Jobu 30 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 30:1-31

Ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ Jobu

1“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,

àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà

baba ẹni tí èmi kẹ́gàn

láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.

2Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi,

níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?

3Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn

wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ

ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.

4Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó;

gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.

5A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn,

àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

6A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta Àfonífojì,

nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.

7Wọ́n ń dún ní àárín igbó

wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.

8Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé,

àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.

9“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin;

àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.

10Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi,

wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.

11Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú;

àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.

12Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi;

wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò,

wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.

13Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú;

wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀,

àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

14Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru;

ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.

15Ẹ̀rù ńlá bà mí;

wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù,

àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.

16“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀;

ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.

17Òru gún mi nínú egungun mi,

èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.

18Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi,

ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.

19Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,

èmi sì dàbí eruku àti eérú.

20“Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;

èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.

21Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́

agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.

22Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,

bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.

23Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,

sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.

24“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,

tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.

25Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?

Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?

26Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;

nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.

27Ikùn mí n ru kò sì sinmi;

Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.

28Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn;

èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.

29Èmi ti di arákùnrin ìkookò,

èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.

30Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi;

egungun mi sì jórun fún ooru.

31Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,

àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.

New International Version

Job 30:1-31

1“But now they mock me,

men younger than I,

whose fathers I would have disdained

to put with my sheep dogs.

2Of what use was the strength of their hands to me,

since their vigor had gone from them?

3Haggard from want and hunger,

they roamed30:3 Or gnawed the parched land

in desolate wastelands at night.

4In the brush they gathered salt herbs,

and their food30:4 Or fuel was the root of the broom bush.

5They were banished from human society,

shouted at as if they were thieves.

6They were forced to live in the dry stream beds,

among the rocks and in holes in the ground.

7They brayed among the bushes

and huddled in the undergrowth.

8A base and nameless brood,

they were driven out of the land.

9“And now those young men mock me in song;

I have become a byword among them.

10They detest me and keep their distance;

they do not hesitate to spit in my face.

11Now that God has unstrung my bow and afflicted me,

they throw off restraint in my presence.

12On my right the tribe30:12 The meaning of the Hebrew for this word is uncertain. attacks;

they lay snares for my feet,

they build their siege ramps against me.

13They break up my road;

they succeed in destroying me.

‘No one can help him,’ they say.

14They advance as through a gaping breach;

amid the ruins they come rolling in.

15Terrors overwhelm me;

my dignity is driven away as by the wind,

my safety vanishes like a cloud.

16“And now my life ebbs away;

days of suffering grip me.

17Night pierces my bones;

my gnawing pains never rest.

18In his great power God becomes like clothing to me30:18 Hebrew; Septuagint power he grasps my clothing;

he binds me like the neck of my garment.

19He throws me into the mud,

and I am reduced to dust and ashes.

20“I cry out to you, God, but you do not answer;

I stand up, but you merely look at me.

21You turn on me ruthlessly;

with the might of your hand you attack me.

22You snatch me up and drive me before the wind;

you toss me about in the storm.

23I know you will bring me down to death,

to the place appointed for all the living.

24“Surely no one lays a hand on a broken man

when he cries for help in his distress.

25Have I not wept for those in trouble?

Has not my soul grieved for the poor?

26Yet when I hoped for good, evil came;

when I looked for light, then came darkness.

27The churning inside me never stops;

days of suffering confront me.

28I go about blackened, but not by the sun;

I stand up in the assembly and cry for help.

29I have become a brother of jackals,

a companion of owls.

30My skin grows black and peels;

my body burns with fever.

31My lyre is tuned to mourning,

and my pipe to the sound of wailing.