกตัดออก”

15“ ‘ผู้ใดไม่ว่าคนอิสราเอลโดยกำเนิดหรือคนต่างด้าว ซึ่งกินซากของสัตว์ใดที่ตายเองหรือถูกสัตว์ร้ายฆ่าตาย จะต้องซักเสื้อผ้าและอาบน้ำ และเป็นมลทินตามระเบียบพิธีจนถึงเวลาเย็น แล้วเขาจึงจะสะอาด 16แต่หากเขาไม่อาบน้ำและซักเสื้อผ้า เขาจะต้องรับผิดชอบ’ ”