Jobu 24 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 24:1-25

Ìbéèrè Jobu

1“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́?

Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?

2Wọ́n a sún ààmì ààlà ilẹ̀,

wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn.

3Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba

lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.

4Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,

àwọn tálákà ayé a fi agbára sápamọ́.

5Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,

wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;

ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.

6Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko,

wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.

7Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ,

tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.

8Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,

wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.

9Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú,

wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.

10Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ;

àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà,

11Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,

tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.

12Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,

ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́

síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.

13“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;

Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.

14Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,

a sì pa tálákà àti aláìní,

àti ní òru a di olè.

15Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀;

‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’

ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.

16Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,

tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán,

wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.

17Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn;

nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.

18“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi;

ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun;

òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.

19Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́,

bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.

20Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò

ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀,

a kì yóò rántí ènìyàn búburú

mọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi;

21Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí

kò ṣe rere sí opó.

22Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára,

bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.

23Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un,

àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn,

ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.

24A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ;

a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn,

a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.

25“Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké,

tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”

King James Version

Job 24:1-25

1Why, seeing times are not hidden from the Almighty, do they that know him not see his days? 2Some remove the landmarks; they violently take away flocks, and feed thereof.24.2 feed…: or, feed them 3They drive away the ass of the fatherless, they take the widow’s ox for a pledge. 4They turn the needy out of the way: the poor of the earth hide themselves together. 5Behold, as wild asses in the desert, go they forth to their work; rising betimes for a prey: the wilderness yieldeth food for them and for their children. 6They reap every one his corn in the field: and they gather the vintage of the wicked.24.6 corn: Heb. mingled corn, or, dredge24.6 they gather…: Heb. the wicked gather the vintage 7They cause the naked to lodge without clothing, that they have no covering in the cold. 8They are wet with the showers of the mountains, and embrace the rock for want of a shelter. 9They pluck the fatherless from the breast, and take a pledge of the poor. 10They cause him to go naked without clothing, and they take away the sheaf from the hungry; 11Which make oil within their walls, and tread their winepresses, and suffer thirst. 12Men groan from out of the city, and the soul of the wounded crieth out: yet God layeth not folly to them.

13They are of those that rebel against the light; they know not the ways thereof, nor abide in the paths thereof. 14The murderer rising with the light killeth the poor and needy, and in the night is as a thief. 15The eye also of the adulterer waiteth for the twilight, saying, No eye shall see me: and disguiseth his face.24.15 disguiseth…: Heb. setteth his face in secret 16In the dark they dig through houses, which they had marked for themselves in the daytime: they know not the light. 17For the morning is to them even as the shadow of death: if one know them, they are in the terrors of the shadow of death.

18He is swift as the waters; their portion is cursed in the earth: he beholdeth not the way of the vineyards. 19Drought and heat consume the snow waters: so doth the grave those which have sinned.24.19 consume: Heb. violently take 20The womb shall forget him; the worm shall feed sweetly on him; he shall be no more remembered; and wickedness shall be broken as a tree. 21He evil entreateth the barren that beareth not: and doeth not good to the widow. 22He draweth also the mighty with his power: he riseth up, and no man is sure of life.24.22 no…: or, he trusteth not his own life 23Though it be given him to be in safety, whereon he resteth; yet his eyes are upon their ways. 24They are exalted for a little while, but are gone and brought low; they are taken out of the way as all other, and cut off as the tops of the ears of corn.24.24 are gone: Heb. are not24.24 taken…: Heb. closed up 25And if it be not so now, who will make me a liar, and make my speech nothing worth?