Jobu 21 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 21:1-34

Jobu dá Sofari lóhùn

1Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé:

2“Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi,

kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.

3Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà

ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.

4“Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí?

Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?

5Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,

kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.

6Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,

ìwárìrì sì mú mi lára.

7Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní

ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?

8Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú

wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.

9Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀

ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.

10Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì

tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;

11Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn

wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.

12Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti

haapu, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.

13Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn

sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.

14Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’

Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.

15Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in?

Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

16Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa

ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.

17“Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú?

Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn,

tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?

18Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́,

àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.

19Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’

Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.

20Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀,

yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.

21Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,

nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?

22“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀?

Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.

23Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀,

ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.

24Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú,

egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.

25Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀,

tí kò sì fi inú dídùn jẹun.

26Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀,

kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.

27“Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti

àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.

28Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé,

àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’

29Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà?

Ẹ̀yin kò mọ̀ ààmì wọn, pé

30ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun.

A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.

31Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú,

ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?

32Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú,

a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.

33Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.

Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́

lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.

34“Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán,

bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”

King James Version

Job 21:1-34

1But Job answered and said, 2Hear diligently my speech, and let this be your consolations. 3Suffer me that I may speak; and after that I have spoken, mock on. 4As for me, is my complaint to man? and if it were so, why should not my spirit be troubled?21.4 troubled: Heb. shortened? 5Mark me, and be astonished, and lay your hand upon your mouth.21.5 Mark…: Heb. Look unto me 6Even when I remember I am afraid, and trembling taketh hold on my flesh.

7Wherefore do the wicked live, become old, yea, are mighty in power? 8Their seed is established in their sight with them, and their offspring before their eyes. 9Their houses are safe from fear, neither is the rod of God upon them.21.9 safe…: Heb. peace from 10Their bull gendereth, and faileth not; their cow calveth, and casteth not her calf. 11They send forth their little ones like a flock, and their children dance. 12They take the timbrel and harp, and rejoice at the sound of the organ. 13They spend their days in wealth, and in a moment go down to the grave.21.13 in wealth: or, in mirth 14Therefore they say unto God, Depart from us; for we desire not the knowledge of thy ways. 15What is the Almighty, that we should serve him? and what profit should we have, if we pray unto him? 16Lo, their good is not in their hand: the counsel of the wicked is far from me.

17How oft is the candle of the wicked put out! and how oft cometh their destruction upon them! God distributeth sorrows in his anger.21.17 candle: or, lamp 18They are as stubble before the wind, and as chaff that the storm carrieth away.21.18 carrieth: Heb. stealeth 19God layeth up his iniquity for his children: he rewardeth him, and he shall know it.21.19 his iniquity: that is, the punishment of his iniquity 20His eyes shall see his destruction, and he shall drink of the wrath of the Almighty. 21For what pleasure hath he in his house after him, when the number of his months is cut off in the midst? 22Shall any teach God knowledge? seeing he judgeth those that are high. 23One dieth in his full strength, being wholly at ease and quiet.21.23 his…: Heb. his very, or, the strength of, his perfection 24His breasts are full of milk, and his bones are moistened with marrow.21.24 breasts: or, milk pails 25And another dieth in the bitterness of his soul, and never eateth with pleasure. 26They shall lie down alike in the dust, and the worms shall cover them.

27Behold, I know your thoughts, and the devices which ye wrongfully imagine against me. 28For ye say, Where is the house of the prince? and where are the dwelling places of the wicked?21.28 the dwelling…: Heb. the tent of the tabernacles 29Have ye not asked them that go by the way? and do ye not know their tokens, 30That the wicked is reserved to the day of destruction? they shall be brought forth to the day of wrath.21.30 wrath: Heb. wraths 31Who shall declare his way to his face? and who shall repay him what he hath done? 32Yet shall he be brought to the grave, and shall remain in the tomb.21.32 grave: Heb. graves21.32 remain…: Heb. watch in the heap 33The clods of the valley shall be sweet unto him, and every man shall draw after him, as there are innumerable before him. 34How then comfort ye me in vain, seeing in your answers there remaineth falsehood?21.34 falsehood: Heb. transgression?