Jobu 3 – YCB & JCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 3:1-26

Jobu ráhùn sí Ọlọ́run

1Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré 2Jobu sọ, ó sì wí pé:

33.3-19: Jr 20.14-18.“Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé,

àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’

4Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,

kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;

bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.

5Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn;

kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e;

kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.

6Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri,

kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà:

kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.

7Kí òru náà kí ó yàgàn;

kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.

8Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún,

tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.

9Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;

kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i,

bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́

10Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,

láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.

11“Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá,

tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?

12Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi,

tàbí ọmú tí èmi yóò mu?

13Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́;

èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi

14pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé

tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.

15Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé

tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn

16Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí:

bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?

17Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu,

níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.

18Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀,

wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.

19Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀,

ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.

Jobu kígbe nínú ìrora rẹ̀

20“Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì,

àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,

21tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá,

tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.

22Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi,

tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?

23Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni

tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún,

tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?

24Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi;

ìkérora mi sì tú jáde bí omi.

25Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí,

àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.

26Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi;

bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”

Japanese Contemporary Bible

ヨブ 記 3:1-26

3

ヨブのことば

1ついにヨブは口を開き、自分の生まれた日をのろいました。

2-3「ああ、なぜ私は生まれたのか。

こんなことなら、いっそ生まれないほうがよかった。

4私が生まれた日など忘れ去られてしまえ。

神にさえ忘れられ、

永遠の暗闇に包まれてしまえばよいのだ。

5-6そうだ、暗闇がその日を奪い、

黒雲が覆い隠すがよい。

その日が暦から消し去られ、

その日には何もなかったことになればよい。

7その日の夜は荒れすさんだ、喜びのない夜となれ。

8のろいの名人よ、その日をのろってくれ。

9その夜は星も出るな。

その夜がどんなに光を待ちわびても

夜は明けることなく、

朝がくることがないように。

10それはこの日が、

母が私を身ごもらせないようにできなかったから、

こんな災難に会うため、わざわざ生まれさせたからだ。

11ああ、なぜ、私は生まれてすぐに死ななかったのか。

12なぜ、産婆は私を生かしておき、

乳房をふくませて養い育てたのか。

13生まれてすぐ死んでいたら、

今ごろ安らかに眠っていただろうに。

14-15栄華を極めた大臣や王たち、

また城の中に財宝を積み上げた領主たちと

いっしょになっていただろうに。

16呼吸もせず、陽の光を見ることもない

死産の子だったらよかったのだ。

17死んでしまえば、悪い者ももう人に迷惑をかけず、

疲れきった者も休むことができる。

18囚人も、残忍な看守から解放されて安らぎを得るのだ。

19死んでしまえば、金持ちも貧しい人もない。

奴隷でさえ、自由の身となる。

20-21なぜ、悲惨な境遇にある者に、

光といのちが与えられているのか。

彼らは死にたくても死ねない。

人が食べ物や金品のことで目の色を変えるように、

ひたすら死を求めているのに。

22思いどおり死ねたら、彼らはどんなに安らかだろう。

23神の与えるものが無益と失意の人生だけだとしたら、

なぜ、神は人を生まれさせるのだろう。

24私から出るのはため息ばかりで、

食事ものどを通らない。

うめき声は水のように止めどなくあふれている。

25恐れていたことがついに起こったのだ。

26ぬくぬくと遊び暮らしていたわけでもないのに、

災いが容赦なく降りかかったのだ。」