Jona 4 – YCB & PCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jona 4:1-11

Jona bínú sí àánú tí Olúwa fihàn

1Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀. 24.2: El 34.6.Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà. 3Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”

4Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”

5Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. 6Olúwa Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà. 7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ. 8Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”

9Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?”

Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”

10Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan. 11Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”

Persian Contemporary Bible

يونس 4:1-11

سنگدلی يونس و رحمت خداوند

1اما يونس از اين موضوع ناراحت و خشمگين شد. 2او نزد خداوند دعا كرد و گفت: «خداوندا، وقتی در مملكت خود بودم و تو به من گفتی به اينجا بيايم، می‌دانستم كه تو از تصميم خود منصرف خواهی شد، زيرا تو خدايی مهربان و بخشنده هستی و دير غضبناک می‌شوی و بسيار احسان می‌كنی. برای همين بود كه خواستم به ترشيش فرار كنم.

3«خداوندا، اينک جانم را بگير، زيرا برای من مردن بهتر از زنده ماندن است.»

4آنگاه خداوند به وی فرمود: «آيا درست است كه از اين بابت عصبانی شوی؟»

5يونس از شهر خارج شده، به طرف شرق رفت. در خارج از شهر برای خود سايبانی ساخته، زير سايهٔ آن منتظر نشست تا ببيند بر سر شهر چه می‌آيد. 6آنگاه خداوند به سرعت گياهی رويانيد و برگهای پهن آن را بر سر يونس گسترانيد تا بر او سايه بيندازد و به او راحتی ببخشد. يونس از سايهٔ گياه بسيار شاد شد. 7اما صبح روز بعد خدا كرمی بوجود آورد و كرم ساقهٔ گياه را خورد و گياه خشک شد. 8وقتی كه آفتاب برآمد و هوا گرم شد، خداوند بادی سوزان از جانب شرق بر يونس وزانيد و آفتاب چنان بر سر او تابيد كه بی‌تاب شده، آرزوی مرگ كرد و گفت: «برای من مردن بهتر از زنده ماندن است.»

9آنگاه خداوند به يونس فرمود: «آيا از خشک شدن گياه بايد عصبانی شوی؟»

يونس گفت: «بلی، بايد تا به حد مرگ هم عصبانی شوم.»

10خداوند فرمود: «برای گياهی كه در يک شب به وجود آمد و در يک شب از بين رفت دلت سوخت، با آنكه برايش هيچ زحمتی نكشيده بودی؛ 11پس آيا دل من برای شهر بزرگ نينوا نسوزد كه در آن بيش از صد و بيست هزار بچهٔ معصوم و بی‌گناه، و نيز حيوانات بسيار وجود دارد؟»