Jobu 29 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 29:1-25

Jobu rántí ìbùkún rẹ̀ àtẹ̀yìnwá

1Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:

2“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá,

bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́;

3Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,

àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;

4Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi,

nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi

5Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,

nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;

6Nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi,

àti tí apata ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.

7“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè,

nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,

8Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi,

wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn;

9Àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ,

wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu;

10Àwọn ọlọ́lá dákẹ́,

ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn.

11Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi,

àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi;

12Nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́,

àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un

13Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi,

èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.

14Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ,

ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.

15Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀

fún amúnkùn ún.

16Mo ṣe baba fún tálákà, mo ṣe

ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí.

17Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú,

mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.

18“Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi,

èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí iyanrìn.

19Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi,

ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.

20Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀

mi, ọrun mi sì padà di tuntun ní ọwọ́ mi.’

21“Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí,

wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.

22Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́;

ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.

23Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò;

wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀kúrò.

24Èmi sì rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́;

ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye sí wọn.

25Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn;

Mo jókòó bí ọba ní àárín ológun rẹ̀;

Mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.

Bibelen på hverdagsdansk

Jobs Bog 29:1-25

Jobs tidligere lykkelige liv

1Job fortsatte:

2„Ak, gid jeg havde det som i gamle dage,

dengang Gud sørgede så godt for mig,

3da han udøste sin velsignelse over mig

og fjernede alle forhindringer fra min vej.

4Jeg husker endnu mine velmagtsdage,

dengang Gud var gæst i mit hjem.

5Den Almægtige var altid hos mig,

og jeg havde mine børn omkring mig.

6Mine køer gav spandevis af mælk

og min olivenpresse mængder af olie.

7Jeg havde min plads blandt lederne i byen

og sad som dommer på byens torv.

8De unge trådte ærbødigt til side, når jeg kom,

og de ældre rejste sig op i respekt.

9Snakken forstummede blandt lederne,

alle tav stille for at høre mig tale.

10Selv de mest ansete satte fingeren for munden,

for at alle kunne høre, hvad jeg havde at sige.

11Alle, som hørte mig, lovpriste min visdom,

alle, der så mine handlinger, roste mig for dem.

12Jeg reddede de hjælpeløse ud af deres problemer,

hjalp de forældreløse til at få deres ret.

13De døende velsignede mig,

deres enker jublede af glæde.

14Jeg blev anset for at være ærligheden selv,

retfærdigheden i egen høje person.

15Jeg blev de blindes øjne

og de lammes fødder.

16Jeg blev de fattiges forsørger

og de fremmedes forsvarer.

17Jeg vristede uskyldige ofre

ud af gabet på de gudløse.

18Jeg forventede en fredfyldt død

efter et langt og lykkeligt liv.

19Jeg var som et træ, hvis rødder når til vandet,

og hvis grene forfriskes af nattens væde.

20Jeg blev æret hver eneste dag,

og min styrke blev dagligt fornyet.

21Folk spurgte mig til råds og lyttede opmærksomt,

de ventede spændt på, hvad jeg havde at sige.

22Når jeg havde talt, sagde ingen mig imod,

men de tog imod mine råd med glæde.

23De så frem til mine gode råd,

som landmanden ser frem til regnen,

og sugede min vejledning til sig,

som var de den tørre jord.

24Når jeg smilte til folk, fik de håbet tilbage,

når jeg så venligt på dem, lyste de af glæde.

25Jeg viste dem vejen, de skulle gå,

og fungerede som deres leder.

Jeg gik i spidsen for dem som en konge,

jeg var den, som trøstede de sørgende.