Jobu 19 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 19:1-29

Ìdáhùn Jobu fún Bilidadi

1Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:

2“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí,

tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?

3Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí;

ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.

4Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́,

ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.

5Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,

tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,

6Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,

ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;

mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.

8Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,

Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.

9Ó ti bọ́ ògo mi,

ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.

10Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,

ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.

11Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi,

ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.

12Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi,

wọ́n sì mọ odi yí mi ká,

wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.

13“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré,

àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.

14Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn,

àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.

15Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;

èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.

16Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;

mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.

17Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi

ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.

18Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín:

Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.

19Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,

àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.

20Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi,

mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.

21“Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,

ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.

22Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí

Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?

23“Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi

nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!

24Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ

wọ́n sínú àpáta fún láéláé.

25Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè

àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;

26Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara

mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,

27Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi,

tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn;

ọkàn mi sì dákú ní inú mi.

28“Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!

Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’

29Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù;

nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà,

Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”

New International Version

Job 19:1-29

Job

1Then Job replied:

2“How long will you torment me

and crush me with words?

3Ten times now you have reproached me;

shamelessly you attack me.

4If it is true that I have gone astray,

my error remains my concern alone.

5If indeed you would exalt yourselves above me

and use my humiliation against me,

6then know that God has wronged me

and drawn his net around me.

7“Though I cry, ‘Violence!’ I get no response;

though I call for help, there is no justice.

8He has blocked my way so I cannot pass;

he has shrouded my paths in darkness.

9He has stripped me of my honor

and removed the crown from my head.

10He tears me down on every side till I am gone;

he uproots my hope like a tree.

11His anger burns against me;

he counts me among his enemies.

12His troops advance in force;

they build a siege ramp against me

and encamp around my tent.

13“He has alienated my family from me;

my acquaintances are completely estranged from me.

14My relatives have gone away;

my closest friends have forgotten me.

15My guests and my female servants count me a foreigner;

they look on me as on a stranger.

16I summon my servant, but he does not answer,

though I beg him with my own mouth.

17My breath is offensive to my wife;

I am loathsome to my own family.

18Even the little boys scorn me;

when I appear, they ridicule me.

19All my intimate friends detest me;

those I love have turned against me.

20I am nothing but skin and bones;

I have escaped only by the skin of my teeth.19:20 Or only by my gums

21“Have pity on me, my friends, have pity,

for the hand of God has struck me.

22Why do you pursue me as God does?

Will you never get enough of my flesh?

23“Oh, that my words were recorded,

that they were written on a scroll,

24that they were inscribed with an iron tool on19:24 Or and lead,

or engraved in rock forever!

25I know that my redeemer19:25 Or vindicator lives,

and that in the end he will stand on the earth.19:25 Or on my grave

26And after my skin has been destroyed,

yet19:26 Or And after I awake, / though this body has been destroyed, / then in19:26 Or destroyed, / apart from my flesh I will see God;

27I myself will see him

with my own eyes—I, and not another.

How my heart yearns within me!

28“If you say, ‘How we will hound him,

since the root of the trouble lies in him,19:28 Many Hebrew manuscripts, Septuagint and Vulgate; most Hebrew manuscripts me

29you should fear the sword yourselves;

for wrath will bring punishment by the sword,

and then you will know that there is judgment.19:29 Or sword, / that you may come to know the Almighty