Jobu 40 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 40:1-24

Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀

1Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé:

2“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?

Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”

3Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,

4“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?

Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.

5Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;

lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”

6Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé:

7“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,

èmi ó bi ọ léèrè,

kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

8“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?

Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo

9Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run

tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?

10Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,

tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.

11Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;

kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.

12Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀

kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,

kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú

14Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,

ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

15“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,

tí mo dá pẹ̀lú rẹ,

òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

16Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.

17Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari;

Iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.

18Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ;

Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.

19Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;

síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

20Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,

níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.

21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,

lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.

22Igi lótusì ṣíji wọn bò o;

igi arọrọ odò yí i káàkiri.

23Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;

ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.

24Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,

tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?

New Amharic Standard Version

ኢዮብ 40:1-24

1እግዚአብሔርም ኢዮብን እንዲህ አለው፤

2“ሁሉን ከሚችል አምላክ ጋር ተከራክሮ የሚረታው አለን?

እግዚአብሔርን የሚወቅሥ እርሱ መልስ ይስጥ!”

3ኢዮብም ለእግዚአብሔር እንዲህ ሲል መለሰ፤

4“እኔ ከንቱ ሰው፣ ምን እመልስልሃለሁ?

እጄን በአፌ ላይ እጭናለሁ።

5አንድ ጊዜ ተናገርሁ፤ የምመልሰው የለኝም፤

ሁለተኛም ተናገርሁ፤ ከእንግዲህ አንዳች አልጨምርም።”

6እግዚአብሔርም በዐውሎ ነፋስ ውስጥ ሆኖ፣ ለኢዮብ እንዲህ ሲል ተናገረ፤

7“እንግዲህ እንደ ወንድ ወገብህን ታጠቅ፤

እኔ እጠይቅሃለሁ፤

አንተም መልስልኝ።

8“ፍርዴን ታቃልላለህን?

ወይስ አንተ ጻድቅ ለመሆን እኔን ትኰንናለህ?

9እንደ እግዚአብሔር ክንድ ያለ ክንድ አለህን?

ድምፅህስ እንደ እርሱ ድምፅ ሊያንጐደጕድ ይችላልን?

10እንግዲያስ ክብርንና ልዕልናን ተጐናጸፍ፤

ግርማ ሞገስንም ተላበስ፤

11ቍጣህን አፍስስ፤

ትዕቢተኛውን ሁሉ ተመልክተህ አዋርደው፤

12ትዕቢተኛውን ሰው ሁሉ ተመልክተህ ዝቅ አድርገው፤

ክፉዎችንም በቆሙበት ስፍራ አድቅቃቸው።

13ሁሉንም በአንድ ላይ ከዐፈር ደባልቃቸው፤

ፊታቸውንም በመቃብር ውስጥ ሸፍን።

14እኔም ቀኝ እጅህ እንደምታድንህ፣

በዚያን ጊዜ አረጋግጬ እቀበላለሁ።

15“አንተን እንደ ፈጠርሁ፣ የፈጠርሁትን

‘ብሄሞት’40፥15 ጕማሬ ወይም ዝሆን ተመልከት፤

እንደ በሬ ሣር ይበላል፤

16ብርታቱ ወገቡ ውስጥ፣

ኀይሉም በሆዱ ጡንቻ ላይ ነው።

17ጅራቱ40፥17 ምናልባት ግንዱ ማለት ሊሆን ይችላል። እንደ ጥድ ዛፍ ይወዛወዛል፤

የወርቹ ጅማት የተጐነጐነ ነው።

18ዐጥንቱ እንደ ናስ ቱቦ፣

እጅና እግሮቹም እንደ ብረት ዘንግ ናቸው።

19እርሱ የእግዚአብሔር ሥራ አውራ ነው፤

በሰይፍ ሊቀርበውም የሚችል ፈጣሪው ብቻ ነው።

20ኰረብቶች ምግቡን ያበቅሉለታል፤

አውሬዎችም ሁሉ በዙሪያው ይፈነጫሉ።

21በውሃ ላይ በሚያድጉ ዕፀዋት ጥላ ሥር ይተኛል፤

በረግረግ ስፍራ ደንገል መካከል ይደበቃል።

22በውሃ ላይ የሚያድጉ ዕፀዋት በጥላቸው ይጋርዱታል፤

የወንዝ አኻያ ዛፎች ይሸፍኑታል።

23ወንዙ በኀይል ቢጐርፍም፣ አይደነግጥም፤

ዮርዳኖስ እስከ አፉ ቢሞላም፣ እርሱ ተረጋግቶ ይቀመጣል።

24ዐይኑን ሸፍነህ ልትይዘው፣

አጥምደህም አፍንጫውን ልትበሳ ትችላለህ?