Jobu 5 – YCB & PCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 5:1-27

Ìjìyà jẹ́ èso àìṣòdodo

1“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn?

Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?

2Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye,

ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.

3Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀,

ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.

4Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu,

a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè,

bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.

5Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ,

tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó,

àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì.

6Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni,

tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.

7Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà,

gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.

8“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀,

ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.

9Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,

ohun ìyanu láìní iye.

10Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé

tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.

11Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè

kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

125.12-13: 1Kọ 3.19.Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po,

bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.

13Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn,

àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.

14Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán;

wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.

15Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà,

lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà,

àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

17“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,

nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.

18Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura,

ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.

19Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,

àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ

20Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú

àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

21A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n,

bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.

22Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn,

bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.

23Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀,

àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.

24Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà,

ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà.

25Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀

àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.

26Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,

bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.

27“Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!

Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”

Persian Contemporary Bible

ايوب 5:1-27

1فرياد برمی‌آورند و كمک می‌طلبند، ولی كسی گوش نمی‌دهد. به سوی خدايان خود روی می‌آورند، اما هيچكدام از آنها به دادشان نمی‌رسد. 2سرانجام در عجز و درماندگی از غصه می‌ميرند. 3كسانی كه از خدا برمی‌گردند، ظاهراً كامياب هستند، ولی بلای ناگهانی بر آنها نازل می‌شود. 4فرزندان ايشان بی‌پناه می‌گردند و كسی از آنها حمايت نمی‌كند. 5محصولاتشان را گرسنگان می‌خورند و ثروتشان را حريصان غارت می‌كنند. 6بلا و بدبختی هرگز بدون علت دامنگير انسان نمی‌شود. 7بدبختی از خود انسان سرچشمه می‌گيرد، همچنانكه شعله از آتش برمی‌خيزد.

8اگر من جای تو بودم، مشكل خود را نزد خدا می‌بردم. 9زيرا او معجزات شگفت‌انگيز می‌كند و كارهای عجيب و خارق‌العادهٔ بی‌شمار انجام می‌دهد. 10بر زمين باران می‌باراند و كشتزارها را سيراب می‌كند، 11فروتنان را سرافراز می‌گرداند و رنجديدگان را شادی می‌بخشد. 12او نقشه‌های اشخاص حيله‌گر را نقش بر آب می‌كند تا كاری از پيش نبرند. 13آنها را در دامهای خود گرفتار می‌سازد و توطئه‌های ايشان را خنثی می‌نمايد. 14روز روشن برای آنها مانند شب تاريک است و در آن كورمال كورمال راه می‌روند.

15خدا مظلومان و فقيران را از چنگ ظالمان می‌رهاند. 16او به فقيران اميد می‌بخشد و دهان ظالمان را می‌بندد.

17خوشا به حال كسی كه خدا تنبيه‌اش می‌كند. پس وقتی او تو را تنبيه می‌نمايد، دلگير نشو. 18اگر خدا تو را مجروح كند خودش هم زخمهايت را می‌بندد و تو را شفا می‌بخشد 19و از هر بلايی می‌رهاند.

20خدا تو را هنگام قحطی از مرگ نجات خواهد داد و در موقع جنگ از دم شمشير خواهد رهانيد.

21از زخم زبان در امان خواهی بود و از هلاكت محفوظ خواهی ماند.

22به جنگ و قحطی خواهی خنديد و حيوانات وحشی به تو آسيبی نخواهد رسانيد. 23زمينی كه شخم می‌زنی خالی از سنگ خواهد بود و جانوران خطرناک با تو در صلح و صفا به سر خواهند برد.

24خانهٔ تو در امان خواهد بود و از اموال تو چيزی دزديده نخواهد شد.

25نسل تو مانند علف صحرا زياد خواهند بود، 26و تو همچون خوشهٔ گندم كه تا وقتش نرسد درو نمی‌شود، در كمال پيری، كامياب از دنيا خواهی رفت. 27تجربه به من ثابت كرده است كه همهٔ اينها حقيقت دارد؛ پس به خاطر خودت نصيحت مرا بشنو.