Jobu 20 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 20:1-29

Ìdáhùn Sofari

1Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé:

2“Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn,

àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.

3Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye

mi sì dá mi lóhùn.

4“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́,

láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,

5pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni,

àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?

6Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run,

ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;

7Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀;

àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’

8Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,

àní a ó lé e lọ bi ìran òru.

9Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.

10Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà,

ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.

11Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀,

tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.

12“Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀,

bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,

13bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,

14Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà,

ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;

15Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde;

Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.

16Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú;

ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.

17Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì,

ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.

18Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì;

gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.

19Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n;

Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.

20“Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀,

kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.

21Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀;

Nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.

22Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;

àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.

23Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun,

Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́,

yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.

24Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn;

ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.

25O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára;

idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá.

Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;

26òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀.

Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run

yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.

27Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn,

ayé yóò sì dìde dúró sí i.

28Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun

ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.

29Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,

àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

New Russian Translation

Иов 20:1-29

Вторая речь Цофара

1Тогда ответил Цофар из Наамы:

2– Мои тревожные мысли заставляют меня ответить,

потому что я объят смятением.

3Я слышу упрек, который позорит меня,

и мой ум побуждает меня ответить.

Цофар описывает судьбу нечестивых

4Разве ты не знаешь, как было издревле,

с тех пор, как поставлен на земле человек,

5что кратко веселье нечестивцев,

и радость безбожников лишь на миг?

6Пусть гордыня его достигает небес,

а голова касается облаков,

7он сгинет навек, как его же нечистоты;

и спросят видевшие его: «Где он?»

8Как сон улетит, и его не найти,

как ночное видение пропадет.

9Глаз, что видел его, впредь его не увидит;

место его на него не посмотрит.

10Его дети будут заискивать перед нищими,

своими руками вернет он все, что похитил,

11молодецкая сила, что наполняет его кости,

вместе с ним ляжет в прах.

12Если его устам сладко зло,

и он под языком его скрывает,

13если он бережет его, не бросает,

держит его во рту,

14то станет пища в его желудке

ядом змеиным внутри него.

15Отрыгнет он богатства, которые проглотил;

Бог исторгнет их из его желудка.

16Змеиный яд он будет сосать,

жало гадюки его убьет.

17Не видать ему потоков водных,

рек, текущих медом и молоком.

18Он вернет нажитое, не отведав;

доходам от труда своего не порадуется.

19Теснил он бедных и пренебрегал ими;

захватывал дома, которые не строил.

20В желудке его нет покоя,

а в богатстве нет спасения.

21Ничто не спаслось от его обжорства,

потому и удача его не удержится.

22Среди достатка его настигнет беда;

все руки обиженных поднимутся на него.

23Когда он свой живот набьет до отказа,

Бог пошлет на него Свой пылающий гнев,

прольет дождем на его плоть20:23 Возможный текст; смысл этого места в еврейском тексте неясен..

24Он убежит от железного оружия,

но его пронзит бронзовая стрела.

25Стрела войдет в его спину

и пройдет, сверкая, сквозь его печень.

Двинутся ужасы на него.

26Кромешная тьма ожидает его сокровища.

Никем не зажженный огонь пожрет его

и сожжет последнее, что осталось в его шатре.

27Беззакония его небеса откроют,

и восстанет против него земля.

28Богатство его дома расточится,

в день Божьего гнева расплещется, как вода.

29Вот участь нечестивому от Бога,

удел, который определил ему Бог.