Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 36:1-33

1Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:

2“Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,

nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.

3Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,

èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.

4Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké

nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

5“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì

gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

6Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,

ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,

ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;

àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a

sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9Nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,

wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.

10Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,

ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.

11Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,

wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,

àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,

wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,

wọ́n á sì kú láìní òye.

13“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;

wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.

14Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,

ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.

15Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,

a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.

16“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,

sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,

ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.

17Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;

ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.

18Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;

láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.

19Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?

Tàbí ipa agbára rẹ?

20Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké

àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.

21Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú;

Nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

22“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;

ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?

23Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,

tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?

24Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,

ti ènìyàn ni yín nínú orin.

25Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;

ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè,

26Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,

bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

27“Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,

kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,

28tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,

tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.

29Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,

tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?

30Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká

ó sì bo ìsàlẹ̀ Òkun mọ́lẹ̀.

31Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;

ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

32Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì

ó sì rán an sí ẹni olódì.

33Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;

ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!

New International Version

Job 36:1-33

1Elihu continued:

2“Bear with me a little longer and I will show you

that there is more to be said in God’s behalf.

3I get my knowledge from afar;

I will ascribe justice to my Maker.

4Be assured that my words are not false;

one who has perfect knowledge is with you.

5“God is mighty, but despises no one;

he is mighty, and firm in his purpose.

6He does not keep the wicked alive

but gives the afflicted their rights.

7He does not take his eyes off the righteous;

he enthrones them with kings

and exalts them forever.

8But if people are bound in chains,

held fast by cords of affliction,

9he tells them what they have done—

that they have sinned arrogantly.

10He makes them listen to correction

and commands them to repent of their evil.

11If they obey and serve him,

they will spend the rest of their days in prosperity

and their years in contentment.

12But if they do not listen,

they will perish by the sword36:12 Or will cross the river

and die without knowledge.

13“The godless in heart harbor resentment;

even when he fetters them, they do not cry for help.

14They die in their youth,

among male prostitutes of the shrines.

15But those who suffer he delivers in their suffering;

he speaks to them in their affliction.

16“He is wooing you from the jaws of distress

to a spacious place free from restriction,

to the comfort of your table laden with choice food.

17But now you are laden with the judgment due the wicked;

judgment and justice have taken hold of you.

18Be careful that no one entices you by riches;

do not let a large bribe turn you aside.

19Would your wealth or even all your mighty efforts

sustain you so you would not be in distress?

20Do not long for the night,

to drag people away from their homes.36:20 The meaning of the Hebrew for verses 18-20 is uncertain.

21Beware of turning to evil,

which you seem to prefer to affliction.

22“God is exalted in his power.

Who is a teacher like him?

23Who has prescribed his ways for him,

or said to him, ‘You have done wrong’?

24Remember to extol his work,

which people have praised in song.

25All humanity has seen it;

mortals gaze on it from afar.

26How great is God—beyond our understanding!

The number of his years is past finding out.

27“He draws up the drops of water,

which distill as rain to the streams36:27 Or distill from the mist as rain;

28the clouds pour down their moisture

and abundant showers fall on mankind.

29Who can understand how he spreads out the clouds,

how he thunders from his pavilion?

30See how he scatters his lightning about him,

bathing the depths of the sea.

31This is the way he governs36:31 Or nourishes the nations

and provides food in abundance.

32He fills his hands with lightning

and commands it to strike its mark.

33His thunder announces the coming storm;

even the cattle make known its approach.36:33 Or announces his coming— / the One zealous against evil