Jobu 8 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 8:1-22

Bilidadi

1Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé:

2“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó?

Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?

3Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí?

Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?

4Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i,

ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.

5Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò,

tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.

6Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin:

ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ,

òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.

7Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,

bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.

8“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì

kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.

9Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,

nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.

10Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?

Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?

11Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀

tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?

12Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,

ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀

13Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,

bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.

14Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,

àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.

15Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,

yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.

16Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn,

ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.

17Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,

ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.

18Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,

nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’

19Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù

àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.

20“Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,

bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́

21títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,

àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,

22ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,

àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”

New International Reader’s Version

Job 8:1-22

The First Speech of Bildad

1Then Bildad the Shuhite replied,

2“Job, how long will you talk like that?

Your words don’t have any meaning.

3Does God ever treat people unfairly?

Does the Mighty One make what is wrong

appear to be right?

4Your children sinned against him.

So he punished them for their sin.

5But seek God with all your heart.

Make your appeal to the Mighty One.

6Be pure and honest.

And he will rise up and help you now.

He’ll give you everything you had before.

7In the past, things went well with you.

But in days to come, things will get even better.

8“Find out what our parents taught.

Discover what those who lived before them learned.

9After all, we were born only yesterday.

So we don’t know anything.

Our days on this earth are like a shadow that disappears.

10Won’t your people of long ago teach you and tell you?

Won’t the things they said help you understand?

11Can grass grow tall where there isn’t any swamp?

Can plants grow well where there isn’t any water?

12While they are still growing and haven’t been cut,

they dry up faster than grass does.

13The same thing happens to everyone who forgets God.

The hope of ungodly people dies out.

14What they trust in is very weak.

What they depend on is like a spider’s web.

15They lean on it, but it falls apart.

They hold on to it, but it gives way.

16They are like a plant in the sunshine

that receives plenty of water.

It spreads its new growth all over the garden.

17It wraps its roots around a pile of rocks.

It tries to find places to grow among the stones.

18But when the plant is pulled up from its spot,

that place says, ‘I never saw you.’

19The life of that plant is sure to dry up.

But from the same soil other plants will grow.

20“I’m sure God doesn’t turn his back on anyone who is honest.

And he doesn’t help those who do what is evil.

21He will fill your mouth with laughter.

Shouts of joy will come from your lips.

22Your enemies will put on shame as if it were clothes.

The tents of sinful people will be gone.”